Kókó tó yẹ kí o mọ̀ nípa Kamala Harris tó fẹ́ di obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò jẹ ààrẹ America

Aworan Kamala Harris

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Rachel Looker and Holly Honderich
    • Role, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ni kete ti Aarẹ Joe Biden gba pe oun ko ni dije fun ipo aarẹ orilẹede Amẹrika labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Democrat ni o ti bẹrẹ si ni gbaruku ti Kamala Harris, igbakeji rẹ ti ẹgbẹ naa fi rọpo rẹ.

Harris ti bẹrẹ si ni ṣe daadaa ninu ipolongo rẹ lati di obinrin akọkọ ti yoo jẹ aarẹ orilẹede Amẹrika.

Koda owo to to $671m lawọn ololufẹ rẹ ti da fun un bayii laarin oṣu meji ti o ti bẹrẹ ipolongo.

Diẹ loku ki owo yii to ilọpo mẹta gbogbo owo ti alatako rẹ, oludije ẹgbẹ oṣelu Republican, Donald Trump, ti ri kojọ.

Wo bi Kamala ṣe de ipo igbakeji aarẹ Amẹrika

Ni bii ọdun marun un sẹyin ni Harris kọkọ gbe igbesẹ lati di aarẹ orilẹede Amẹrika.

O ti kọkọ ṣe agbẹjọro fun ẹkun Alameda laarin ọdun 2004 si 2011 niluu San Francisco.

Lẹyin naa ni Harris di agbẹjọro agba fun ipinlẹ California, oun si ni obinrin akọkọ ati alawọ dudu ti yoo dipo naa mu.

Lati ipo yii ni Arabinrin Harris ti dupo sẹnẹtọ lọdun 2016 ti o si wọle.

Amọ, erongba rẹ lati dupo aarẹ lọdun 2020 ko wa si imuṣẹ, awọn eeyan ko tẹwọ gba awọn eto to loun fẹ ṣe.

Amọ, Biden lo pe e wi pe ko wa ṣe igbakeji oun ninu eto idibo aarẹ to lọ l’Amẹrika.

Kamala Harris ati ọkọ rẹ Doug Emhoff di mọ ara wọn nibi apero ẹgbẹ oṣelu Democratic ni Chicago

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Arabinrin Harris ṣagbatẹru oniruuru iṣẹ gẹgẹ bi igbakeji aarẹ.

Oun naa lo tun ṣagbatẹru bibuwọlu ofin to din ọwọngogo nnkan ku lorilẹede Amẹrika.

Bakan naa ni o tun ṣiṣẹ lori ofin to ṣe iranwọ ati eyi to idẹrun ba Amẹrika lẹyin ajakalẹ arun covid-19.

Aarẹ Biden tun kepe Harris wi pe ko ṣagbatẹru akitiyan lati ṣewadi ohun to n ṣokunfa bi ọpọ eeyan ṣe n tu yaya wọ Amẹrika lati Mexico lai ni iwe igbeluu.

Ọrọ ibode Mexico ati Amẹrika yii jẹ ohun kan ti ọpọ eeyan ti n bu ẹnu atẹ lu Harris wi pe ko ṣe daadaa to.

Wọn ni lẹyin oṣu mẹfa ni Arabinrin to gbera lọ si ibode ọhun lati mọ ohun to n ṣẹlẹ nibẹ lẹyin iburawọle rẹ gẹgẹ igbakeji aarẹ Amẹrika.

Harris naa lo n ṣoju ijọba Democrat lori sisọ ewu ti fifofin de oyun ṣiṣẹ ti fa lẹyin ti ileẹjọ to ga julọ l’Amẹrika yi idajọ to fawọn eeyan lẹtọọ lati ṣẹyun lọdun 2022.

Nigba to n sọrọ nibi ipolongo kan, Arabinrin Harris di ẹbi ru Trump ati ẹgbẹ oṣelu Republican wi pe awọn lo fẹ fi ẹtọ awọn eeyan Amẹrika si oyin ṣiṣẹ dun wọn.

 Kamala Harris n bawọn eeyan sọrọ nibi ipolongo ṣaaju ibo aarẹ Amẹrika ni Chicago, Illinois, US, on Thursday, 22 August

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Arabinrin Harris n gbiyanju lati bawọn oludibo sọrọ pẹlu bi awọn iwadii kan ṣe fihan pe alato rẹ, Trump n sun mọ agbo oṣelu Amẹrika diẹ diẹ.

Lori ọrọ awọn eeyan to n wọ Amẹrika, ọrọ ẹtọ awọn akọ sakọ ati abo sabo, atawọn ọrọ mii ni Harris ti ri atako lasiko ipolongo ibo lọdun 2020.

Lẹyin ọdun mẹrin bayii, Arabinrin Harris n koju Trump gẹgẹ bi akinkanju.

Amọ, o tun n ṣeleri lati sẹto ti yoo daabo bawọn ẹbi to ri ṣe diẹ bi tiẹ.

O ni lati igba toun ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bi agbẹjọro, onibaara kan ṣoṣo loun ti ni eyi ti i ṣe awọn araalu.

Ibẹrẹ pẹpẹ Kamala Harris

Ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 1964 ni wọn bi Kamala Harris niluu Oakland, nipinlẹ California, ti awọn obi rẹ si jẹ ọmọ ilẹ okeere.

Ọmọ orilẹede India ni iya rẹ, Shyamala Gopalan Harris, nigba ti baba rẹ jẹ ọmọ ilẹ Jamaica.

