"A ti ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ sí ń ti àwọn ṣọ́ọ̀bù tẹ́tẹ́ pa"

Ọlọpaa sharia ipinlẹ Kano ti sọ pe oun yoo pada bẹrẹ si n gbogun ti awọn to n ta tẹtẹ bayii nipinlẹ ọhun, paapaa awọn ṣọọbu tẹtẹ.
Igbesẹ yii lo n waye lẹyin idajọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria to wọgile ofin to ṣe idasilẹ ajọ to n ri si ọrọ titẹ tita ni Naijiria lọjọ Eti.
Ofin ọdun 2005 ọhun lo fidi rẹ mulẹ pe awọn araalu lẹtọọ lati maa ta oniruru tẹtẹ.
Ile ẹjọ to ga julọ ti wa sọ pe ijọba ipinlẹ nikan lo lagbara lati sọrọ tabi paṣẹ lori tẹtẹ tita.
Lẹyin idajọ yii, ọlọpaa Sharia ipinlẹ Kano ti sọ pe inu awọn dun si idajọ naa ati pe awọn yoo bẹrẹ sin fi imu awọn onitẹtẹ danrin bayii, paapaa awọn ṣọọbu ti awọn eeyan ti n ta tẹtẹ ọhun.
Ipinlẹ Kano jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ ti awọn Musulumi pọju si ni iha Ariwa Naijiria ti wọn si n lo ofin Sharia.
Adari Hisbah, Abba Sufffi, sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP ninu ifọrọwerọ kan pe “A o pada bẹrẹ si n ti awọn ṣọọbu tẹtẹ ni bayii to ti lodi si ofin Sharia ipinlẹ Kano lati maa ta tẹtẹ.”
Oṣu to kọja ni Hisbah ti kọkọ ti ọpọ ṣọọbu pa ni Kano lẹyin ti wọn ni awọn ṣọọbu naa n tapa si ofin Sharia.
Suffi ni amọ awọn dawọ iṣẹ naa duro lẹyin ti ajọ to n ri si ọrọ tẹtẹ ni Naijiria, National Lottery Commission, sọ pe tẹtẹ ko lodi si ofin.
O tẹsiwaju pe “Pẹlu idajọ yii, ko si aniani nipa ẹni to lagbara lori tẹtẹ laarin ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ mọ.
“Awa ni Kano ko faramọ ofin to gbe lẹyin tẹtẹ lati ilẹ.... nitori ofin naa gbe lẹyin tẹtẹ tita eyii to jẹ eewọ ninu ẹsin islam.”
O pari ọrọ rẹ pe ọpọ awọn obi lo maa n fi ẹjọ awọn ọmọ wọn to n ta tẹtẹ sun ikọ agbofinro naa.
Wayi o, nnkan bhii igba ṣọọbu tẹtẹ lo laarin ilu Kano.















