Àrùn 'listeria' bẹ́ sílẹ̀ l'Amẹrika, ọmọ tuntun jòjòló méjì kú, àwọn míì dèrò ilé ìwòsàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọ tuntu jojolo kan ti jade ni California, nilẹ Amẹrika latari arun ‘listeria’ to bẹ silẹ nibẹ.
Iroyin ni iya ọmọ naa tun dubulẹ aisan.
Bo tilẹ jẹ ibeji ọmọ tuntun jojolo ọhun tun jade laye, iwadii awọn dokita ko ri apẹrẹ arun listeria ni agọ ara rẹ.
Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun nilẹ Amẹrika, CDC, sọ pe eeyan mẹrin lo ti lugbadi arun naa nipinlẹ mọkanla laarin ọdun 2021 si ọdun 2024. A ko le sọ akoko pato ti ọmọ tuntun naa jade laye.
Ibujade arun ọhun ti mu ki ileeṣẹ to n pese ẹran, Yu Shang Food Inc. ko awọn ẹran to ninu ọja pada wọle.
Ileeṣẹ naa to wa ni South Carolina ti ko ẹran ti iwọn rẹ le ni ẹgbẹrun mejilelogun kilo kuro lọja lẹyin ti iwadii fi han pe arun naa wa lara awọn ẹran rẹ.
Ni California, eeyan meje lo dubulẹ aisan, meji ni Illinois, ati eeyan kọọkan ni New York ati New Jersy.
CDC sọ pe iye eeyan to n ṣaisan le pọ ju iye awọn ti awọn mọ lọ, aisan naa si le ti tan de awọn ipinlẹ mii nilẹ ọhun.
Arun wo ni listeria?
Arun listeria jẹ kokoro aifojuri to maa n ran ounjẹ eyii to ṣaba maa n ran awọn ọmọde, alaboyun atawọn eeyan ti eroja to n gbogu ti aisan ninu agọ ara wọn ko lagbara pupọ.
Lara awọn nnkan ti kokoro arun naa maa n gbogun ti ni awọn ẹya to ṣe pataki ninu agọ ara.
O si maa n fa ori fifọ, igbẹ gbuuru, iṣoro lati yin ọrun ẹni, iran baibai atawọn apẹrẹ mii.












