Ìwà ọ̀daràn tó ń wáyé nípasẹ̀ kíkó pàǹtí lọ sílẹ̀ òkèrè

- Author, Navin Singh Khadka
- Role, BBC World Service environment correspondent
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Tí èèyàn bá ti yọ lókèrè ni yóò ti máa rí èéfí ńlá tó ń ru jáde láti ilé ilẹ̀ Agbogbloshie.
Afẹ́fẹ́ tó ń jáde láti ilé ilẹ̀ ọ̀hún tó wà ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Accra, orílẹ̀ èdè Ghana jẹ́ èyí tí kò dára rárá. Bí èèyàn bá ṣe ń súnmọ́ ibẹ̀ sí ni kò ṣe ní le mí dáadáa sí, tí èèyàn kò nsì ní ríràn dada.
Ní agbègbè yìí ni àwọn géńdé ọkùnrin tó máa ń já àwọn ilẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ láti dáná sún wọn tò sí. Àwọn kan nínú wọn gun orí ilẹ̀ tó ga láti kó àwọn àlòkù ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán, kọ̀mpútà àti ẹ̀yà ara ẹ̀rọ ìfọṣọ kalẹ̀.
Ohun táwọn ọkùnrin náà ń ṣe ni láti yọ kọ́pà àti wúrà lára àwọn ẹ̀rọ náà.
“Mi ò gbádùn rárá,” èyí ni ọ̀rọ̀ tó jáde lẹ́nu Abdulla Yakubu, òṣìsẹ́ kan tó ń dáná sun àwọn wáyà àti ike, pẹ̀lú bí ojú rẹ̀ ṣe pọ́n, tó sì ń yọ omi.
“Afẹ́fẹ́ tí à ń mí sínú níbi yìí kò da rárá, ojoojúmọ́ sì ni mo máa ń ṣiṣẹ́ níbí, dandan ni kó ṣàkóbá fún ìlera wa.”

Ọjà tí wọ́n máa ń fòfin dè jùlọ
Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ní ìdá mẹ́ẹ̀dógún péré nínú àwọn ìdọ̀tí tó wà káàkiri àgbáyé ni wọ́n ń ṣe àtúnlò rẹ̀ àti pé ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ ló máa ń wá ọ̀nà ẹ̀bùrú láti fi da àwọn ilẹ̀ wọn nù.
Ọ̀pọ̀ wọn ló máa ń wá àwọn alárinà láti bá wọn gbé àwọn ilẹ̀ yìí kúrò ní orílẹ̀ èdè wọn.
Àwọn ìdọ́tí yìí lo ṣòro láti tún ṣàmúlò wọn fi ṣe nǹkan mìíràn nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ́míkà tó wà nínú wọn tí kò ṣe é yọ kúrò lára wọn.
Kódà àwọn orílẹ̀ èdè tó ti gòkè àgbà kò ní ohun èlò láti fi tún ṣàmúlò àwọn ìdọ̀tí yìí.
Àwọn olùwádìí àjọ UN ní ó ṣeéṣe kí àlékún bá bí wọn yóò ṣe máa kó àwọn ìdọ̀tí yìí kúrò ní àwọn orílẹ̀ èdè tó ti gòkè àgbà lọ sí àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn àti pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìdọ̀tí tí wọ́n fòfin dè jùlọ lásìkò yìí.
Àwọn òṣìṣẹ́ ní ẹnubodè Naples ní orílẹ̀ èdè Italy fi bí àwọn tó ń kó ọjà wọlé ṣe parọ́ohun tí wọ́n kó, tó sì jẹ́ pé àwọn ohun èlò iná tí kò dára mọ́ ló jẹ́ ìdá ọgbọ̀n nínú ẹrù tí wọ́n kó.
Wọ́n ṣàfihà àwọn ẹrù kan tí wọ́n ń kó lọ sí ilẹ̀ Áfíríkà, bí ọkọ̀ kan ṣe kún fún àwọn àlòkù ẹ̀yà ara ọkọ̀ àtàwọn tí kò dára mọ́ nínú rẹ̀, tí ọ́ìlì sì ń jò dànù lára ọ̀pọ̀ wọn.

Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà kó wọn kúrò nílùú
Ní orílẹ̀ èdè UK, àwọn aláṣẹ ní àwọn ń rí àlékún lórí bí wọ́n ṣe ń kó ìdọ̀tí kúrò ní orílẹ̀ èdè.
Ní papakọ̀ ojú omi Felixstowe, Ben Ryder, agbẹnusọ fún àjọ tó ń rí sí ètò àyíká UK ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń pe àwọn nǹkan tó jẹ́ pàǹtí bíi ohun tó ṣì ṣe é lò àmọ́ tó jẹ́ pé wọ́n kàn tú wọn sílẹ̀ láti ṣe àwárí àwọn irin tó bá ṣe é lò nínú wọn, tí wn kàn sì máa lọ dáná sún wọn nígbà tí wọ́n bá dé orílẹ̀ èdè ti wọ́n ń kó wọn lọ bíi Ghana.
Ryder fi kun pé àwọn mìírà máa ń lọ̀ wọ́n, tí wọ́n yóò sì we mọ́ àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n ń kó jáde.
Ìjábọ̀ kan tí World Customs Organization gbé jáde ṣàfihàn rẹ̀ pé àwọn ọkọ̀ tí kò dára mọ́ tí wọ́n ‘[n kó lọ sí ilẹ̀ òkèrè ti lé ní ìdá ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin.
Àmọ́ àwọn onímọ̀ sọ pé iye tí wọ́n ṣàkọ́ọ́lẹ̀ rẹ̀ kéré jojọ sí nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ gangan.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ì tíì sí ìwádìí tó gbòòrò lórí àwọn ibi tí wọ́n ń kó àwọn ìdọ̀tí náà lọ, UN ní àwọn orílẹ̀ èdè tó w[níìl[oòrùn gúúsù Asia wà lára àwọn ibi tí wọ́n ń kó wọn lọ jùlọ.
Àwọn olùwádìí UN sọ pé àwọn tó ń ṣe fàyàwọ́ àwọn pàǹtí yìí ni wọ́n máa ń lo àwọn ọ̀nà tí ọwọ́ ìjọba kò fi ní tẹ̀ wọ́n.

Àwọn kẹ́míkà tó léwu
Àwọn ike àti irin tó wà nínú àwọn ohun èlò yìí kò dára fún ìlera ọmọnìyàn yálà nípa jíjó tàbí dída sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń mójútó ìlera àgbáyé, World Health Organisation, WHO ṣe sọ.
WHO ní àwọn èèyàn tí kò ní ìmọ̀ nípa ewu tí àwọn pàǹtí náà ń ṣe ló máa ń ṣe àmójútó rẹ̀ ní àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ń ko lọ láì lo àwọn ohun èlò láti fi dáàbò bo ara wọn.
Àjọ International Labour Organization àti WHO sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin àti ọmọdé ni wọ́n máa fara kásá àwọn kẹ́míkà tí kò dára yìí bíi lẹ́ẹ̀dì, tí èyí sì lè ṣàkóbá fún ìdàgbàsókè ọmọ.
Láti ọdún 2025, àpérò Basel Convention ní gbogbo àwọn tó ń ọjà lọ sí ilẹ̀ òkèrè gbọ́dọ̀ ṣàlàyé ohun tí wọ́n ń kó jáde.

Àmọ́ àwọn orílẹ̀ èdè kan bíi Amẹ́rikà kò ì tíì máa ṣàmúlò Basel Convention, táwọn kan sì gbàgbọ́ pé èyí le mú kí ìwà náà tẹ̀síwájú.
Ní ilé ilẹ̀ Agbogbloshie ní Ghana, ìwà yìí ń burú síi ní ojoojúmọ́.
Habiba sọ pé ọ̀pọ̀ owó tóun ń gbà lórí ilẹ̀ tí òun bá kó ni òun fi máa ń ra oògùn láti dá ààbò bo ara òun lọ́wọ́ àwọn ìjàmbá tó lè wáyé.
“Àmọ́ mo ṣì ń ṣe iṣẹ́ yìí nítorí kò sí ọ̀nà mìíràn fún mi àti ẹbí mi láti jẹun.”
Gbogbo ìgbìyànjú láti bá iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àyíká sọ̀rọ̀ ló já sí pàbó.