Ohun tí ojú wa rí rèé ní iléèwòsàn tí wọ́n ti ń ṣètò ayédèrú oyún àtí ìyanu ọmọ bíbí ní Nàìjíríà

Àkọlé fídíò, Ohun tí ojú wa rí rèé ní iléèwòsàn tí wọ́n ti ń ṣètò ayédèrú oyún
    • Author, Yemisi Adegoke, Chiagozie Nwonwu, and Lina Shaikhouni
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7
Aworan ọmọ ikoko lọwọ eeayn kan

Chioma gbagbọ pe Hope, ọmọ ọkunrin to gbe dani jẹ ọmọ rẹ.

Lẹyin ọdun mẹjọ ti ko ti ri ọmọ bi, o ni ọmọ naa jẹ ọmọ iyanu.

O sọ pẹlu igboya,”emi ni mo ni ọmọ mi”

O jokoo si ẹgbẹ ọkọ rẹ, Ike, ninu ọfisi osisẹ Naijiria kan, ẹni to n fi ọrọ wa tọkọtaya naa lẹnu wo.

Gẹgẹ bii Kọmisana fun ọrọ obinrin ati igbayegbadun nipinlẹ Anambra, Ify Obinabo ni ọpọ oriri nipa yiyanju ọrọ mọlẹbi- ṣugbọn ọrọ eyi kọja bẹ.

Eeyan marun un lati inu mọlẹbi Ike, to wa ninu ọfisi naa ko gbagbọ pe Hope jẹ ọmọ bibi inu tọkọtaya naa.

Chioma ni oun gbe ọmọ naa fun oṣu mẹdogun. Kọmisana ati mọlẹbi ọkọ ko gbagbọ.

Chioma ni oun ri ọpọ wahala lati ọdọ mọlẹbi ọkọ rẹ nitori ko loyun. Koda, wọn ni ki ọkọ rẹ fẹ iyawo miiran.

Ninu alaye rẹ, o lọ si ile iwosan kan to n wa ojutu si isoro oyun nini - ile iwosan n gba awọn obinrin kan ti wọn n wa ọmọ, ti wọn si n ta ọmọ fun wọn.

A yi orukọ Chioma, Ike ati awọn yooku pada ninu iroyin yii lati le da bobo wọn ni agbegbe wọn.

Aworan dokita Ify Obinabo to n gbọ alaye Chioma

‘Iwosan Iyanu’

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Orilẹede Naijiria jẹ ọkan ninu awọn orilẹede ti ọmọ bibi ti wọpọ lagbaye, ti ọpọ obinrin si n la ọpọ iṣoro kọja ti wọn ko ba ri ọmọ bi.

Nitori wahala yii, awọn obinrin kan n wa gbogbo ọna lati ri pe wọn di ọlọmọ laye.

O le ni ọdun kan ti BBC African Eye ti n ṣe iwadii lori awọn ile wosan to n pese oyun ni ọna arabamda.

Awọn onijibiti yii n ṣe bi dokitatabi nọọsi ti wọn si n sọ fun awọn obinrin pe awọn le jẹ ki wọn gba ọna iyanu loyun ti wọn fun ni itọju kan. Owo itọju ti wọn ba kọkọ bẹrẹ lo jẹ ọpọ dọla, ti wọn yoo si tun fun wọn ni abẹrẹ , ohun minu tabi ki wọn fi nnkan si oju ara wọn.

Gbogbo awọn obinrin ti a ba sọrọ ati awọn oṣisẹ ni wọn ko mọ nnkan to wa ninu awọn oogun. Ṣugbọn awọn obinrin naa sọ fun wa awọn iyatọ ti oogun mu ba ara wọn- bi ki ikun wọn tobi si- eyi ti yoo jẹ ki wọn gbagbọ pe wọn ti loyun.

