Bí mo ṣe di ẹni tó ń tọrọ oúnjẹ jẹ lẹ́yìn tí mo di ìlúmọ̀ọ́ká tán - Olajumoke Oníbúrẹ́dì

Aworan Olajumoke Orisaguna

Oríṣun àwòrán, Olajumoke Orisaguna/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Arabinrin Olujumoke Orisaguna to di ilumọọka lọdun 2016 lẹyin ti gbajugbaja ayaworan T.Y. Bello gba igba burẹdi to n kiri lori rẹ ti ṣalaye ohun to ṣẹlẹ si i lẹyin t'awọn eeyan mọ ọn tan.

Ṣebi ori ti yoo gbeni ni i gbe alawore koni, nibi ti Arabinrin Bello ti n ṣiṣẹ fọto rẹ lo ti gan-an ni Jumoke to n ta burẹdi niluu Eko.

Níbẹ ni Bello ti wo arabinrin naa pe o le maa ṣiṣẹ arinrin oge pẹlu ẹwa ti Eledua fi jinki rẹ.

Bayii ni nǹkan yi pada fun Jumoke oniburedi ti o si di ẹni t'awọn eeyan n ri fọto rẹ ninu iwe iroyin.

Koda, awọn ileeṣẹ redio ati telifisan naa n f'ọrọ wa Jumoke lẹnu wo.

Ṣadeedee ni nnkan yi pada fun Jumoke oniburedi

Ni bii ọdun mẹrin sẹyin ni nnkan ṣadeedee yi biri fun Jumoke ti o si padanu owo ati gbogbo nnkan to ti kojọ.

Koda, gbogbo awọn ti wọn n pe e ni apegba tẹlẹ ko pe e mọ.

Ohun ti a gbọ ni pe ẹni to n ṣe akoso gbogbo nnkan ti Jumoke n ṣe lo lu u ni jibiti ti o fi padanu gbogbo nnkan to ni.

Jumoke ni ẹni to n ṣiṣẹ pọ pẹlu oun yii lo ṣe owo oun kumọ kumọ nipa oriṣiiriṣii idokowo ti ko kẹsẹ jari.

Jumoke fidi ọrọ yii mulẹ nibi eto kan ti wọn pe ni "Ipadabọ Olujumoke Oniburedi."

"Oju mi ri to, mo padanu gbogbo nnkan.

Ẹni to n ṣakoso iṣẹ mi yii gbe mi lọ si orilẹede South Africa ni igba meji ọtọọtọ, amọ, emi ni mo sanwo baalu ti a wọ ati owo ile itura ti a lo.

N50,000 pere lo fun mi nigba ti a pada si Naijiria.

Mi o lowo kankan mọ, gbogbo kan ni mo padanu.

Bayii ni mo bẹrẹ si ni pe awọn eeyan ki wọn ran mi lọwọ lati le jẹun.

Aunti Azuka Ogunjuiba ati TY Bello lo ṣe iranwọ fun mi.

Arabinrin Azuka lo san owo ile mi, o si tun gba ṣọọbu fun mi.

Oun naa lo n fi ounjẹ ranṣẹ si mi t'awọn ọmọ mi naa fi n ri ounjẹ jẹ.

Nnkan le fun mi nigba naa."

Jumoke ni oun ti kẹkọọ bayii wi pe oun ko ni fi awọn to fẹ ilọsiwaju oun silẹ mọ.