Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Netanyahu, Gallant àti Deif lẹ́yìn tí ICC ní kí wọ́n fòfin gbé wọn?

Netanyahu, Gallant [ati Deif

Oríṣun àwòrán, EPA/Reuters/Supplied

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Àwọn adájọ́ ní ilé ẹjọ́ ìwà ọ̀daràn àgbáyé, ìyẹn International Criminal Court (ICC) ti ní kí wọ́n fi òfin gbé olóòtú ìjọba orílẹ̀ èdè Israel, mínísítà tẹ́lẹ̀ rí fétò ààbò Israel, ọ̀gá iléeṣẹ́ ológun Israel àti olórí ikọ̀ Hamas.

Àtẹ̀jáde kan láti ilé ẹjọ́ náà ní àwọn ìpèníjà tí Israel fi ránṣẹ́ sí wọn, tí wọ́n sì ní kí wọ́n fi póró òfin gbé Benjamin Netanyahu àti Yoav Gallant.

Bákan náà ni wọ́n tún pàṣẹ pé kí wọ́n fòfin gbé Mohammed Deif tó jẹ́ olórí ikọ̀ Hamas bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Israel ní àdó olóró táwọn jù láti ojú òfurufú ti ṣekúpa Deif ní Gaza nínú oṣù Keje.

Àwọn adájọ́ náà ní àwọn ní ẹ̀rí láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn èèyàn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà lọ́wọ́ nínú ìwà ọ̀daràn tó ń lọ lórí ogún tó ń wáyé láàárín Israel àti Gaza.

Wọ́n ní wọ́n lọ́wọ́ lórí títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú mọ́lẹ̀ tó ń wáyé níbi ogun náà.

Israel àti Hamas ti jiyàn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n yìí.

Kí ni óò ṣẹlẹ̀ sí Netanyahu, Gallant àti Deif báyìí?

Ọwọ́ àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́rìnlélọ́gọ́fà tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ICC, yàtọ̀ sí Amẹ́ríkà àti Israel ló wà báyìí láti pinnu láti ṣe àmúṣẹ ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà.

Ní oṣù Karùn-ún, olùpẹjọ́, Karim Khan só pé kí ilé ẹjọ́ fòfin gbé Netanyahu, Gallant, Deif àtàwọn olórí ikọ̀ Hamas méjì mìíràn ti wọ́n ti jáde láyé, Ismail Haniyeh àti Yahya Sinwar.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Israel gbàgbọ́ pé Deif ti jáde láyé àmọ́ ilé ẹjọ́ náà ní àwọn kò lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó ti kú.

Lára àwọn ẹ̀sùn tí olùpejọ́ kà sí wọn lọ́rùn ni bí àwọn ọmọ ogun Hamas ṣe ṣèkọlù sí ẹkùn gúúsù Israel lọ́jọ́ Keje, oṣù Kẹwàá, ọdún 2023 tí wọ́n sì pa èèyàn tó tó ẹgbẹ̀fà.

Bákan náà ni wọ́n tún kó èèyàn 251, tí wọ́n sì fi wọ́n sí àhámọ́ ní Gaza.

Olùpejọ́ náà fi kun pé Israel náà ṣe ìkọlù padà sí Hamas àti pé èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógójì ni wọ́n ti pa ní Gaza gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ìlera tí Hamas ń darí ṣe sọ.

Khan fẹ̀sùn ka àwọn olórí ikọ̀ Hamas pé wọ́n tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú mọ́lẹ̀, pípa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn, ìfipábánilòpọ̀ àtàwọn ẹ̀sùn míì.

Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n fẹ̀sùn kan àwọn olórí Israel pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ìkọlù sáwọn aráàlú, lílo ebi gẹ́gẹ́ bí ohun ìjà ogun, ìpànìyàn àti pípa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn.

Àtẹ̀jáde kan tí iléeṣẹ́ ààrẹ Amẹ́ríkà fi léde ní àwọn ò faramọ́ ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà.

Ẹ̀wẹ̀, alákòso ètò ilẹ̀ òkèrè àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yúróòpù, EU sọ pé wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ̀lé àṣẹ ilé ẹjọ́ náà, kí wọ́n sì ṣe àmúṣẹ rẹ̀.

Iléeṣẹ́ olóòtú ìjọba Israel nígbà tí wọ́n fèsì sí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà sọ pé àwọn kò faramọ́ ẹ̀sùn irọ́ tí ICC kà sí àwọn lọ́rùn.

Iléeṣẹ́ náà ní Benjamin Netanyahu yóò tẹ̀síwájú láti ṣe àmúṣẹ gbogbo èrò wọn láti kojú ogun sí ikọ̀ Hamas àtàwọn agbéṣùmọ̀mí ní ilẹ̀ Iran.

Gallant, tí wọ́n yọ nípò mínísítà fétò ààbò Israel ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí kò ì tíì ṣo ohunkóun lórí ìdájọ́ náà.

Ikọ̀ Hamas ní tirẹ̀ ní àwọn faramọ́ ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà, tí wọ́n sì ń sọ fún àwọn orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé láti ṣe àmúṣẹ ìdájọ́ ọ̀hún kí wọ́n le dènà ìwà àìtọ́ tí Israel ń hù sáwọn ará ìlú ní Gaza.