Ọ̀pọ̀ ọmọdé pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìwọ́de tako ìjọba ní Mozambique

Ìyá Antonio Juaqim ń sunkún níbi pósí rẹ̀ tóbìnrin mìíràn sì n rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún

Oríṣun àwòrán, Anthony Irungu / BBC

    • Author, Ian Wafula
    • Role, BBC News, Maputo
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Àwọn ọ̀dọ́ tó fi mọ́ ọmọdé ló ń ṣe omi lójú gbéré bí wọ́n ṣe ń dágbére ìkẹyìn fún ọ̀rẹ́ wọn, ẹni ọdún mẹ́rìndínlógú tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lásìkò ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn.

Lásìkò ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn tako ètò ìdìbò ààrẹ tó wáyé ní orílẹ̀ èdè Mozambique lóṣù tó kọjá ni ìbọn ti ba Antonio tí wọ́n sì sin òkú rẹ̀ sí itẹ́ òkú tó wà ní olú ìlú orílẹ̀ èdè náà, Maputo.

“Ẹnu ni wọ́n ti yìnbọn fún Antonio, tí ọta ìbọn náà sì jáde lẹ́yìn orí rẹ̀,” ìbátan rẹ̀, Manuel Samuel sọ fún BBC.

Wọ́n ní àwọn rí fídíò bí àwọn ọlọ̀pàá ṣe ń yìnbọn sáwọn olùwọ́de níbi ẹ̀rọ ayàwòrán tó wà láwọn ṣọ́ọ̀bù kan tó wà ní agbègbè náà.

Ṣíṣekúpa Antonio Juaqim jẹ́ ìrántí nípa bí orílẹ̀ èdè Mozambique, tó wà ní gúúsù ilẹ̀ Áfíríkà, ṣe ń gbònà láti ìgbà ti wọ́n ti kéde ẹgbẹ́ òṣèlú Frelimo - ẹgbẹ́ tó ti ṣe ìjọba láti ọdún mọ́kàndínláàádọ́ta sẹ́yìn tí orílẹ̀ èdè náà ti gba òmìnira - gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ tó tún jáwé olúborí ìbò ààrẹ.

Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní orílẹ̀ èdè ọ̀hún kéde pé olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú Frelimo, Daniel Chapo rí ìbò ìdá mọ́kànléláàádọ́rin (71%) níbi ètò ìdìbò náà, tí ẹni tó sì súnmọ jùlọ, Venâncio Mondlane rí ìbò ìdá ogún (20%).

Àlùfáà ìjọ ẹ̀sìn kan ti òun náà díje níbi ètò ìdìbò náà gẹ́gẹ́ bí ọlọ́danni lẹ́yìn tó kúrò ní ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò, Renamo party, Mondlane ní òun kọ èsì ìdìbò náà àti pé èèrú wáyé níbi ètò ìdìbò náà.

Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní irọ́ ni pé àwọn ṣe èèrú ìbò àmọ́ Mondlane - ẹni tó ti sá kúrò ní orílẹ̀ èdè náà nítorí é ó bẹ̀rù kí wọ́n má fòfin gbe – ń sọ fún àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ lóri ayélujára pé kí wan ṣe ìwọ́de tako èsì ìdìbò náà.

Ní aago mẹ́sàn-án alaalẹ́ ni àwọn èèyàn máa ń lu abọ àti pọ́ọ̀tì wọn, ní ìdáhùn sí ìpè Mondlane pé àwọn kò faramọ́ kí ìṣèjọba ẹgbẹ́ òṣèlú Frelimo tún tẹ̀síwájú.

Obìnrin tó ń fọn fèrè pẹ̀lú àwọn lùfẹ̀hónúhàn mìíràn ní Maputo, Mozambique
Àkọlé àwòrán, Àwọn alátìlẹyìn Venâncio Mondlane ń fẹ́ àyípadà ìjọba
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Samuel ṣàlàyé pé alẹ́ ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kọkànlá ni ìwọ́de náà kọ́kọ́ wáyé nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tú jáde lati ṣe ìwọ́de tí wọ́n sì ń lu agbada, ìgò àtàwọn nǹkan míì láti fi súfèé.

“Níṣe ló dàbí pé wọ́n ṣe àtúnbí Mozambique.”

Ó sọ pé àmọ́ níṣe ni ìwọ́de náà parí pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ tó lágbára, tí Antonio sì wà lára àwọn tí ọlọ́pàá yìnbọn pa lọ́jọ́ náà.

Láti ìgbà inu ilé ni àwọn èèyàn ti máa ń lu abọ àti agbada wọn káàkiri gbogbo ìlú Maputo tó bá ti di aago mẹ́sàn-án alẹ́.

Níbi ètò ìsìnkú Antonio tó wáyé ní itẹ́ òkú São Francisco Xavier Cemetery lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin tí wọ́n ṣekúpa á, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ gbé oríṣiríṣi òdòdó sí orí sàárè rẹ̀, tí wọ́n sì bẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ fèrè sórí rẹ̀, láti fi se ìrántí pé ọmọdé ni.

