Ǹjẹ́ obìnrin yìí lè gbégbá orókè nínú ìbò Ààrẹ Namibia tó ń bọ̀?

Oríṣun àwòrán, AFP
- Author, Frauke Jensen
- Role, BBC News, Windhoek
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ti nnkan ba lọ gẹgẹ bii erongba ẹgbẹ oṣelu to wa lori oye ni Namibia, orilẹede naa yoo yan Aarẹ obinrin akọkọ nibẹ ni ọṣẹ yii.
Amọ ṣa o ṣeeṣe ki eyii ma ri bẹẹ latari awọn idi kan bii awọn ti ko fẹ ki ẹgbẹ oṣelu to wa lori oye tẹsiwaju lati maa tukọ orilẹede naa.
Netumbo Nandi-Ndaitwah, to jẹ igbakeji Aarẹ lọwọ yii ni oludije ẹgbẹ oṣelu SWAPO, to ti n tukọ orilẹede naa lati igba to gba ominira lọwọ South Africa lati ọdun 1990.
Aarẹ Tanzania, Samia Suluhu Hassan, nikan Aarẹ obinrin nilẹ adulawọ lọwọ yii, Nandi-Ndaitwah si le darapọ mọ gẹgẹ bii Aarẹ obirin to ba jawe olubori lọsẹ yii.
Ẹgbẹ oṣelu rẹ, to ti wa lori ipo fun nnkan bii ọgbọn ọdun ni awọn alatilẹyin rẹ dinku lasiko ibo gbogbogbo to kọja.
Ọludije marundinlogun mii lo tun n dije du ipo Aarẹ, ti Panduleni Itula ti ẹgbẹ oṣelu Independent Patriots for Change (IPC) jẹ ọkan gboogi lara wọn.
Yatọ si Itula, obirin naa tun n dije lorilẹde ti ọpọ eeyan rẹ gbagbọ pe ọkunrin lo yẹ ko wa nipo Aarẹ.
Yatọ si eyii, o jẹ oloṣelu kan ti awọn eeyan ni igbabọ ninu rẹ.
O ni “Mo ni igbagbọ ninu iṣẹ ajọsẹ, ohun lo mu mi ṣe aṣeyọri ti mo ti ṣe latẹyinwa titi ti mo fi ipo ti mo wa lonii.”
Ọmọ ọdun mẹrinla ni obinrin naa wa lasiko to darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu rẹ.
O si wa lara awọn to gbogun ti iṣejọba South Africa lorilẹede rẹ lasiko naa ti wọn n pe orilẹede ọhun ni South West Africa.

Oríṣun àwòrán, AFP
Lasiko kan, obinrin naa ni olori ọdọ ẹgbẹ SWAPO, eyii to mu ko gba iyi lawujọ awọn oloṣelu ẹgbẹ ọhun.
O ti kọ ọpọlọpọ ẹko ni ẹka eto oṣelu, bẹẹ lo ti ni ọpọ iriri nibẹ.
Lara awọn ọmọ ilẹ naa to ṣeeṣe ko dibo lọjọru, Laimi, sọ fun BBC niluu Windhoek pe “Ọ jọ eeyan daadaa ati ọlọgbọn eeyan to mọ ohun to n ṣe.”
Ọrẹ rẹ, Maria ni “Itula ni tirẹ da bii ẹṣọ ara pẹlu igo oju rẹ, o ja fafa, o si maa n mura daadaa amọ boya nnkan to fi n tan awọ eeyan jẹ niyẹn.”
Awọn mejeji ti a ba sọrọ yii jẹ ọdọ amọ ti wọn ko niṣẹ lọwọ.
Iṣẹ eto ilera eyin ni Itula kọ, o si ti fi akoko igba kan wa ninu ẹgbẹ oṣelu SWAPO ki wọn to le kuro nibẹ lọdun 2020 lẹyin to dije du ipo tako Aarẹ Hage Geinbob ninu idibo ọdun 2019.
Oun naa ti fi akoko igba kan jẹ olori ọdọ, o si ti ṣẹwọn ri ko to lọ ṣatipo nilẹ Gẹẹsi ni ibẹrẹ ọdun 1980.
Ọdun 2013 lo pada si Namibia, ọdun mẹfa lẹyin naa lo di ẹni iwaju ninu oṣelu ilẹ ọhun.

Oríṣun àwòrán, AFP
Nandi-Ndaitwah sọ pe oun n fẹ irẹpọ ati ifọwọsowọpọ laarin ijọba atawọn araalu.
Gẹgẹ bii obinrin to ni anfani lati de ipo Aarẹ, o n fun awọn obinrin orilẹde naa ni ireti ọjọ ọla rere.
Wayi o, onimọ nipa oṣelu orilẹede ọhun, Henning Melber, ti sọ pe bi ifigagbaga Nandi-Ndaitwah ati Panduleni Itula ṣe gbona to, o ṣeeṣe ki atundi ibo waye lẹyin ibo Aarẹ to n bọ.
Ni South Africa to wa lẹgbẹ orilẹede naa, ẹgbẹ oṣelu ANC to wa lori oye lati ọdun 1994 amọ lẹyin eto idibo oṣu Karun un, ẹgbẹ naa bẹrẹ si n pin agbara pẹlu ẹgbẹ alatako.
Ni Botswana, ẹgbẹ to wa lori oye naa lulẹ ninu idibo to waye nibẹ lẹyin ọgọta ọdun ti agbara ti wa lọwọ rẹ.
Ni bayii, SWAPO n sa ipa rẹ ki irufẹ nnkan bẹẹ ma ṣẹlẹ si oun naa lẹyin ibo ọla.












