Ilé aṣòfin bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yọ igbákejì ààrẹ nípò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ilé aṣòfin orílẹ̀ èdè Kenya ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yọ igbákejì ààrẹ orílẹ̀ ède náà kúrò nípò.
Àwọn aṣòfin tí wọ́n fọwọ́ sí ìyọnípò Rigathi Gachagua fẹ̀sùn kàn-án wí pé ó lọ́wọ́ nínú ìwọ́de ìfẹ̀hóníhàn tako ìjọba tó wáyé nínú oṣù Kẹfà àti pé ó ń lọ́wọ́ nínú ìwà àjẹbánu, títako ìjọba àti ṣíṣe àtìlẹ̀yìn fún ẹlẹ́yàmẹ̀yà.
Igbákejì ààrẹ náà ti tako gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án, ó ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni.
Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn ààigbọ́ra ẹni yé tó ń wáyé láàárín Gachagua àti ààrẹ William Ruto.
Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Abẹnugan ilé aṣòfin àpapọ̀ orílẹ̀ èdè Kenya ní kí ìgbésẹ̀ ìyọnípò náà bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí aṣòfin 291 ti àbá náà lẹ́yìn pé kí wọ́n yọ ọ́ nípò. Gẹ́gẹ́ bí òfin, tí àwọn aṣòfin bá ti pé 117 tí wọ́n ti àbá náà lẹ́yìn, ìgbésẹ̀ ìyọnípò lè bẹ̀rẹ̀.
Ìgbésẹ̀ ìyọnípò náà ni ìrètí wà pé yóò lọ ní ìrọ̀rùn ní ilé aṣòfin méjéèjì látàrí bí àwọn aṣòfin tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ṣe ń fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn aṣòfin ẹgbẹ́ òṣèlú ààrẹ láti yọ igbákejì ààrẹ náà nípò lẹ́yìn ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn náà. Ṣùgbọ́n wọn ò tíì mú ọjọ́ tó máa wáyé gangan.
Gbogbo ìgbìyànjú láti dènà ìyọnípò náà ní ilé ẹjọ́ ló já sí pàbó.
Ìfaǹfà tó ń wáyé láàárín ààrẹ William Ruto àti igbákejì rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára nǹkan tó ń fa àìṣedédé ètò ìṣèjọba ní irú àsìkò yìí tí Kenya ń kojú ìṣòro ètò ọrọ̀ ajé àti owó.
Lásìkò ètò ìdìbò ọdún 2022 níbi tí Ruto ti fìdí olóòtú ìjọba tẹ́lẹ̀ rí, Raila Odinga janlẹ̀ ni Ruto yan Gachagua gẹ́gẹ́ bí igbákejì rẹ̀.
Ẹkùn Mount Kenya ni Gachagua ti wá tó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún Ruto láti rí ìbò tó pọ̀ ní ẹkùn náà.
Àmọ́ bí àwọn aṣòfin tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Odinga ṣe ti ń darapọ̀ mọ́ ìjọba lẹ́yìn ìwọ́de tá àwọn ọ̀dọ́ ṣe tako mímú àlékún bá àwọn owó orí ni ètò òṣèlú orílẹ̀ èdè náà ti yípadà, tí igbákejì ààrẹ sì ń rí ara rẹ̀ bíi òun nìkan.
Gachagua ẹ̀wẹ̀, pẹ̀lú ohùn akin, ní òun ní àtìlẹyìn àwọn olùdìbò ní ààrin gbùngbùn Kenya.
“Igba àwọn aṣòfin kò lè yí ìfẹ́ àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè wa padà,” ó sọ.
Kí àbá náà tó lè dófin, ìdá méjì mínú ìdá mẹ́ta àwọn aṣòfin àti ilé aṣòfin àgbà ló gbọ́dọ̀ fọwọ́ si.
Àwọn tí wọ́n ń ṣe àtìlẹyìn fún ìyọnípò náà ní àwọn gbàgbọ́ pé ó máa jẹ́ ìbuwọ́lù.
Gachagua ní òun kò kàn ní gbà bẹ́ẹ̀ láì jà fún ẹ̀tọ́ òun.
Ó sọ fún àwọn akọ̀ròyìn kí ìjíròrò ilé tó bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun pé ààrẹ le sọ fún àwọn aṣòfin láti má gbé ìgbésẹ̀ náà àmọ́ tí wọ́n bá tẹ̀síwájú, a jẹ́ wí pé ààrẹ mọ̀ nípa rẹ̀ ni.
Ruto ti ṣaájú jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun kò ní jẹ́ kí igbákejì òun kojú ìfìyàjẹni lágbo òṣèlú nítorí nǹkan tí òun kojú nígbà tí òun wà ní ipò igbákejì sí Uhuru Kenyatta tó gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àmọ́ ìfaǹfa tó wáyé láàárín Ruto àti Gachagua ti ń fojú hàn lẹ́nu oṣù díẹ̀ sẹ́yìn.
Gachagua kò máa sin Ruto lọ sí pápákọ̀ òfurufú tó bá ń ṣe ìrìnàjò lọ sí ilẹ̀ òkèrè bíi ti ìgbà kan mọ́ tàbí kó pàdé rẹ̀ nígbà tó bá dé padà.
Akọ̀wé iléeṣẹ́ ètò abẹ́nú, Kithure Kindiki, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ òfin ni ó ti ń ṣe ọ̀pọ̀ àwọn ojúṣe tí igbákejì ààrẹ máa ń ṣe – irúfẹ́ nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ruto àti Kenyatta jà.
Gẹ́gẹ́ bíi Gachagua, Mount Kenya náà ni Kindiki ti wá - ẹkùn tí ìbò tí máa ń pọ̀ jùlọ ní Kenya.
Ọ̀pọ̀ àwọn aṣòfin ló ń ṣe àtìlẹyìn fún Kindiki táwọn èèyàn sì ń rò ó pé bóyá òun ni wọ́n fẹ́ fi rọ́pò Gachagua.
Ẹ̀ka tó ń rí sí ìwádìí ìwà ọ̀daràn ní iléeṣẹ́ ọlọ́pàá (DCI), fẹ̀sùn kan àwọn aṣòfin méjì àtàwọn èèyàn míì tí wọ́n súnmọ́ Gachagua pé wọ́n lọ́wọ́ nídìí ṣíṣe àtìlẹyìn fún ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn tó lágbára tó wáyé ní oṣù Kẹfà.
Gachagua nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ fi àwọn ẹ̀sùn náà bá òun lórúkọ jẹ́ ni àti láti lè ní nǹkan tí wọ́n fi yọ òun nípò lé lórí.
Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni Kindiki, tí DCI wà lábẹ́ iléeṣẹ́ rẹ̀ ní òun yóò ṣe àrídájú rẹ̀ pé òun ṣe òótọ́ nínú ìwádìí òun àmọ́ tó ní ọ̀pọ̀ àwọn alágbára ló máa jìyà ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n wà nídìí ìfẹ̀hónúhàn náà ní kìí ṣe àwọn èèyàn Gachagua ló ṣe àtìlẹyìn fún àwọn àti pé àwọn aṣòfin náà ń fi ìyẹn bo ẹ̀sùn ìwà ìbájẹ́ àti ìṣèjọba tí kò dára mọ́lẹ̀ ni.
Wọ́n ní ohun tó bá fi lè mú àwọn aṣòfin lé igbákejì lọ, ààrẹ William Ruto náà gbọdọ̀ kúrò nípò.















