Ìjọba Tinubu ní láti gbé ìgbésẹ̀ lórí àwọn ètò ìṣèjọba tó ń ni aráàlú lára - Àwọn Gómìnà PDP

Aworan awọn gomina ẹgbẹ oṣelu PDP

Oríṣun àwòrán, X/Ahmadu Umaru Fintiri

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn Gomina ẹgbẹ oṣelu PDP ti fi ẹhonu wọn han sita, ti wọn si ni awọn ba araalu kẹdun lori inira ti wọn lakọja nitori awọn ilana eto iṣejọba ẹgbẹ oṣelu APC labẹ Aarẹ Bola Tinubu.

Bakan naa ni wọn kesi Aarẹ orilẹede Bola Tinubu pe ko se atunṣe si awọn eto iṣejọba rẹ eyi ti wọn ni o n fa iniran fun araalu.

Ipade naa lo waye niluu Jos nipinlẹ Plateau, ti ọpọ awọn gomina si wa ni ijoko.

Bẹẹ ba gbagbe, Tinubu yọ owo ori epo rọbi kete to wọle sipo aarẹ, to si jẹ ọkan lara idi ti ọwọngog fi gbode lorilẹede Naijiria.

Awọn gomina naa ni awọn gbagbọ pe atunṣe si awọn ilana eto iṣejọba Tinubu yoo wa ojutu si inira araalu.

Alaga awọn Gomina PDP, Bala Mohammed ni, “A ba awọn ọmọ Naijiria kede lori iniria ti wọn n la kọja labẹ ijọba APC.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

“A n kesi Aarẹ Tinubu lati wa ọna abayọ si awọn eto iṣejọba yii ki araalu le jẹ igbadun ijọba.”

Mohammed fikun ẹgbẹ apapọ awọn Gomina ẹgbẹ oṣelu PDP yoo tun bọ lati ma wa tẹsiwaju awọn ipinlẹ wọn.

Lara awọn to wa nibi ipade naa ni Gomina lati ipinlẹ Bauchi, Zamfara, Taraba, Adamawa, Oyo, ati olugba alejo gomina ipinlẹ Plateau.