Mọ̀ nípa àwọn ọmọ Naijiria mẹ́jọ ti ọwọ́ tẹ̀ lókè òkun fún ẹ̀sùn ńlá -ńlá

Oríṣun àwòrán, AFP/Getty/ Others
Lọsẹ yii, ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Finland fi ṣikun ofin mu olori ẹgbẹ agbesunmọmi IPOB, Simon Ekpa.
Awọn alaṣẹ lorilẹede naa ni awọn mu Simon Ekpa fun ẹsun pe o sọ fun awọn eeyan pe ki wọn ma hu iwa jaduku.
Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria ni inu awọn dun pupọ a si bi awọn agbofinro orilẹede Finland se mu olori ẹgbẹ ajijagbara IPOB naa
Ki i se igba akọkọ ree ti awọn agbofinro yoo mu ọmọ Naijiria loke okun fun awọn ẹsun nla.
Eyi ni awọn ọmọ orilẹede mẹjọ ti wọn dero ahamọ ni orilẹede miiran
Simon Ekpa

Oríṣun àwòrán, Simon Ekpa/Twitter
Iroyin lati orilẹede naa sọ pe ile ẹjọ kan lagbegbe Päijät-Häme ti paṣẹ pe ki wọn lọ fi afurasi naa si ọgba ẹwọn fun akoko diẹ nibi ti yo yi maa gba atẹgun.
Ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin ọhun ni pe o n ru awọn eeyan soke lati wu iwa ọdaran pẹlu erongba igbesunmọmi.
Ile ọjọ naa sọ pe Simon Ekpa n pin ọrọ igbesunmọmi ati iyapa lori ayelujara.
Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2021 ni ọkunrin naa wu iwa ọdaran ọhun.
Igba keji ree ti ọwọ agbofinro yoo tẹ Ekpa ni Finland.
Igba akọkọ ti wọn mu ni inu oṣu keji ọdun 2023 amọ wọn fi silẹ lẹyin wakati diẹ.
Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọsu kẹfa ọdun 2021, ijọba Naijiria kede pe ọwọ tẹ olori ikọ adijagbara IPOB, Nnamdi Kanu ni orilẹede miiran.
Agbẹjọro agba fun orilẹede Naijiria lasiko naa, Abubakar Malami ko sọ orilẹede ti ọwọ ti Kanu.
Ṣugbọn iwadii fihan pe orilẹede Kenya ni ọwọ ti tẹ ti wọn si dapada si orilẹede Naijiria ni kiakia.
Kanu ti foju ba ile ẹjọ fun ọpọ igba, ti igbẹjọ si n lọ lọwọ lori ọrọ rẹ.
Tukur Mamu

Oríṣun àwòrán, Tukur Mamu
Ni ọdun 2022, ajọ DSS ni awọn Tukur Mamu, to da ọrọ ijinigbe awọn erọ ọkọ reluwe ti awọn agbegbọn jigbe ni laarin Abuja si Kaduna.
Agbẹnusọ DSS, Peter Afunanya ni ọwọ tẹ Mamu ni paapa ofurufu Cairo lorilẹede Egypt ni ọjọ Kẹfa oṣu kẹsan an ọdun 2022 nigba to n lọ si Saudi Arabia.
Wọn da Tukur Mamu pada si orilẹede Naijiria, ti iwadii si tẹsiwaju lori ọrọ rẹ.
Umar Farouk Abdulmutallab

Oríṣun àwòrán, AFP
Ni oṣu keji ọdun 2012, ile ẹjọ kan lorilẹede Amẹrika ran ọmọ orilẹede Naijiria kan si ẹwọn egbere lẹyin ti ọwọ tẹ lasiko to mu ina si ado oloro.
Umar FAROUK Abdulmutallab ni o jẹjọ pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fikan pe o fẹ tan ina si ado olodo ninu baalu.
O le ni eeyan 300 to wa ninu baalu naa ni ọjọ keresimesi lọdun 2009.
Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, SUNDAY IGBOHO
Ni ọsu keje ọdun 2021, awọn alaṣẹ ijọba Bebin mu Sunday Adeyemo, ẹni ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ni paapa ofurufa.
Eyi waye lẹyin ti DSS sekọlu si ile rẹ niluu Ibadan .
Igboho wa ni ahamọ lorilẹede Benin fun ọdun meji ki wọn to tu silẹ.
Lawal Babafemi

Oríṣun àwòrán, Lawal Babafemi
Ni oṣu kẹjọ ọdun 2015, ileẹjọ kan ni New York lorilẹede Amẹrika ran Lawal Olaniyi Babafemi, ẹni to jẹ ẹni ọdun marundinlogoji lasiko naa lọ ẹwọn fun ọdun mejilelogun lẹyin ti iwadii ni o jẹ bi ẹsun sisẹ papọ pẹlu ikọ adijagbara al-Qaeda.
Babafemi jẹwọ ẹsun naa ti wọn fi kan laarin ọdun 2010 si 2011, to si ni oun kuro lorilẹede Naijiria lọ si Yemen lati lọ gba idanilẹkọ lori sise ikọlu ati iwa ọdaran.
Ramon Abbas - Hushpuppi

Oríṣun àwòrán, Hushpupi Instagram
Ni oṣu kẹfa ọdun 2020, ọwọ tẹ Ramon Abbass, ẹni ti ọpọ mọ si Huspuppi lorilẹede UAE fun ẹsun gbigba awọn eeyan lori ayelujara.
Wọn dapada si orilẹede Amẹrika lati lọ foju ba ile ẹjọ.
O le ni milọnu meji eeyan to ko sọwọ Huspuppi, to si gba wọn.
Ileẹjọ ran lọ si ẹwọn ọdun mọkanla lẹyin ti iwadii o jẹ ẹsun naa.
Bakan naa ni ile ẹjọ ni ko san owo toto $1,732,841 fun awọn eeyan meji to lu ni jibiti.
Ike Ekweremadu ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, MET POLICE
Agba ọjẹ oloṣelu lorilẹede ni ọwọ tẹ niluu UK fun ẹsun pe o n ra ẹya ara eniyan.
Paapa ofurufu Heathrow ni ọwọ ti aarẹ ile igbimọ aṣofin tẹlẹ.
Bi wọn se mu lo da ọpọ rogbodiyan silẹ ni Naijiria ati ni ita Naijiria.
Awọn alaṣẹ UK fi Ekweremadu sinu ahamọ niluu London ti igbẹjọ rẹ si n tẹsiwaju.
Ṣugbọn ni ọdun 2023, ileẹjọ ran oun ati iyawo rẹ si ẹwọn ọdun mẹsan an lẹtin ti iwadii ri pe wọn jẹbi ẹsun naa.















