Amẹ́ríkà gbé TikTok re ilé ẹjọ́ lórí ‘àkóbá’ tí áàpù náà ń ṣe fáwọn ọmọdé

Aworan ọmọde

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

O le ni ipinlẹ mejila lorilẹede Amẹrika to ti gbe ileeṣẹ itakun ori ayelujara TikTok lọ sile ẹjọ bayii lori ẹsun wi pe aapu naa n ṣakoba fun ilera ọpọlọ awọn ọmọde atawọn ọdọ.

Agbẹjọro mẹrinla kaakiri orilẹede Amẹrika lo fẹsun kan TikTok pe wọn n lo awọn nnkan to n jẹ kawon ọmọde fẹ maa lọ sori aapu naa ni gbogbo igba.

Awọn agbẹjọro ọhun ṣalaye pe ileeṣẹ TikTok ti ṣi araalu lọna lori eto abo ti wọn lo wa fawọn to ba n lo aapu naa fun igba pipẹ.

Eyi tun ti jẹ ki ẹsun ti wọn fi kan TikTok lekan sii lẹyin ti ile igbimọ aṣofin agba l’Amẹrika ṣe ofin kan loṣu Kẹrin ọdun yii pe ijọba yoo fofin de aapu naa, ayafi ti ẹni to ni ileeṣẹ China ọhun ba gba lati ta a loku.

Awọn ipinlẹ to gbe TikTok lọ sile ẹjọ ọhun sọ ninu iwe ipẹjọ wi pe ‘’TikTok naa mọ pe aapu awọn n ṣakoba fun ilera ọpọlọ ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu awọn ọmọde atawọn ọdọ l’Amẹrika.

Pẹlu ewu to wa ninu lilo TikTok yii fawọn ọmọde, ileeṣẹ naa si tun n sọ fun araalu pe aabo to peye wa fawọn ọmọde to n lo TikTok.’’

Agbẹjọro agba ipinlẹ New York, Letitia James, sọ pe ọpọ awọn ọdọ lo ti ku tawọn mii si ṣeṣe tori wọn n ṣe ohun ti wọn kọ lori aapu TikTok.

O ni awọn mii ni ọkan wọn si ti poruuru bayii ti inu wọn si tun bajẹ tori nnkan ti wọn n wo lori TikTok.

Arabinrin Letitia fi ọmọdekunrin ọmọ ọdun mẹẹdogun kan to ku ni Manhattan nibi to ti n ṣere gele to kọ lori TikTok lori ọkọ to n lọ ṣe apẹẹrẹ.

Nigba to ya ni iya ọmọ naa ri pe ọmọ rẹ ti n wo ere gele ọhun lori foonu rẹ tẹlẹ.

Agbẹjọro agba ipinlẹ New York ni TikTok duro lori ẹsẹ wọn pe aapu naa ko mewu dani fawọn ọmọde, o ni irọ to jina si otitọ ni eyi.

Ajọ to n ri si nnkan tawọn ọmọde n wo lori itakun ayelujara ti fi iru ẹsun yii naa kan Facebook ati Instagram fun ipa ti ko dara ti wọn ni awọn aapu ọhun n ni lori awọn ọdọ.

Ipinlẹ Texas ati Utah naa ti gbe wọn lọ sile ẹjọ fun idi kan naa.