Afẹ́fẹ́ ìdọ̀tí, kùrukùru àti oòrùn yóò gba ojú ọjọ́ láti Ọjọ́rú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n ri si ọrọ oju ọjọ ni Naijiria, The Nigerian Meteorological Agency, NiMet, ti sọ pe afẹfẹ idọti, oorun to mu ganrin-ganrin ati ati kurukuru yoo gba oju ọjọ, bẹrẹ lati Ọjọruu, ogunjọ oṣu kọkanla ọdun 2024.
Ọjọ mẹta gedegbe ni eyi yoo fi ri bẹẹ, gẹgẹ bi Nimet ṣe wi. Iyẹn ni pe ọjọ Ẹti ni ayipada oju ọjọ naa yoo dopin.
Gẹgẹ bi Nimet ṣe wi, kaakiri Naijiria ni ayipada naa yoo ti waye.
Ninu atẹjade Nimet ti wọn fi sita lọjọ Iṣẹgun, wọn ṣalaye bi yoo ti ri ni awọn apa Oke Ọya bii Zamfara, Katsina, Kano, Sokoto, Kebbi, Jigawa ati Kaduna.
Wọn fi kun un pe àrá le maa san ni awọn ipinlẹ bii Delta, Bayelsa, Rivers, Cross River ati Akwa Ibom. Ojo si le rọ pẹlu.
Ni apa Guusu Naijiria, oju ọjọ ko ni i fi bẹẹ mọlẹ kedere lọwọ aarọ, bi Nimet ṣe ni yoo waye.
Ajọ Nimet rọ awọn araalu lati da aabo bo ara wọn ṣaaju ati lasiko ayipada oju ọjọ yii.
Wọn gba awọn ti wọn ba ni aisan ikọ seemi-seemi (Asthma) nimọran lati ṣora lasiko ayipada naa.
Bakan naa ni wọn gba awọn ileeṣẹ ọlọkọ ofurufu nimọran lati gba akọsilẹ to yẹ lori irinna lọwọ Nimet, ki wọn le mọ bi wọn yoo ṣe ṣeto irinajo gbogbo.














