Ìdí táwọn Ọba alayé àtàwọn oníṣẹ̀ṣe fi gbọdọ̀ jọ ṣiṣẹ́ pọ̀ - Gani Adams

Aworan Iba Gani Adams

Oríṣun àwòrán, Iba Gani Adams/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Aarẹ Onakakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, ti pe fun iṣọkan laarin awọn ọba alade at'awọn oniṣẹṣe ni ilẹ Yoruba.

Iba Gani Adams sọrọ yii lasiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ ICIR ti wọn jẹ ẹlẹsin Ifa ṣe abẹwo si i nile rẹ niluu Eko.

Aarẹ ẹgbẹ awọn ẹlẹṣin Ifa, Ọmọwe Fayemi Fakayode sọ pe abẹwo awọn si Iba Adams ko ṣẹyin ati mu ilosiwaju ba ilẹ Yoruba ki alaafia si jọba nibẹ.

Ọmọwe Fakayode ni ohun tawọn n fẹ ni ki iṣọkan ati ibaṣepọ wa laarin awọn olori Yoruba at'awọn ọba alaye ki idagbasoke le ba ilẹ Yoruba.

Ninu ọrọ rẹ, Iba Gani Adams lu awọn ọmọ ẹgbẹ ẹlẹsin Ifa lọgọ ẹnu.

O ni awokọṣe rere ni iwa Ọmọluwabi ti wọn n hu jẹ.

Iba Adams wa rọ awọn oniṣẹṣe pe ki wọn ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹgbẹ awọn ẹlẹṣin Ifa tori ibasepọ laarin wọn lo le mu iṣọkan ati igbasoke wa.

"Mo ke pe gbogbo ọmọ Yoruba lagbaaye lati maa lepa alaafia, iṣọkan ati aabo ilẹ wa.

Bakan naa ni ẹbẹ mi yii tun lọ sọdọ gbogbo ọba ilẹ Yoruba.

Mo rọ yin pe ki ẹ jẹ ki a wa ni iṣọkan ki a si maa gbe aṣa ati ìṣe wa larugẹ.

Eyi nikan lo le mu ilọsiwaju ba ilẹ Yoruba," Gani Adams lo sọ bẹẹ.

Iba Gani Adams ni gbigbe aṣa ati ìṣe Yoruba larugẹ le ṣe itaji ọrọ aje to n ṣojojo.

O wa rọ awọn ọba alade at'awọn oniṣẹṣe pe ki wọn jẹ awokọṣe rere fun araalu.