Ọlọ́pàá Amẹrika yìnbọn pa ọkùnrin tó pe 911 fún ìrànlọ́wọ́

Police
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogoji kan, Brandon Durham, ti jade laye lẹyin ti ọlọpaa yinbọn lu u nile rẹ niluu Las vegas, nilẹ Amẹrika.

Iku ọkunrin ọhun waye lẹyin to pe ọlọpaa lori ipe 911 lasiko ti awọn ajeji kan fi agidi wọ inu ile rẹ.

Inu yara kekere kan ni mọlẹbi Durham, to fi mọ ọmọ rẹ obirin to jẹ ọmọ ọdun mẹẹdogun sapamọ si lasiko iṣẹlẹ naa.

Awọn ẹbi rẹ ọhun ti wa ke si ijọba Amẹrika ko gba iṣẹ lọwọ ọlọpaa to gbẹmi baba wọn.

Ọmọbinrin oloogbe naa sọ pe inu oun bajẹ gidi latari bi ọlọpaa naa ṣe mu baba oun bii ọdaran nigba to jẹ pe oun gan lo nilo iranlọwọ.

Amọ ṣa, agbẹjọro ọlọpaa ti wọn fẹsun ipaniyan naa kan ti sọ pe onibara oun ko wu iwa ọdaran kankan.

Ileeṣẹ ọlọpaa Las Vegas ninu atẹjade kan sọ pe oun ti ni ki ọlọpaa ti wọn fẹsuyn kan ọhun, Alexander Bookman, lọ rọọkun nile titi di igba ti awọn yoo fi iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Bawo ni ọrọ naa ṣe bẹrẹ?

Ṣaaju ni oloogbe, ọgbẹni Durham ti kọkọ pe ọlọpaa lori ipe 911 lati sọ fun wọn pe eeyan meji n yinbọn niwaju ile oun ti wọn si n gbiyanu lati fi agidi wọle.

Nigba ti awọn ọlọpaa de ibẹ, wọn ba ọkọ ayọkẹlẹ meji niwaju ile naa ti gilaasi rẹ ti fọ.

A gbọ pe awọn ọlọpaa naa n gbọ iro ibọn ninu ile ọhun, eyii to mu ki wọn fi ipa ja ilẹkun ile naa lati wọle.

Fidio ara aṣọ ọlọpaa ṣafihan bi ọlọpaa ti wọn fẹsun kan ṣe n wọ ile naa pẹlu ibọn rẹ lọwọ, to si n pariwo.

Lẹyin naa lo ri oloogbe ọhun to n ba obinrin kan jijakadi pẹlu ọbẹ lọwọ rẹ.

Eyii lo mu ko maa pariwo pe “Ju ọbẹ naa silẹ, ju ọbẹ ọwọ rẹ silẹ” ko to ṣina ibọn bolẹ.

Fidio naa ṣafihan bi ọlọpaa ọhun ṣe tun yin ibọn fun oloogbe naa ni igba marun un ọtọtọ to si ku loju ẹsẹ.