Agbébọn kọlu ọkọ̀ akérò ní Pakistan, èèyàn 41 jáde láyé, 16 míì farapa

Oríṣun àwòrán, EPA-EFE/REX/Shutterstock
O kere tan, eeyan mọkanlelogji, ti obinrin ati ọmọde wa lara wọn, lo ti jade laye ni Pakistan lẹyin ti awọn agbebọn ṣadede ṣina ibọn fun ọkọ ero kan to n lọ lẹba ọna.
Asiko ti wọn n rinrinajo lagbegbe Kurram, to sunmọ ala ilẹ naa pẹlu Afganistan ni iṣẹlẹ ọhun waye.
Agbẹnusọ ọlọpaa agbegbe ọhun ni ṣe ni awọn agbebọn naa kọkọ doju kọ ọkọ awọn ọlọpaa to wa pẹlu awọn eeyan naa.
Awọn ọlọpaa naa lo n daabo bo awọn ero ọkọ ọhun lẹyin oniruru irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ to ti waye ṣeyin.
Ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ naa sọ fun BBC pe eeyan mọkanlelogoji lo jade laye, ti awọn mẹrindionlogun mi si farapa yanayana.
Aṣoju ijọba lagbegbe Khyber Pakhtunkhwa, Nadeem Aslam Chaudhry sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ eyii to gba omije loju awọn.
Ọkan lara awọn ero inu ọkọ ọhun, Saeeda Bano sọ fun BBC pe abẹ aga inu ọkọ ni oun sapamọ si, ti oun si n woye pe ọlọjọ ti de ni bo ṣe n gbọ iro ibọn lakọlakọ.
O ni lẹyin ti iro ibọn naa wa sopin loun jade ti oun si ri ọpọ ẹjẹ nilẹ, to fi mọ oku awọn eeyan atawọn to farapa.
Iroyin ni apapọ agbebọn mẹwaa lo ṣiṣẹ laabi naa.
A gbọ pe ṣe ni awọn ọmọde atawọn obinrin fi ara pamọ sinu igbo lẹyin ti ọlọpaa de ibi ti ikọlu naa ti waye.
Aṣoju ijọba kan, Javed ullah Mehsud, sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe pupọ ninu awọn ti ọrọ naa kan lo jẹ Musulimi Shia.
O ti pẹ ti ija ti n waye laarin awọn Musulumi Shia ati Sunni ni Afganistan.