Awọn obinrin to n gba itọju yii ni wọn kilọ fun pe ki wọn ma lọ si ọdọ dokita mii tabi ile iwosan miiran, nitori ayẹwo kankan ko ni ṣe afihan oyun – ti wọn si n sọ fun wọn pe ẹyin wọn ni oyun naa wa dipo ikun wọn;

To ba to asiko lati bimọ, wọn yoo sọ awọn obinrin na pe wọn yoo bẹrẹ si ni rọbi lẹyin ti wọn ba gba abẹrẹ kan, eyi ti wọn yoo tun san ọpọ owo fun.

Bi wọn se bimọ lo jẹ ohun iyalẹnu. Awọn obinrin ni wọn yoo sun abẹrẹ oorun ti wọn yoo si ji pẹlu ami pe wọn ti bimọ. Awọn mii, wọn yoo fun wọn abẹrẹ yoo fun wọn ni ero pe wọn ti bimọ.

Ni eyikeyi ọna, awọn obinrin yoo ni gbe ọmọ dani.

Chioma sọ fun kọmisana Ify pe nigba ti oun fẹ bimọ, dokita naa fun ni abẹrẹ ni bi ibara idi rẹ, to si ni ki o gbin. Ko sọ bi o ṣe pada ni Hope sugbọn o ni bi o ṣe bimọ naa lo nira pupọ.

Aworan "Dr Ruth" to ile iwosan onijibi ni Anambra

Ikọ BBC gbiyanju lati lọ si inu ọkan ninu awọn ile iwosan yii- ti wọn si ṣalabapade obinrin kan ti wọn mọ si “Dokita Ruth”- wọn se bi tọkọtaya to ti n wa oyun fun ọdun mẹjọ.

Dokita Ruth yii n si ile iwosan rẹ ni gbogbo Ṣatide kede loṣu ni ile itura kan ti wọn kọku niluu Ihiala nipinlẹ Anambra. Ni ita yara ile itura rẹ, ọpọ awọn obinrin lo to sita, ti wọn duro lati ri dokita naa, ọpọ lo ni ikun to tobi.

Agbegbe naa lo kun ero gidi. O to asiko kan, ayajọ nla jade lati inu yara nigba ti o sọ fun obinrin kan pe o ti loyun.

Nigba to to asiko fun akọroyin wa lati ri Dokita Ruth, o sọ fun wọn jẹbina ni itọju wọn.

O ni ki wọn gba abẹrẹ pr yoo fun wọn ni anfani lati mu iru ọmọ ti wọn fẹ boya ọkunrin tabi obinrin.

Ṣugbọn wọn ni rara si abẹrẹ , ti dokita Ruth si fun wọn ni oogun lilko pe ki wọn lo ti wọn ba de si ile pẹlu amọran lori bi wọn yoo se ni ibalopọ.

Owo akọkọ ti wọn na lo jẹ 350,000 naira($200).

Akọroyin wa ko lo oogun naa tabi tẹlẹ amọran Dr Ruth, to si pada lọ ri lẹyin ọsẹ mẹrin.

Lẹyin to lo ẹrọ kan fi yẹ ikun akọroyin wa wo, Dr Ruth ki ku orire pe o ti loyun.

Awọn mejeeji pari wo ayọ.

Lẹyin iroyin yii ayọ, Dokita Ruth ṣalaye bi wọn yoo se san owo fun awọn oogun lati le bimọ naa, eyi to jẹ milọnu meji naira ($1000).

Laisi lo awọn oogun yii, oyun naa le lo ju oṣu mẹsan an lọ pẹlu alaye ti ko ba imọ sayẹnsi lọ pe “Ọmọ yoo da bi ọmọ ti ko pe – a ni lati bẹrẹ pada .”

“Dr Ruth ko ti fesi si awọn ẹsun ti BBC ka si lẹsẹ.”

Aworan awọn obinrin to n derolati ri Dr Ruth

Bi awọn eeyan se gba awọn nnkan yii gbọ lo si jẹ nnkan okunkun.

Ṣugbọn a ri pe wọn wa ninu ajọ kan lori ayelujara nibi ti wọn ti n gbe iroyin ofege nipa oyun nini kiri.

