Verydarkman yọjú sílé aṣòfin, wo ohun tó ṣẹlẹ̀ síi níbẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ fọ́nrán ohùn Bobrisky tí wọ́n ká sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, @bobrisky/verydarkman/Instagram
Gbajúmọ̀ orí ayélujára, Martin Otse tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí VeryDarkMan ti ṣàlàyé bí ó ṣe rí fọ́nrán tí wọ́n fi ká ohùn gbajúmọ̀ akọ tó máa ń ṣe bí abo, Idris Okuneye, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Bobrisky sílẹ̀.
Ní ọjọ́ Ajé, ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù Kẹsàn-án ni VeryDarkMan yọjú sí ikọ̀ tó ń ṣe ìwádìí ní ilé aṣojúṣòfin tó sì sọ̀rọ̀ nípa bí ohùn náà ṣe dé ọwọ́ rẹ̀.
Ṣáájú ni ilé aṣojúṣòfin tí ránṣẹ́ pe VeryDarkMan, ọ̀gá àgbà EFCC àti Bobrisky láti wá wí tẹnu wọn lórí fọ́nrán náà.
Ó ṣàlàyé pé èèyàn kan tí Bobrisky jẹ lówó mílíọ̀nù mẹ́rin náírà ló kan sì òun láti bá òun gba owó náà padà lọ́wọ́ Bobrisky.
Ó ní ẹni náà sọ fún pé òun ní àwọn àṣìrí kan lọ́wọ́ látara ohùn Bobrisky tí òun ká sílẹ̀ nígbà tí àwọn ń sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀.
Ó sọ pé lẹ́yìn tí òun gbọ́ ohùn náà, òun ṣe fídíò, tí òun sì fi ránṣẹ́ sí ẹni náà láti fi ránṣ ẹ́ Bobrisky.
“Bí Bobrisky ṣe wo fídíò náà ló bẹ̀rẹ̀ sí ní bẹ onítọ̀hún, tó si san owó náà padà fún-un.”
Ó fi kun pé òun mọ̀ọ́mọ̀ gbé ohùn náà síta ni nígbà tí òun gbọ́ àwọn nǹkan tí Bobrisky ń sọ níbẹ̀, tí òn sì ri pé àwọn èèyàn nílò láti mọ bí ìwà ìbàjẹ́ ṣe gbokùn tó ní Nàìjíríà.
Ṣáájú ni VeryDarkMan ní òun kò ní sọ̀rọ̀ níwájú ìgbìmọ̀ ilé náà nítorí Bobrisky kò yọjú, tó sì jẹ́ pé agbẹjọ́rò rẹ̀ ló rán láti ṣojú rẹ̀.
Ó ní òun kò ní sọ̀rọ̀ tí òun kò bá rí ọ̀gá àgbà àjọ EFCC níkalẹ̀.
“Mi ò rí ìdí tí mà á wà níbí àmọ́ tí Bobrisky kò ní yọjú. Agbẹjọ́rò mi máa sọ̀rọ̀. Mi ò ní sọ nǹkankan àyàfi tí Bobririsky àti ọ̀gá àgbà EFCC bá wá sí bí.
Àmọ́ lẹ́yìn náà ni agbẹjọ́rò rẹ̀, Deji Adeyanju sọ fún ìgbìmọ̀ náà pé oníbàárà máa sọ̀rọ̀, ó kàn fẹ́ kí gbogbo àwọn tó yẹ wà ní ìkàlẹ̀ ni.
Verydarkman wá rọ ilé aṣojúṣòfin láti ṣe ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà dáradára láti ìdí òótọ́ múlẹ̀, kí wọ́n sì ṣe àwárí bàbá ìsàlẹ̀ tí Bobrisky ní kò jẹ́ kí òun wọ ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Aṣojú EFCC àti ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n Nàìjíríà náà yọjú síwájú ìgbìmọ̀ náà láti sọ nǹkan tí wan mọ̀ lórí ẹ̀sùn náà.
Ohun ti Bobrisky sọ ninu fọnran ti VeryDarkMan gbe sita ree...
