Ipa tí ìpìnnu ìjọba lórí owó orí yóò ní lára mẹ̀kúnnù Naijiria rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn aba mẹrin kan to ni i ṣe pẹlu owo ori sisan, eyi ti Aarẹ Bola Tinubu gbe lọ sile igbimọ Aṣoju-ṣofin ṣi n mu awuyewuye dani lẹyin ọsẹ diẹ to ti gbe e siwaju wọn.
Ọrọ abadofin naa n fa ariyanjiyan laaarin awọn aṣofin, bẹẹ naa ni wọn si n gba a bii ẹni gba igba ọti kaakiri Naijiria.
Ohun ti kaluku n sọ ni pe ki ni idi ẹ ti Aarẹ yoo tun fi maa gbe awọn aba to le mu afikun ba owo ori sisan dide, nigba to jẹ inira ni yoo tun ko ba awọn eeyan Naijiria.
Bẹẹ lawọn kan n duro de alaye kikun lori ipinnu ijọba Tinubu yii.
Wọn ni awọn fẹẹ mọ ohun to tumọ si i gan-an kawọn too sọrọ nipa rẹ.
Ṣugbọn ohun to ṣe pataki loju awọn mẹkunnu Naijiria, ti wọn si n beere alaye si, ni pe bawo ni aba yii yoo ṣe nipa lori aye awọn?
Ṣe yoo mu aye le koko si i ni abi anfaani kan wa nibẹ tawọn o mọ.?
Ipa owó orí tó ń wọlé fún aráàlú
Lara ariyanjiyan to wa ninu aba yii ni ti owo ti wọn n yọ ninu owo to n wọle fun awọn eeyan lori iṣẹ ti wọn n ṣe, eyi ti a mọ si ‘Personal Income Tax.’
Aba tuntun yii ṣe alaye kan, pe oun yoo mu ajaga owo ori sisan kuro lọrun awọn ti owo ti wọn n pa wọle ko ba to nnkan.
Wọn ni awọn ti owo to n wọle fun wọn ko ba to ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin naira (800,000) lọdun, ko ni i sanwo ori lati inu owo wọn.
Nigba ti owo to n wọle fun wọn lọdun ba to miliọnu meji le ẹgbẹrun meji naira (2.2m) ni wọn yoo yoo san ida mẹẹẹdogun (15%) ninu ọgọrun-un (100%).
Ṣugbọn fun awọn ti wọn n na iru owo yii, ofin ti ṣe afikun owo ti wọn yoo san bii owo ori, gẹgẹ bi Dokita Zaid Abubakar, olori ẹka to n ri si pipa owo wọle nipinlẹ Kano ṣe ṣalaye.
" Ilana ti wọn n pe ni onitẹsiwaju ni owo ori yii ba de, eyi to tumọ si pe bi owo to n wọle fun ọ ba ṣe n pọ si i ni owo ori ti iwọ yoo san yoo maa pọ si i.
''Ṣugbọn awọn ti owo to n wọle fun wọn ko ba pọ yoo jẹ anfaani àbá yii gan-an''.
Dokita Zaid lo sọ bẹẹ.
Awọn kan ki i fẹẹ sọ iye ti wọn n pa, ki owo ori ti wọn yoo san le dinku .
"Ninu iru eto yii, ki i ṣe gbogbo eeyan lo le sọ ootọ nipa iye to n wọle fun wọn, wọn yoo maa din in ku ki wọn le sanwo ori kekere.
Afi tijọba ba wa ọna kan ti wọn le fi ja ọgbọn iru awọn eeyan bẹẹ, ọkan lara awọn ohun ti ofin yii wa fun niyẹn."
Bẹẹ ni Dokita Zaid ṣalaye.
Èlé orí ọjà (VAT)
Ijọba Aarẹ Tinubu ti sọ tẹlẹ pe oun ti gbọ aroye awọn ọmọ Naijria, paapaa awọn mẹkunnu ti ọrọ aje Naijria n ni lara gidi latari awọn atunto ti ijọba n ṣe.
Awọn nnkan jijẹ, ohun lilo bii ina ọba, itọju ailera, eto ẹkọ, sisan owo ile, lilo foonu ati bẹẹ bẹẹ lọ ti di iṣọro bayii nitori atunto ti iṣakoso Aarẹ Tinubu gunle.
Ṣugbọn awọn nnkan wọnyi ni aba ti Tinubu gbe kalẹ ti sọ pe afikun ko ni i ba owo ori rẹ.(VAT).
Ohun ti ofin yii sọ ni pe ele ori ọja yoo lekun lati ida meje aabọ ( 7.5%) si ida mẹẹẹdogun (15 %).
Ṣugbọn alekun le ba owo awọn nnkan wọnyi bii Dr Zaid ṣe ṣalaye, nigba ti awọn to wa nidii rẹ ba ti gbe owo le e.
"Ohunkohun ti wọn ba ti n sanwo ori lori le wọn si i lọja.
Bi wọn ba ṣafikun owo ina, o di dandan ki awọn ileeṣẹ to n ri si ina ọba fi owo kun un. Awọn ọmọ Naijiria naa ni yoo si fi ara gba ẹkunwo naa.''
Bayii ni Dokita Zaid Abubakar ṣalaye.
Owó orí onídàgbàsókè
Aba Aarẹ Tinubu yii ṣalaye pe adinku yoo de ba owo ti awọn ajọ ijọba kan ti wọn n gba owo idagbasoke.
Awọn ajọ bii bii TETFUND, NITDA, NASENI ati bẹẹ bẹẹ lọ ti wọn jẹ ti ijọba ni ọrọ naa kan bi wọn ṣe sọ
Wọn ni adinku naa yoo bẹrẹ lati 2025, yoo si pari si 2030, nigba ti ijọba ko ni i fun wọn ni awọn owo miran mọ.
Eyi le mu ifasẹyin ba iṣẹ awọn ajọ yii, pẹlu bo ṣe jẹ pe eto ẹkọ ni wọn n ri si.
Yoo si pada kan mẹkunnu to n tiraka lati ran ọmọ rẹ niwee, ati gbogbo Naijiria lapapọ.
Ọjọgbọn Ahmed Bello Dogarawa, lati ẹka iṣiro owo ni Yunifasiti Ahmadu Bello ni Zaria, ṣalaye bi wọn yoo ṣe pin owo naa.
"Bakan naa ni pinpin owo yii yoo ṣe lọ. Laaarin 2025 si 2027, bi owo ori ba wọle, ida aadọta (50%) yoo lọ si ọdọ TETFUND lọdọọdun.To ba di 2027, NITDA ati NASENI ko ni i gba owo kankan, wọn yoo ni lati wa owo ti wọn yoo fi maa ṣe ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe ni.
"Bẹrẹ lati 2030, TETFUND naa ko ni i ri owo kankan gba, awọn akẹkọọ nikan ni a o maa ṣeranlọwọ ẹyawo fun."
Ṣugbọn nibi ti nnkan de duro bayii, ko ti i si ipinnu kankan to waye latari awọn ayipada yii.
Bẹẹ ni aba ti ijọba fẹẹ sọ di ofin naa ṣi wa niwaju awọn igbimọ ati aṣoju.

























