Ṣé lóòótọ́ ni pé àwọn aráàlú yóò san owó gba káàdì ìdánimọ̀ NIN?

Oríṣun àwòrán, NIMC
Ajọ to n risi idanimọ lorilẹede Naijiria NIMC ni awọn ọmọ Naijiria yoo ni lati san owo gba kaadi idanimọ NIN tuntun to ni ọpọ iwulo.
Olori fun ẹka to n risi kaadi gbigba, Peter Iwegbu lo kede eyi lasiko ipade ọlọjọ meji to se pẹlu awọn akọroyin nipinlẹ Eko.
O ni owo yii wa fun pipese kaadi naa fun awọn eeyan to nilo rẹ nikan.
Iwegbu ni awọn gbe igbesẹ naa lati ri pe awọn ko ṣe asisẹ ti tẹlẹ lori pipese kaadi naa fun awọn araalu lọfẹ ti ọpọ ko si pada gba kaadi naa.
“Bi ijọba se ti din owo nina ku lo fa ti awọn araalu yoo fi san owo lati gba kaadi yii,”
Bakan, agbẹnusọ NIMC, Lanre Yusuf ni fifun awọn araalu ni kaadi ọfẹ ni ko so eso rere fun ajọ naa.
Yusuf ni bayii, eeyan to ba nilo kaadi naa ni yoo bẹrẹ fun, ki awọn to pese rẹ.
”Lati gba kaadi tuntun, araalu yoo san owo, yoo sọ ibi ti yoo ti gba ti a ba fi ransẹ si.
Yusuf ni NIMC yoo se ifilọlẹ kaadi tuntun to ni ọpọ iwulo laipẹ fun araalu.
Bakan naa lo fikun pe awọn ti ba awọn ileeṣẹ ifowopamọ sọrọ lati le jẹ ki awọn eeyan ma gba kaadi naa ni awọn ẹka ile ifowopamọ kaakiri Naijiria.















