Èèyàn 45 kú, 61 míràn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi méjì rì sínú agbami

Aworan awọn oṣiṣẹ abo oju omi

Oríṣun àwòrán, Djibouti Coast Guard

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ko din ni eeyan marndinlaadọta to ti jade laye, nigba ti awọn miran tun di awati lẹyin ti ọkọ oju omi meji kan to n ko awọn aṣatipo wọ omi ni agbami kan ni Djibouti.

Awọn alaṣẹ nibẹ sọ pe awọn ọkọ oju omi meji naa gbera n lọ si orilẹede Yemen ni pẹlu awọn ero to to ọọdunrun o le mẹwaa ninu wọn ki o to di pe o ri sinu agbami okun pupa lọjọ Iṣẹgun.

Ajọ to n mojuto abo ori omi ni Djibouti sọ pe, “titi di bi a ṣe n sọrọ yii, eeyan mọkalelọgọta ni wọn ṣi n wa, bẹẹ si ni awọn oṣiṣẹ idoola ẹmi ko ti da ọwọ iṣẹ duro.

Eyi ni tuntun ninu iṣẹlẹ ijamba ọkọ oju omi to maa n waye lagbegbe yii, eleyi ti awọn onimọ ti tọkan si gẹgẹ bi oju omi ti awọn aṣatipo n gba julọ to si tun lewu julọ lagbaye.

Ọkọ oju omi naa ri ni iwọn aadọjọ mita si eti okun nitosi ẹkun iwọ oorun ariwa Khor Angar.

Wọn ni wọn ṣi n wa awọn eeyan to ṣeeṣe ki wọn moribọ ninu ijamba ọkọ oju omi naa, pẹlu bi wọn ti ṣe ri ẹmi awọn marundinlọgọfa doola lara awọn to wa ninu ọkọ naa.

Ọpọlọpọ awọn ọmọ ilẹ Afirika to fẹ sa lọ si orilẹ Yuroopu lọna ati wa igbe aye to rọrun fun ara wọn ni wọn maa n gba ori okun pupa kọri si agbegbe ilẹ larubawa.

Ni oṣu kẹfa ọdun yii ko din ni awọn eeyan mẹrindinlọgọta ti wọn jẹ ọmọ orilẹede Somalia ati Ethiopia ni wọn ku sinu ijamba ọkọ oju omi kan ti ọpọ miran ti wọn to ogoje niye pẹlu tun di awati nigba ti ọkọ ọju omi ti wọn wọ lati orilẹede Somalia dojude lori odo Gulf of Eden, ni agbegbe gusu orilẹede Yemen. Awọn obinrin mọkanlelọgbọn ati ọmọde mẹfa wa ninu awọn to ku nigba naa.

Lọdun to kọja, iye awọn eeyan to rinrinajo kuro lẹkun origun Africa, iyẹn Horn of Africa lọ si Yemen jẹ ẹgbẹrun mẹtadinlọgọrun o le igba, eyi to tun pọ sii ju ẹgbẹrun mẹtalelaadọrin to lọ lọdun 2022.

Pupọ ninu wọn lo jẹ pe awọn onifayawọ ni wọn maa n lo, awọn ọkọ oju omi to kun akunfaya ni wọn si maa lati fi kọja.