Ko sọ ile nu nitori ọpọ igba lo maa n ṣabẹwo si India lati kekere.

O kawe lọpọ ile ẹkọ, lara awọn ile ẹkọ naa ni Howard University ati University of California College of the Law, San Francisco.

Bi o ṣe jẹ wi pe ọtọtọ ni orilẹede ti baba ati iya Arabinrin Harris ti wa yoo jẹ ki ọpọ ọmọ orilẹede Amẹrika fẹran rẹ.

Kamala ati aburo rẹ niyii pẹlu mama wọn nigba ti wọn wa ni ewe.

Oríṣun àwòrán, Kamala Harris

Àkọlé àwòrán, Kamala ati aburo rẹ niyii pẹlu mama wọn nigba ti wọn wa ni ewe.

Lita Rosario-Richardson ba Kamala pade nile ẹkọ giga fasiti Howard nigba ti wọn jọ jẹ akẹkọọ ni bii ogoji ọdun sẹyin.

Lita ni oun ṣakiyesi nigba naa wi pe Kamala fẹran ariyanjiyan.

Awọn mejeeji jọ n ṣe ọrẹ nigba naa, wọn si tun maa n kopa ninu itakurọsọ awọn akẹkọọ nibi ti wọn ti maa n ṣe ariyanjiyan gẹgẹ bii idije.

‘’Ronald Reagan ni aarẹ Amẹrika nigba naa, asiko yii si ni ọpọ maa n sọ pe awọn eeyan alawọdudu l’Amẹrika.

Awa naa mọ wi pe gẹgẹ bi ọmọ awọn eeyan dudu ti wọn ko lẹrun wa si Amẹrika, anfaani ẹkọ ti a n kọ ni fasiti yoo ro wa lagbara lati mu iyatọ ba igbe aye awọn alawọ dudu l’Amẹrika,’’ Rosario-Richardson lo sọ bẹẹ.

Amọ, Arabinrin Harris tun gbe laarin awọn ọmọ ilẹ Amẹrika to jẹ alawọ funfun.

Koda, o tun gbe ni orilẹede Canada nigba ti mama rẹ gba iṣẹ olukọ ni fasiti McGill niluu Montreal.

Harris gan an maa n ṣapejuwe ara rẹ bii ọmọ Amẹrika lai fi ti ẹya rẹ ṣe.

O ni bi oun ṣe ri tẹ oun lọrun lain nan an ni ohun ẹnikẹni le maa sọ nipa oun.

Ibẹrẹ ṣiṣe itakurọsọ Kamala

Ọrẹ rẹ Rosario-Richardson tun sọ pe lati ibẹrẹ ni Harris ti n ṣafihan awọn abuda kan eyi to jẹ ki o di ọkan lara awọn obinrin perete ti wọn ti ṣe nnkan to lamilaaka.

Rosario-Richardson ṣalaye pe ohun to jẹ koun pe e wi pe ki o wa darapọ mọ ẹgbẹ awọn akẹkọọ to n ṣe itakurọsọ ni gbangba ni fasiti Howard.

Bakan naa ni Harris tun maa n pa awọn eeyan lẹrin in nigba mii gẹgẹ bi o ṣe ṣe lẹyin toun ati Biden jawe olubori tan ninu ibo ọdun 2020.

Bi o ṣe rẹrin in nigba to pe Biden lori foonu lẹyin ti wọn jawe olubori ninu ibo aarẹ jẹ nkan ti ọrẹ rẹ ranti nipa Kamala.

Kamala, 'Momala', awọn to yi itan pada

Àkọlé fídíò, Gbọ bi wọn ṣe maa n pe ọrukọ Kamala

Kamala ṣe igbeyawo pẹlu Doug Emhoff lọdun 2014 nigba ti o fi wa nipo sẹnẹtọ ti o di iya fun ọmọ meji ti ọkọ rẹ ti ni tẹlẹ, Cole ati Ella.

Kamala sọ pe ‘’nigba temi ati Doug ṣe igbeyawo, Cole, Ella ati emi jọ sọ asọyepọ wi pe a o fẹẹ ki wọn maa pe mi ni orogun iya wọn.

Idi niyii ti a fi sọ pe ‘’Momala’’ ni ki wọn maa pe mi.’’

Cole, Ella ati baba wọn lo jọ lọ ṣe ayẹsi Kamala nibi apero ẹgbẹ oṣelu Democrat.

Maya to jẹ aburo Kamala naa, Meena to jẹ ọmọ aburo rẹ atawọn ọmọ ọmọ aburo rẹ wa nibẹ ni Chicago lati yẹ ẹ si.

Ọjọgbọn Nadia Brown to jẹ onimọ nipa ọrọ oṣelu ati itan awọn alawọdudu l’Amẹrika nile ẹkọ giga fasiti Purdue sọ fun BBC wi pe alakalẹ awọn eeyan nla nla bii Fannie Lou Hamer, Ella Baker, Septima Clark, atawọn mii ni Kamala n tẹle.

Atunṣe lori ohun to ṣẹlẹ lọjọ kejila oṣu Kẹjọ, ọdun 2024: Iroyin yii to jade ṣaaju sọ pe Kamala harris lo ibo rẹ lati buwọlu Adajọ Ketanji Brown Jackson si ile ẹjọ to ga julọ l'Amẹrika, eyi ko ri bẹ rara..

Aworan bana