Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Àkójọpọ̀ àwọn ìròyìn káàkiri Nàìjíríà tí kò ṣe é má gbọ̀ ọ́.
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Iṣẹ tiata lo gba ile ọkọ lọwọ mi, amọ mi o kabaamọ pe mo duro nidi iṣẹ naa

Agba oṣerebinrin, Taiwo akinwande, ti ọpọ mọ si Yetunde Wumi lo sọ bẹẹ

Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu BBC Yoruba, O ṣalaye bi irinajo naa se bẹrẹ lọdun 1982

O sọrọ lori awọn nnkan to la kọja ati awọn iriri to ri idi iṣẹ tiata

Fọnan ifọrọwerọ naa wa loju opo wa.

O seese ki owo hajj to milọnu mẹwaa naira tabi jubẹ lọ

Haa, eyi tun gbẹnutan

Ajọ NAHCON ni ijọba ti yọ owo iranwọ lori irinajo si Mecca

Awọn onimọ lori Hajj ati Umrah ba BBC sọrọ lori igbesẹ yii

ati ohun to jẹ ọna abayọ fun igbesẹ yii

Ekunrere n bẹ loju opo BBC.com/Yoruba

Aṣewo kan gun onibaara rẹ paa nipinlẹ Eko

Ileeṣẹ ọlọpaa ni oloogbe Okafor, gbe Joy wale lati ba a ṣere ifẹ ni agbegbe Lekki,

Amọ o kọlati fun un lowo ti wọn jọ duna-dura laaarọ ọjọ keji.

Ti Joy si fi ibinu gun un paa

Ẹkunrere iroyin n bẹ loju opo naa.