Wo ohun tó ń ṣẹ̀rùba ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Nàìjíríà àtàwọn ilẹ̀ òkèrè míràn l’Amẹrika nítorí ìpadàbọ̀ Trump

Donald J. Trump

Oríṣun àwòrán, Donald J. Trump

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn ile ẹkọ nilẹ Amẹrika ti bẹrẹ si n kọ iwe si awọn akẹkọọ wọn to jẹ ọmọ ilẹ okeere ati oṣiṣẹ pe ki wọn tete pada si ọgba ile ẹkọ wọn ṣaaju iburawọle Aarẹ tuntun, Donald Trump.

Ikilọ yii lo n waye lẹyin ibẹru pe Aarẹ Trump yoo le ọpọ ọmọ ilẹ okere pada si orilẹede wọn.

Trump funra rẹ ti sọ ṣaaju pe oun yoo mu ileri ipolongo ibo oun lati le awọn ọmọ ilẹ okere ti ko ni iwe igbelu pada silẹ wọn ṣe.

O ni oun ni ni yoo le iye eeyan to pọju ninu itan Amẹrika pada si orilẹede wọn.

Ọjọgbọn kan, Chloe East, ni fasiti Colorado sọ fun BBC pe ọpọ awọn akẹkọọ ni aya wọn ti n ja bayi latari ọrọ Trump.

Ẹwẹ, iroyin lati ọdọ ajọ Higher Ed Immigration Portal sọ pe nnkan bii ẹgbẹrun lọna irinwo akẹkọọ ti ko ni iwe igbelu lo n kawe l’Amẹrika.

Ọjọgbọn ọhun sọ siwaju si fun BBC pe inu ifoya ni ọpọ awọn akẹkọọ naa wa bayii nipa ohun ti wọn yoo ṣe lori iwe iriinna wọn.

Pupọ ninu awọn akẹkọọ naa ni ọkan wọn ko balẹ lori boya awọn yoo le tẹsiwaju ẹkọ wọn ti Trump ba gori oye tan.

Awọn fasiti wo lo ti kọ iwe ranṣe si awọn akẹkọọ wọn?

Ninu oṣu Kọkanla yii, fasiti Massachusetts ti fi iwe ranṣe si awọn akẹkọọ ati oṣiṣẹ rẹ.

Fasiti naa ni ki wọn wa ọna lati pada sile ọgba ẹkọ ki Trump to gba ọpa aṣẹ ijọba ninu oṣu Kinni ọdun 2025.

Bẹẹ naa ni ile ẹkọ Massachusetts Institute of Technology ti kọwe si awọn akẹkọo rẹ, to fi mọ fasiti Wesleyan.

Imọran ti wọn n fun awọn akẹkọọ ati olukọ naa ni pe ki wọn ri daju pe wọn ti pada sile ẹkọ ṣaaju iburawọle Trump ninu oṣu Kinni, ọdun to n bọ.

Wayi o, awọn akẹkọọ lati ilẹ Asia, paapaa orilẹede China lo ti n kigbe sita lori ọrọ naa.

Eyii ko ṣẹyin iabṣepọ Trump orilẹede wọn ti ko dan mọran.

Eeyan melo ni ko niwe igbelu l’Amẹrika?

Gẹgẹ bii ohun ti ẹka ijọba Department of Homeland Security ati ajọ Pew Research sọ, nnkan bii milioọnu mọkanla eeyan ni ko ni iwe igbelu nibẹ.

Apapọ iye eeyan naa jẹ ida 3.3% gbogbo eeyan ilẹ ọhun.

Pupọ ninu awọn ti ko ni iwe naa lo si ti pẹ gidi nilẹ ọhun ti ọpọ wọn i lo nnkan bi ọdun mẹwaa o le.