Àwọn òṣìṣẹ́ ìlera wọ gau lórí ikú àwọn ọmọdé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Ege Tatlici
- Role, BBC News Turkish
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Níṣe ni àwọn èèyàn kan ní orílẹ̀ èdè Turkey ti ń pè fún ìwádìí tó lòòrìn lórí ẹ̀sùn pé àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn ìjọba ní orílẹ̀ èdè náà máa ń mọ̀ọ́mọ̀ darí àwọn ọmọ ìkókó lọ sí ilé ìwòsàn aládàni.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó ti ṣokùnfà ikú àwọn ọmọdé mẹ́wàá tó sì ń fa awuyewuye ní orílẹ̀ èdè ọ̀hún.
Àwọn èèyàn náà ń fẹ̀sùn kan àwọn dókítà, nọ́ọ̀sì àtàwọn awákọ̀ ọkọ̀ adóòlà ẹ̀mí pé wọ́n máa ń parọ́ pé nǹkan ń ṣe ọmọ ìkókó, tí wọ́n sì máa darí wọn láti gbé ọmọ náà lọ sí ilé ìwòsàn tó jẹ́ ti aládàni, níbi tí wọ́n ti máa gbé àwọn ọmọ náà sínú yàrá tó wà fún ìtọ́jú ló lágbára fún ìgbà pípẹ́.
Ní oṣù Kọkànlá ọdún 2016, ìyàwó Tolga Oymak, Nukhet bí ìbẹta sí ilé ìwòsàn tó lórúkọ ní Turkey.
Oṣù àwọn ọmọ náà kò ì tíì pé tí ìyà wọn fi wọ́n tí wọ́n sì nílò kí wọ́n gbé àwọn ọmọ ọ̀hún sínú ìgò àmọ́ ilé ìwòsàn náà kò ní ìgò mẹ́ta tí yóò gba àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.
Èyí ló mú kí àwọn ẹbí wá ilé ìwòsàn mìíràn tí wọ́n sì darí wọn lọ síbẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Tolga sọ fún BBC News Turkish pé ní ọjọ́ kẹta ni ọ̀kan nínú àwọn ìbẹta náà jáde láyé, tí wọ́n sì sọ fun pé èémí ọmọ náà ni kò ṣe dáadáa.
“Ó ku àwọn méjì, àwọn dókítà sì sọ fún wa pé àwọn méjéjèjì wà ní àláfíà.”
Àmọ́ nígbà tó di ọjọ́ márùn-ún lẹ́yìn ìgbà náà, dókítà kan pe Tolga pé kó máa bọ̀ ní ilé ìwòsàn pé èémí ọ̀kan lára àwọn ọmọ méjì tó kù kò ṣe dada mọ́.
“A ò lè wọ inú yàrá tí wọ́n gbé wọn sí àmọ́ à ń wo bí ẹ̀mí ṣe bọ́ lára ọmọ náà ojú fèrèsé ta wà.
“Ẹ ti pa méjì nínú àwọn ọmọ mi, ṣé ẹ fẹ́ pa ọ̀kan tó kù ni? Mo sọ fún àwọn òṣìṣẹ́ ìlera náà, wọ́n ní kí n fara balẹ̀.”
Lílu iléeṣẹ́ ìjọba ní jìbìtì
Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn, àwọn ọmọdé náà tí wọ́n ń darí sí ọ̀kan lára àwọn ilé ìwòsàn aládàni mọ́kàndínlógún ni wọ́n máa ń fún ní ìtọ́jú tí wọn kò nílò lójúnà à ti fi gba owó lákoto ìjọba.
Àwọn òṣìṣẹ́ ìlera náà táwọn iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé ní Turkey ń pè ní “the newborn gang” máa ń gbà tó owó ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ liras, owó Turkey lójúmọ́ kan, fún pé ọmọ kan ń sun ẹ̀ka náà.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ó kéré tán, ọmọ mẹ́wàá ni wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó ti jáde láyé látàrí ìwà àìbìkítà àti ìwà kò tọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ọ̀hún.
Èèyàn mẹ́tàdínláàádọ́ta ni wọ́n kojú ìgbẹ́jọ́ ní Instabul lọ́sẹ̀ yìí. Èèyàn méjìlélógún lára àwọn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn ló ti wà ní àhámọ́ òfin.
Àwọn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn náà ní àwọn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n kà sáwọn lọ́rùn àti pé gbogbo ìgbésẹ̀ táwọn gbé wáyé láti ṣe dada ni.
Ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn gangan, Dókítà Firat Sari ló ń kojú ìgbẹ́jọ́ pé ó dá iléeṣẹ́ sílẹ̀ pẹ̀lú èròńgbà láti hu ìwà ọ̀daràn, lu iléeṣẹ́ ìjọba ní jìbìtì, ṣe ayédèrú ìwé ìjọba àti ṣíṣekúpani bípa kíkọ iṣẹ́ sílẹ̀.
Tó ba jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án, ó ṣeéṣe kó lọ sẹ́wọ̀n ọdún 583.
Níbi ìgbẹ́jọ́ náà, dókítà Sari tó ń ṣe àmójútó àwọn ẹ̀ka ìtọ́jú ọmọdé láwọn ilé ìwòsàn aládàni ọ̀hún jiyàn ẹ̀sùn pé àwọn kò ṣàmójútó àwọn ọmọ náà bí ó ṣe yẹ.
Ó sọ fáwọn olùpẹjọ́ pé gbogbo ìlànà tó tọ́ ni àwọn tẹ̀lé lórí ìtọ́jú àwọn ọmọdé náà.
Gbígba ìwé àṣẹ padà
Ṣùgbọ́n Doğukan Taşçı, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn nọ́ọ̀sì tí wọ́n mú sọ pé àwọn kùdìẹ̀kudiẹ kan máa ń wáyé lóòótọ́ pàápàá látara ògùn títà àti láti ṣèrú àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn aláàárẹ̀ lójúnà àti mú kí owó táwọn máa gbà látara ìjọba pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ.
Ó ní bí èrò bá ṣe pọ̀ ní ẹ̀ka náà sí ni owó táwọn máa gbà ṣe pọ̀ sí.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní oṣù Kẹta, ọdún 2023 ni èèyàn kan lọ fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ tó iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí rẹ̀.
Ilé ìwòsàn mẹ́wàá nínú mọ́kàndínlógun tí wọ́n fẹ̀sùn, tó fi mọ́ èyí tó jẹ́ ti mínísítà tẹ́lẹ̀ rí fétò ìlera lórílẹ̀ èdè náà ni ìjọba ti gba ìwé àṣẹ tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ wọn lẹ́yìn ìwádìí.
Àwọn ẹbí tó lé ní 350 ló ti ń bèèrè fún ìwádìí tó jinlẹ̀ lórí ikú àwọn ọmọ wọn.
Wọ́n ní kí mínísítà fétò ìlera kọ̀we fipò rẹ̀ sílẹ̀ àti pé kí ìjọba sọ gbogbo àwọn ilé ìwòsàn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn shún di ti ìjọba.
Ààrẹ Turkey, Recep Tayyip Erdogan sọ pé gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú ikú àwọn ọmọdé náà ló maa fojú winá òfin àmọ́ tóṣèkìlọ̀ pé kí wọ́n yé di gbogbo ẹ̀bi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ru iléeṣẹ́ èto ìlera nìkan.
'Gbígbé ayé ìnira'
Láti ìgbà tí ìròyìn ẹ̀sùn náà ti jáde ni àwọn ẹbí tí wọ́n pàdánù èèyàn wọn ti ń kojú ohun kan tàbí òmíràn.
Tolga sọ pé òu kò è ba ìyàwó òun sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí òun kọ́kọ́ gbọ́ nípa ẹ̀sùn náà.
“Nígbà ti mo rí orúkọ ilé ìwòsàn táwọn ọmọ wa pàdánù ẹ̀mí wọn sí lára àwọn ilé ìwòsàn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn, ara mi gbóná.
“Mo fẹ́ mọ̀ bóyá òótọ́ ni nǹkan tára ń rò fún mi nígbà náà, bóyá lóòótọ́ ni wọ́n pa àwọn ọmọ wa ni.”
Ọmọ ẹyọ̀kan tó kù nínú ìbẹta Tolga ti pé ọdún mẹ́jọ báyìí. Òun àtiìyàwó rẹ̀ kò ronú láti bímọ mìíràn.
“Ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbà náà kó ìnira bá wa, ọgbẹ́ tó dá sí ìyàwó mi lọ́kàn kò ì tíì jiná di àsìkò yìí. A ò fẹ́ kojú irú ìnira bẹ́ẹ̀ mọ́.
*Additional reporting by Emre Temel and Fundanur Ozturk.












