Okọ̀ ojú omi Egypt rì, èèyàn mẹ̀tàdínlógún di àwátì

Red Sea

Oríṣun àwòrán, Red Sea Governorate

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ijọba Egypt ti kede pe eeyan mẹrindinlogun, ninu eyi ti awọn ọmọ ilẹ okeere kan wa, lẹyin ti ọkọ irinajo afẹ oju omi kan ri si inu okun pupa.

awọn alaṣẹ orilẹede naa tun sọ pe, eeyan mejidinlọgbọn ni wọn ti doola ẹmi wọn ninu ijamba naa.

awọn meji lara awọn ti wọn ṣi n wa ni wọn jẹ ọmọ orilẹede Gẹẹsi,. awọn alaṣẹ orilẹede Finland pẹlu ti sọ pe ọkan lara awọn ero inu ọkọ igbafẹ oju omi naa to jẹ ọmọ orilẹede awọn ni wọn ṣi n wa, nigba ti awọn alaṣẹ orilẹede Egypt pẹlu ni ọmọ orilẹede naa mẹrin ni wọn wa lara awọn ti wọn n wa.

Nnkan bii aago marun un irọlẹ ni wọn fi ipe pajawiri ranṣẹ lati inu ọkọ oju omi naa to kuro ni ebute kan to wa lagbegbe Marsa Alam lọjọ Abamẹta fun irinajo ọlọjọ marun un.

Arinrinajo afẹ mọkanlelọgbọn ati oṣiṣẹ mẹrinla lo wa ninu ọkọ oju omi naa.

Gomina Red Sea, Ọgagun Amr Hanafi sọ fun awọn akọroyin pe agbegbe Wadi el-Gemal ni wọn ti ri awọn ti ori ko yọ lẹyin iṣẹlẹ ọhun.

O fi kun pe ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi Egypt ati ọkọ ofurufu ileeṣẹ ọmọ ogun ti n ṣiṣẹ takuntakun lati doola awọn to di awati.

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, ko si ẹni to tii le sọ ohun to ṣokunfa ijamba naa.

Ṣaaju ni ileeṣẹ to n ri si ọrọ oju ọjọ ni Egypt, Egyptian Meteorological Authority ti kọkọ sọtẹlẹ pe iji yoo ja lori okun Mediterranean ati Okun Pupa latari bi oju ọjọṣe ri.

Wọn ni afẹfẹ yoo fẹ ni iwọn bii ọgọrin kilomita laarin wakati kan ti omi naa yoo si ga ni iwọn mita mẹrin.

Iroyin ni ọmọ ilẹ Egypt ni gbogbo awọn oṣiṣẹ inu ọkọ oju omi naa nigba ti awọn arinrinajo afẹ inu rẹ jẹ awọn eeyan ilẹ mi bii Spain, UK, Germany ati Amẹrika.