Samuel sọ fún BBC pe òkú àwọn ọmọdé mẹ́fà ni òun kà ní ilé ìgbókùúpamọ́sí.

“Wọ́n ń ṣekúpa wá àti ọjọ́ ọ̀la wa.”

Àjọ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn, Human Rights Watch sọ pé èèyàn ogójì, tó fi mọ́ àwọn ọmọdé mẹ́wàá ni àwọn ọlọ́pàá ṣekúpa níbi ìwọ́de náà.

Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Mozambique, Bernadino Raphael bá ẹbí àwọn èèyàn tó pàdánù ẹ̀mí wọn dẹ́kùn àmọ́ tó di ẹbí ikú wọn ru àwọn alátìlẹyìn Mondlane.

Raphael sọ fún BBC pé àwọn èèyàn náà lo àwọn ọmọdé láti fi dá ààbò bo ara wọn, tí wọ́n sì ń ti àwọn ọmọ náà síwájú.

Ó ní kò sí nǹkan táwọn ọlọ́pàá lè ṣe ju pé kí wọ́n dá ààbò bo ara wọn nítorí àwọn ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìwà ipá sáwọn ọlọ́pàá, pa ọlọ́pàá mẹ́fà, jo dúkìá àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ okọ̀.

“Èèyan 103 ló farapa, tí69 nínú wọn sì jẹ́ ọlọ́pàá.”

Ọkọ̀ tí wọ́n dáná sun lásìkò ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn lẹ́yìn ètò ìdìbò gbogogbò ní Maputo, Mozambique

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn Mozambique kọminú lórí ọjọ́ iwájú orílẹ̀ èdè náà lẹ́yìn ìwà ipá tó wáyé lẹ́yìn ètò ìdìbò

Ṣùgbọ́n Albino Forquilha, olórí ẹgbẹ́ òṣèlú Optimist Party for the Development of Mozambique tó ṣe àtìlẹyìn fún Mondlane fẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá pé wọ́n lo ìwà ipá lórí àwọn èèyàn.

Ó ní àwọn ọlọ́pàá náà ṣiṣẹ́ bí ẹni tó ń dá ààbò bo ẹgbẹ́ tó ń ṣe ìjọba.

Onínọ̀ nípa nípa ètò ààbò tó fi South Africa ṣe ibùjókòó, Borges Nhamirre sọ pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí ìpànìyàn àti bíba dúkìá jẹ́ lásìkò ìwọ́de máa wáyé ní orílẹ̀ èdè Mozambique.

Ó ní ó hàn gbangba pé àwọn èèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ gba ti ẹgbẹ́ òṣèlú Frelimo mọ́, pàápàá àwọn ọ̀dọ́ tó ń wá ìgbé ayé tó rọrùn nípa iṣẹ́, ibùgbé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Nhamirre ní àwọn ọ̀dọ́ náà kò náání ẹni tó gba òmìnira fún orílẹ̀ èdè bíkòṣe bí wọ́n ṣe máa rí òmìnira nípa ètò ìsúná wọn.

Lẹ́yìn tí wọ́n kéde èsì ìbò lọ́jọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Kẹwàá, Chapo tẹnumọ pé òun àti ẹgbẹ́ òṣèlú Frelimo jáwé olúborí nípa ṣíṣe ètò ìdìbò tí kò ní ẹja ń bákàn nínú.

Láti ìgbà náà ló ti ń ṣe pẹ̀lẹ́ ní ìrétí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ lórí ẹjọ́ tí Mondlane pè láti wọ́gilé ìbò náà.

Bíi Antonio, Alito Momad, ẹni ogún ọdún ni wọ́n ní àwọn ọlọ́pàá ṣekúpa lásìkò ìwọ́de kan náà.

BBC ṣe alábàápàdé àwọn ọ̀rẹ́ ẹ rẹ̀ ní agbègbè kan lẹ́bàá Maputo, tí wọ́n ń ṣe ìsìn ìkẹyìn fún-un lọ́jọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù Kọkànlá.

Àwọn ọ̀rẹ́ ẹ rẹ̀ fi àwòrán rẹ̀ han BBC tí a sì rí ohun tó dàbí ọgbẹ́ ìbọn lẹ́yìn orí ẹ̀.

Ó jẹ́ ìrántí bí ètò ìdìbò náà ṣe ti gé ẹ̀mí àwọn èèyàn kúrú pàápàá àwọn ọ̀dọ́, táwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn sì ní ìrètí pé wọ́n máa rí ìdájọ́ òdodo gbà lórí ikú àwọn èèyàn wọn bí Mozambique ṣe ń la ìgbà tó le kọjá láti ìgbà tí wọ́n ti ní ẹgbẹ́ òṣèlú púpọ̀ láti bíi ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn.