Àwọn ọkùnrin mẹ́rin tó páwọpọ̀ fipá bá ọmọbìnrin kan lòpọ̀ rí ẹ̀wọ̀n gbére he

Àwọn afurasí tí wọ́n dájọ́ ẹ̀wọ̀n gbére fún

Oríṣun àwòrán, Ronald Sonyo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ilé ẹjọ́ kan ní orílẹ̀ èdè Tanzania ti rán àwọn ọkùnrin mẹ́rin kan lọ sí ẹ̀wọ̀n gbére fẹ́sùn wí pé wọ́n pawọ́pọ̀ fípa bá ọmọbìnrin kan tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò ì tíì pé ọdún méjìdínlógún lòpọ̀.

Lára àwọn tí wọ́n rán ní ẹ̀wọ̀n gbére náà ni Clinton Damas tó fìgbà kan jẹ́ ọmọ ogun Tanzania People’s Defence Force àti Praygod Mushi tí òun jẹ́ òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n.

Àwọn yòókù ni Nickson Jackson àti Amin Lema.

Yàtọ̀ sí ẹ̀wọ̀n gbére, ilé ẹjọ́ ní kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn san owó mílíọ̀nù kan Tanzania Shilling (N612,680.86) fún ọmọbìnrin tí wọ́n fipá bá lòpọ̀ ọ̀hún.

Afurasí karùn-ún lórí ẹjọ́ náà tó jẹ́ obìnrin ọlọ́pàá tí ìgbàgbọ́ wà pé òun ló ní àwọn ọkùnrin náà fipá bá ọmọbìnrin náà lòpọ̀.

Ní oṣù Kẹwàá ni ìgbẹ́jọ́ àti ìdájọ́ tirẹ̀ yóò wáyé.

Ìṣẹ̀lẹ̀ náà fa awuyewuye káàkiri orílẹ̀ èdè Tanzania.

Ní ìta ilé ẹjọ́ Májísíréètì Dodoma tí wọ́n ti gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀ lọ́jọ́ Ajé, agbẹjọ́rò àwọn ọkùnrin náà, Godfrey Wasonga sọ pé ìdàjọ́ náà kò tẹ́ àwọn lọ́rùn, bó ṣe ní àwọn ilé ẹjọ́ kò tẹ̀lé àwọn òfin tó yẹ.

Àmọ́ àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn àtàwọn ìlú mọ̀ọ́ká ni wọ́n ti ń kan sáárá sí ìdájọ́ náà lórí ayélujára.

Nínú oṣù Kẹjọ ni fídíò bí àwọn ọkùnrin náà ṣe ń fipá bá ọmọbìnrin náà lòpọ̀ gba orí ayélujára tó sì fa awuyewuye.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá rọ àwọn èèyàn láti yé pín fídíò náà nítorí àti dá ààbò bo ọmọbìnrin náà àtàwọn ẹbí rẹ̀.

Orílẹ̀ èdè Tanzania ló ń kojú ìṣòro ìwà ipá lórí awọn obìnrin èyí tó ń fi ojoojúmọ́ peléke si, tí ọ̀pọ̀ rẹ̀ sì máa ń lọ láì fi ìyà tó tọ́ jẹ àwọn tó ṣe é.

Àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ní tí àwọn tó fipá bá ọmọbìnrin náà lòpọ̀ láì fi ìyà tó tọ́ jẹ wọ́n yóò mú kí ìwà náà túnbọ̀ máa tẹ̀siwájú ní àwùjọ ni.

Láìpẹ́ yìí ni wọ́n ọlọ́pàá, Theopista Mallya kúrò nípò látàrí ọ̀rọ̀ tó sọ pé aṣẹ́wó ni ọmọbìnrin náà.