Àwọn ọ̀dọ́ Kwara fẹ̀hónúhàn lẹ́yìn tí àwọn ajínigbé gbẹ̀mí oníṣẹ̀ṣe

Ilu igbaja ni ijọba ibilẹ Ifelodun, nipinlẹ Kwara kan gogo bi awọn ọdọ ilu ṣe tu jade lati fẹhonuhan tako bi awọn ajinigbe ṣe ṣekupa ọkan lara awọn aṣiwaju ilu.
Awọn ọdọ naa ti wọn fi ẹdun ọkan wọn han lori iṣẹlẹ naa ni awọn o fẹ awọn Fulani darandaran ni ilu naa mọ.
Aarọ kutu ọjọ Aje ni iroyin iku ọkan lara awọn aṣiwaju ilu naa gba igboro ilu Ìgbàjà.
Ọkan lara awọn ọdọ ilu ọhun to ba BBC sọrọ, ọgbẹni Akeem Lasisi sọ pe o ti pẹ tawọn ajinigbe naa ti ń da awọn laamu ni ilu naa ati agbegbe rẹ.
O fidi rẹ mulẹ pe, awọn ajinigbe ṣekupa Lukman Balogun ti gbogbo eeyan mọ si Balogun, oun si ni olori awọn onisẹṣe ilu Igbaja.
Awọn ọdọ ilu naa ṣe iwọde lọ si aafin ọba alaye ìlu naa, elese yi ilẹ Igbaja, Ọba Ahmed Babalola Awuni Arepo Kẹta.
Lasiko to n ba awọn ọdọ ilu naa sọrọ, Oba ọ̀hún parọwa si wọn lati ni suuru pẹlu ileri lati gbe igbesẹ lori iṣoro to n ba ilu naa fínra.
Awọn ọdọ naa ni awọn o fẹ awọn Fulani adaranjẹ mọ ni ilu awọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ejirẹ Adeyemi ṣeleri lati kan si awọn akọroyin lori ibi ti ọrọ naa de laipẹ.















