Ohun tó fàá tí aago orílẹ́èdè kan fi yàtọ̀ sí òmíràn lágbàáyé

Aworan aago

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lọdun 1883 ni ileeṣẹ reluwe ṣe ayipada akoko eyi to jẹ ki iyatọ wa ninu aago awọn orilẹede agbaye.

Ṣaaju akoko ti a n sọ yii, oorun l'awọn eeyan kaakiri agbaye maa fi mọ iye aago to lu.

Laarin ọdun 13th sẹnturi si 15th sẹnturi ni aago de.

Nibi ti oorun ba de láwọn ilu nla nla maa n yi aago sì, eyi lo jẹ ki aago awọn ilu yatọ sira wọn.

Eyi tẹsiwaju titi di ọdun 1800 nigba ti iyatọ lọna 144 wa ninu aago oniruuru ilu lapa Ariwa Amerika nikan.

Eyi ko fa wahala kankan tori ko sẹni to maa n gunle irinajo to jinna, ẹṣin ati rakumi l'awọn eeyan maa n gun lọ ibi ti wọn ba ti n lọ nigba naa.

Igba ti ọkọ oju irin de ni eyi jẹ ipenija.

Aarẹ ile iko nnkan iṣẹmbaye si lori ileeṣẹ reluwe, Jon Goldman, ni Baltimore, Maryland lorilẹede Amerika sọ pe ni nnkan bi ọdun 1800 ti reluwe ti gbe ọpọ eeyan lati Amẹrika lọ si Canada ni erongba lati ni aago tawon eeyan yoo maa lo fun irinajo bẹrẹ.

Aworan ile iko nnkan iṣẹmbaye si ni Baltimore Maryland

Oríṣun àwòrán, B&O Railroad Museum

O ni iyatọ to wa ninu aago awọn orilẹede jẹ ipenija nla fun ileeṣẹ ọkọ oju irin.

Ọgbẹni Goldman ni iṣoro akọkọ ni pe reluwe maa ja awọn ero silẹ ti wọn ko ni le ba a tori akoko.

O ni ekeji ni pe ọkọ oju irin meji le kọlu ara wọn ti wọn ba lọ loju irin kan naa tori akoko to yatọ lati ilu kan si omiran.

Orilẹede Britain to ṣe ọkọ oju irin lọna igbalode naa n koju iru ipenija yii lasiko naa.

Lọdun 1847 ni gbogbo ileeṣẹ ọkọ oju irin Ilẹ Gẹẹsi bẹrẹ si lo aago kan ṣoṣo.

Ọdun 1880 ni Ileeṣẹ Gẹẹsi bẹrẹ si ni lo aago GMT ti gbogbo eniyan mọ lonii.

Aworan aago

Oríṣun àwòrán, Alamy

Aago GMT yii ṣe iranwọ nla fun irinajo reluwe ni Ilẹ Gẹẹsi nigba naa.

Aago GMT yii mu adinku nla ba ijamba ọkọ oju irin, o si tun jẹ ko rọrùn fawọn ero lati de ibi ti wọn n lọ ni kiakia.

Ko pẹ ti imọ nipa aago yii fi tan kalẹ de apa ariwa Amẹrika.

Ni ọdun 1879, onimọ nipa oju irin, Sanford Fleming, ṣe agbekalẹ imọ kan lori ọrọ aago lẹyin ijamba ọkọ oju irin to ṣẹlẹ.

Lọjọ kejidinlogun oṣu Kokanla ọdun 1883 l'awọn ileeṣẹ reluwe ni Canada ati Amẹrika tẹwọ gba agbekalẹ Fleming lori aago.

Amọ, nitori pe apa ariwa Amẹrika tobi gan an, awọn ileeṣẹ pinnu lati ni aago mẹrin ọtọọtọ.

Ko si eyi to tii yipada lati igba naa di oni

Aworan reluwe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Goldman ni eyi mu adinku ba ijamba ọkọ oju irin lati igba ti aago ti wa.

Lẹyin ọdun si asiko yii ni Fleming ṣagbatẹru apero kan niluu Washington DC nibi ti wọn ti gba akoko GMT wọle gẹgẹ bi aago ti gbogbo agbaye yoo maa lo.

Bi Ilẹ Gẹẹsi ṣe n foju sọna si ọdun 2025 lati ṣe ayẹyẹ igba ọdun idasilẹ reluwe lọna igbalode, o ṣe pàtàkì lati mọ idi ti aago orilẹede kan fi n yatọ si omiran.