VeryDarkMan ṣe fidio kan ninu eyi ti o ti sọ ọpọlọpọ ọrọ nipa awọn ohun ti o ṣẹlẹ lẹyin ti EFCC fẹsun ṣiṣe owo naira baṣu baṣu kan Bobrisky.
Ninu fọnran ti VeryDarkMan ṣe yii ni o ti fi ọrọ ti Bobrisky sọ lori foonu pẹlu ẹnikan nibi to ti sọ pe awọn oṣiṣẹ EFCC kan sọ foun pe EFCC yoo yọ ẹsun kiko owo lọ si oke okun lara awọn ẹsun ti wọn fi kan oun toun ba le san miliọnu mẹẹdogun.
VeryDarkman fẹsun kan EFCC pe kete ti ajọ naa gba miliọnu mẹẹdogun ti wọn beere lọwọ Bobrisky tan ni wọn yọ ẹsun jiji owo ko lọ soke okun kuro ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan an lootọọ.
Bobrisky ṣalaye ninu fọnran naa pe ‘’bayii ni mo bẹrẹ si ni pe ọpọ awọn ọrẹ mi lori foonu wi pe ki wọn ran mi lọwọ pẹlu owo.
Lẹyin o rẹyin, awọn ọrẹ mi da owo jọ fun mi titi ti owo naa fi pe N15m ti EFCC sọ pe ki n mu wa.
Bayii ni mo ṣe san miliọnu mẹẹdogun yii ti ajọ naa si yọ ẹsun jiji owo ko lọ oke okun kuro ninu ẹsun ti wọn kan mi.
Lẹyin naa ni wọn sọ pe ẹsun ṣiṣe owo naira baṣu baṣu nikan ni mo maa jẹjọ lori rẹ.’’
Mo ti n lọ sọgba ẹwọn ki baba isalẹ mi to pe mi pe mi o ni ṣẹwọn - Bobrisky
Bobrisky tun ṣalaye ninu fọnran ohun rẹ ti VeryDrakman gbe jade wi pe oun ti wa loju ọna si ọgba ẹwọn nigba ti baba isalẹ oun pe oun lori ago pe koun ma foya tori oun o ni wọ inu ọgba ẹwọn.
‘’Bayii ni baba isalẹ mi sọ fun mi pe oun yoo ṣeto ile to dara kan fun mi ti ko jina sọgba ẹwọn.
O ni oun yoo pe ọga ọgba ileeṣẹ ijọba to n ri si ọgba ẹwọn ni Naijiria to wa l’Abuja nipa ọrọ naa.
Lẹyin naa ni wọn gbe mi lọ sinu ile kan, wọn si sọ fun mi pe n ko gbọdọ jade titi ti ọjọ to yẹ ki n fi wa lẹwọn yoo fi pe.
Wọn ni ọga agba to n ri si ọrọ ọgba ẹwọn yii yoo gba miliọnu meje naira,’’ Bobrisky ṣalaye.
VeryDarkMan wa kepe ọga agba ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ọgba ẹwọn ni Naijiria pe ko wa sọ tẹnu rẹ lori ọrọ naa.
Bobrisky tun sọ pe akọrin takasufee Falz the Bad Guy naa sọ fun baba rẹ Femi Falana to jẹ agbẹjọro agba nipa oun.
O ni Falana sọ pe oun le bẹbẹ wi pe ki ile ẹjọ foju aanu wo oun lori ọrọ naa.
Falana sọ pe ‘ijọba apapọ le darijin mi, o ni oun yoo kọ ẹbẹ naa ranṣẹ si minisita eto idajọ ni Naijiria ẹni ti yoo gbe e lọ siwaju aarẹ fun ibuwọlu.
Ṣugbọn ohun ti a gbọ ni pe ọkunrin naa ni miliọnu mẹwaa naira loun maa gba ki oun to le ṣiṣẹ naa.’’
VeryDarkMan wa sọ pe awọn aṣiri ti Bobrisky tu sita yii fihan pe iwa ibajẹ ko le tan nilẹ kiakia lorilẹede Naijiria.
O wa kepe ajọ EFCC lati ṣe iṣẹ iwadii lori awọn ẹsun to jẹ jade ninu ọrọ ti Bobrisky sọ.














