Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan tí ilé alájà mẹ́rin dàwó, èèyàn 29 ló ti kú, wọ́n ti dóòlà èèyàn 88 míràn

Eeyan mọkandínlọgbọn lo ti ku ninu iṣẹlẹ ile alaja mẹrin to dawo ni ilu Dar es Salaam lorilẹede Tanzania.
Awọn alaṣẹ lorilẹede naa tun sọ pe eeyan mejidinlaadọrun ni wọn ti doola ẹmi wọn kuro labẹ awoku ile alaja naa.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, Thobias Makoba to jẹ agbẹnusọ fun ijọba orilẹede Tanzania ṣalaye pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ awọn ohun to ṣokunfa bi ile naa ṣe dawo.
Ọgbẹni Makoba fi kun un pe awọn agbofinro ti fi ṣikun ofin mu ọkan lara awọn to ni ile naa, gẹgẹbi ara igbesẹ iwadii.
“A ti mu u si ahamọ titi di igba ti ọkan awọn ọlọpaa yoo balẹ pẹlu awọn iroyin to titẹ wọn lọwọ pẹlu iwadii wọn.”
- Lẹ́yìn ìjà tó wáyé láàárín olùkọ́ àti olùgbé Ogbomoso, títìpa ni ilé ẹ̀kọ́ girama Are-ago wà
- Èèyàn mẹ́je farapa níbi ilé alájà méje tó dàwó l‘Eko, òṣìṣẹ́ kan sọnù, kò sẹ́ni tó kú - Ìjọba Eko
- Ìwádìí BBC rèé lórí ìdí tí ilé fi ń dàwó léra léra l'Eko
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko sọ̀rọ̀ lórí ilé alájà méjì tó dàwó lágbègbè Orile-Iganmu lọ́jọ́ Ajé
Bakan naa ni ijọba orilẹede naa tun ti paṣẹ ṣiṣi awọn opopona to wa lagbegbe ibi ti iṣẹlẹ naa, lati le mu ki iṣẹ okoowo o maa tẹsiwaju.
Amọṣa o, wọn ni ibudo ile to wo naayoo ṣi wa labẹ akoso awọn ọlọpaa, pẹlu bi awọn alaṣẹ ṣi ṣe n gbiyanju lati tu awoku ile naa palẹ.
Ni ọsẹ to kọja, Aarẹ Samia Suluhu Hassan ṣe abẹwo si agbegbe naa nibi to ti sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ pe aikun oju oṣuwọn awọn ohun elo ti wọn lo fun kikọ ile naa lo ṣokunfa ajalu naa.
Bakan naa lo paṣẹ iwadi si gbogbo awọn ohun elo ikọle to ti wọn n ta kaakiri ọja nla Kariakoo International Market lati le mọ awọn igbesẹ tuntun to yẹ ni gbigbe.
















