Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá tún ti palẹ̀ Speed Darlington mọ́- Agbẹjọro rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Youtube/Speed darlington
Gbajugba olorin takasufe, Speed Darlington, ẹni ti ọpọ mọ si AKPI ni ileeṣẹ ọlọpaa tun ti mu ṣahamọ.
Agbẹjọro rẹ, Deji Adeyanju lo kede ọrọ naa loju opo ayelujara rẹ lori ikanni X.
Adeyanju ni bi Akpi ni awọn ọlọpaa ilu Owerri lo Akpi si ahamọ kete to pada si orilẹede Naijiria.
Ohun to sẹlẹ ni pato ni ako ti mọ ṣugbọn bẹẹ ba gba, ni oṣu to kọja, Akpi lo ọjọ marun un ni ahamọ lẹyin to sọko ọrọ si akẹgbẹ rẹ Burna Boy.
Fidio kan to ti kari loju opo ayelujara bayii, ṣafihan ibi ti Speed Darlington ti n beere lọwọ Burna Boy nipa ọna to gba to fi ri ami ẹyẹ agbaye Grammy gba ni 2021.
Speed Darlington tawọn eeyan tun mọ si "Akpi", n beere ninu fidio naa pe ṣe Diddy fi epo pa idi rẹ ko too gba ami ẹyẹ nla naa ni.
" Ko pẹ ti Burna Boy gbe foto to ya pẹlu Diddy jade lo gba ami ẹyẹ Grammy.
" O kan n ya mi lẹnu ni, Burna Boy, mo n beere lọwọ rẹ, ma binu. Epo meloo ni Diddy da si idi rẹ ki wọn too fun ọ ni ami ẹyẹ yiii."
Bẹẹ ni Speed Darlington ṣe n beere ninu fidio ti wọn lo di wahala si i lọrun to fi di awati yii.

Oríṣun àwòrán, X.Deji Adeyanju
Gbajúgbajà akọrin tàkasúfèé, Speed Darlington di àwátì - Nǹkan tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Speed Darlington/X
Lati bii ọjọ meloo kan ni ariwo ti n sọ lori ayelujara nipa olorin taka-sufee, Speed Darlington Okoye, to deede di awati .
Iya rẹ, Queen Theresa, ti bẹrẹ si i ke gbajare lori ayelujara bayii, pẹlu alaye pe ọdọ awọn ọlọpaa ni ọmọ oun wa.
Queen Theresa ni ki awọn awọn ọlọpaa tu ọmọ oun silẹ, ati pe Burna Boy, olorin taka-sufe bii tiẹ lo gbe Darlington kuro nile rẹ.
Iya Speed sọ pe ẹni to n ṣọ geeti ile ọmọ oun lo jẹ koun mọ pe awọn kan ni wọn waa gbe Speed nile, lẹyin to ju fidio kan si ori ayelujara nipa Burna Boy.
“ Mo ṣẹṣẹ gbọ iroyin pe wọn o ri ọmọ mi. Ẹni to n ṣọ geeti ile rẹ lo pe awọn ẹbi mi, pe fidio kan wa ti Speed Darlington ṣe nipa Burna Boy." Bẹẹ ni iya Speed Darlington wi.
Kí ni Speed Darlington sọ nípa Burna Boy tó di wàhálà?
Fidio kan to ti kari loju opo ayelujara bayii, ṣafihan ibi ti Speed Darlington ti n beere lọwọ Burna Boy nipa ọna to gba to fi ri ami ẹyẹ agbaye Grammy gba ni 2021.
Speed Darlington tawọn eeyan tun mọ si "Akpi", n beere ninu fidio naa pe ṣe Diddy fi epo pa idi rẹ ko too gba ami ẹyẹ nla naa ni.
" Ko pẹ ti Burna Boy gbe foto to ya pẹlu Diddy jade lo gba ami ẹyẹ Grammy.
" O kan n ya mi lẹnu ni, Burna Boy, mo n beere lọwọ rẹ, ma binu. Epo meloo ni Diddy da si idi rẹ ki wọn too fun ọ ni ami ẹyẹ yiii."
Bẹẹ ni Speed Darlington ṣe n beere ninu fidio ti wọn lo di wahala si i lọrun to fi di awati yii.
Fidio ibi ti wọn ti gbe e naa ti n ja ran-in lori ayelujara, ṣugbọn ko ti i si ẹnikan to jade lati sọ pe oun mọ nipa bi Speed ṣe sọnu.
Koda, Burna Boy ti wọn fẹsun kan paapaa ko ti i wi nnkan kan ni gbogbo igba ti a fi ko iroyin yii jọ.
Olorin taka-sufee l’America ni Diddy ti Speed n wi, Sean John Combs gan-an lorukọ rẹ, oun naa si ti gba ami ẹyẹ nla Grammy ni igba mẹta.
Awọn ẹsun to jọ mọ ibalopọ akọ si akọ, oogun oloro ati ẹwọn sabaa maa n jẹyọ nipa Diddy.
Kí ni Deji Adeyanju, lọọya ajafẹtọọ ọmọniyan sọ nipa Speed Darlington?
Deji Adeyanju to jẹ lọọya to maa n ja fun ẹtọ ọmọniyan, ṣalaye loju opo X pe ọdọ awọn ọlọpaa ni Speed Darlington wa loootọ.
O ni awọn ti mọ ibi ti olorin taka-sufee naa wa, awọn yoo si sa gbogbo ipa lati tu u silẹ ni ahamọ ọlọpaa.
" A ti da si ọrọ Speed Darlington yii, a maa ri i pe o gba itusilẹ. Awọn alaṣẹ la n bẹ ki wọn ma da ọwọ bo ofin to faaye gba eeyan lati sọ ero ọkan rẹ.
Ogun to n doju kọ keeyan le sọ ero ọkan rẹ gbọdọ dopin ni Naijiria.’’ Amofin Deji Adeyanju lo sọ bẹẹ.
Ta a ni Speed Darligton?
Speed Darlington jẹ ọmọ akọrin Pericoma Okoye, to ku lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji ọdun 2017.
Iya rẹ ni Queen Theresa Onuorah.
Awọn eeyan mọ Speed Darlington fun bo ṣe maa n koro oju si awọn ohun ti ko ba tọ lagbo orin amuludun.
Ẹni ọdun mọkandinlogoji ni.
Awọn iṣẹ rẹ tawọn eeyan mọ daadaa ni "Greatest Tank Battle", "My Party", "Hustle Hard", ati "Let’s Dance."