Pinpin iroyin ofege

Oyun arabamda yii ni awọn onimọ ni o jẹ oyun ti obinrin ko ni mọ pe oun loyun fun igba pipẹ.

Ṣugbọn lasiko iwadii wa, BBC ri pe wọn n pin iroyin ẹlẹjẹ kaakiri Facebook nipa iru oyun naa.

Obinrin kan lati Amẹrika, ẹni to ni opo to n sọrọ nipa Oyun arabamda yii, sọ pe oun ti loyun fun ọpọ ọdun, ti imọ ṣayẹnsi ko si le ṣalaye irinajo rẹ.

Ni oju opo Facebook kan ti wọn ti pa, ọpọ ohun ti wọn gbe sita lo n lo ọrọ ẹsin lati fi kan sara si itọju oniyanu ree fun awọn eeyan ti ko ti ri ọmọ bi.

Gbogbo awọn iroyin ẹlẹjẹ yii ni ti awọn obinrin lati gba awọn nnkan wọnyi gbọ.

Ọpọ awọn eeyan to wa loju ọpọ yii ni ki se ọmọ Naijiria nikan ṣugbọn lati orilẹede South Africa, Caribbean ati paapa Amẹrika.

Awọn onijibiti yii ti lo wọn lati fi pawo.

Kete ti eeyan ba ti ni oun setan lati bẹrẹ itọju, wọn yo gbe wọn lọ si oju opo Whatsapp. Nibẹ olori yoo ma pin awọn iroyin nipa ile iwosan naa ati ọna lati bẹrẹ.

‘Ko ti ye mi’

Awọn alaṣẹ sọ fun wa pe lati pari itọju yii, awọn onijibiti nilo ọmọ tuntun, lati se eyi wọn ma wa awọn obinrin ti wọn fẹ gbe ọmọ silẹ, ọpọ wọn lo jẹ ọmọde, ti wọn ko si fẹ sẹ oyun nitori o lodi si ofin.

Ni oṣu keji ọdun 2024, Ẹka eo ilera nipinlẹ Anambra yawọ ile iwosan kan nibi Chioma ni oun bi Hope si.

BBC gba fọnran naa to ṣafihan bi wọn se yawọ ile meji kan.

Ni ọkan, awọn yara naa kun fun awọn irinsẹ eto ilera- fun awọn onibara- ti ikeji si kun fun awọn oloyun obinrin ki ti wọn mu silẹ. Ọpọ ninu wọn lo jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun.

Ọpọ wọn ni wọn ta lọ si ibẹ, laimọ pe wọn yoo gba ọmọ ti wọn ba bi ta fun awọn onijibiti .

Uju, ki se orukọ rẹ,ati awọn mii ni ẹru ba lati sọ fun awọn mọlẹbi wọn pe wọn loyun, ti wọn si wa ọna abayọ. O ni wọn fun oun 800,000 naira fun ọmọ rẹ.

Nigba ti a bi pe se o kabamọ igbesẹ rẹ lati ta ọmọ rẹ, o ni; “Ko ti ẹ ye mi”

Kọmisana Obinabo, ẹni to se akitiyan lati tọwọ iwa ibajẹ yii bomi ni, awọn onijibiti yii n wa awọn obinrin bi Uji lati ri ọmọ wọn ta.

Aworan ọmọ ikoko

Ni ipari ifọrọwerọ alagbara naa, Kọmisana Obinabo n oun yoo gba Hope kuro lọwọ Chioma.

Ṣugbọn Chioma bẹbẹ, ni oun ti lugbadi nnkan to sẹlẹ, ti oun ko si mọ ohun to lọ.

Kọmisana tẹwọ gba alaaye rẹ.

Bayii, Chioma ati Ike gba lati ma tọju ọmọ wọn – ayafi ti awọn obi to bi ba jade lati wa gba nnkan wọn pada.

Ti iwa si awọn obinrin nipa airi ọmọ bi ba tẹsiwaju, irufẹ jibiti bayii yoo tẹsiwaju, onimọ ṣalaye.