Iran ju àdó olóró 180 sí Israel, ọ̀pọ̀ di aláìnílélórí

Israel

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ijọba Israel ti sọ pe orilẹede Iran ti sọ ado oloro ọgọsan an si orilẹede oun, eyii to fa ibẹrubojo sọkan awọn araalu.

Ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu eeyan lo ti sa fi ile wọn silẹ ki iro ibugbamu to maa dun lakọlakọ niluu Jerusalem ati Tel Aviv.

Awọn adoola ẹmi sọ pe eeyan meji farapa lẹyin ti irin ara ado oloro naa ba wọn.

Ileeṣẹ ọmọ ogun Israel ni pẹlu iranlọwọ ilẹ Amẹrika lawọn fi koju pupọ ninu misaili naa amọ diẹ lara wọn balẹ sọdọ awọn.

IIeeṣẹ ọmọ ogun Iran, Revolutionary Guards ti sọ pe gbogbo ado oloro ti awọn ju si Israel lo balẹ sibẹ.

Wọn ni inu awọn dun gidi pe awọn ni anfani lati gbẹsan iku olori Hezbollah, Hamas ati ọkan lara awọn ọgagun Iran ti iku wọn ti ọwọ Israel waye.

Nigba ti aṣoju ijọba ilẹ Amẹrika sọrọ lori iṣẹlẹ naa, o ni o jọ bii pe Israel kapa awọn misaila ti Iran fi ranṣẹ silẹ rẹ, awọn si ti n jiroro pẹlu Israel lori bi yoo ṣe gbeṣan pada.

Ẹwẹ akọwe agba ajọ United Nations ti bu ẹnu atẹ lu ija to n waye laarin orilẹede mejeji.

Ikọlu naa lo n waye lẹyin wakati diẹ ti awọn ọmọ ogun Israel bẹrẹ ikọlu si iha ila oorun Lebanon lati ṣekupa awọn ọmọ ogun Hezbollah to wa nibẹ latari bi agbegbe naa ṣe pin ala pẹlu Israel.

Nnkan bi ọdun kan sẹyin ni Israel bẹrẹ si n kọju ija si Hezbolla latari bo ṣe n ju ado oloro si awọn eeyan lagbegbe rẹ.