Ìdí tí aráàlú tí kò bá san owó orí rẹ̀ fi lè dèrò ẹ̀wọ̀n l'Oyo - Ìjọba

Aworan Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ipinlẹ Oyo ti kìlọ fawọn araalu at'awọn olokowo nipinlẹ naa wi pe ki wọn ma dagunla si owo ori sisan, bi bẹẹ kọọ, iru ẹni bẹẹ yoo foju wina ofin.

Ijọba ipinlẹ Oyo ni asiko ti to fun gbogbo awọn to n jẹ gbese owo ori lati san gbogbo owo ti wọn n jẹ ijọba.

Alaga igbimọ to n pawo wọle fun ijoba nipinlẹ Oyo, Olufemi Awakan, sọ pe dandan lowo ri gẹgẹ bi iwe ofin Naijiria apa kẹrinlelologun ṣe la a kalẹ.

Awakan ni gbogbo araalu ti wọn ba ti n ṣowo jere, tabi ti wọn ba n ṣiṣẹ kan tabi omiran yala iṣẹ ijọba tabi iṣẹ aladaani gbọdọ maa san owo ori.

Ọgbẹni Awakan ni owo ori kii ṣe ijiya lati ọwọ ijoba bi ko ṣe ojúṣe araalu si ijọba.

O ni alakalẹ ofin wa to fontẹ lu owo ori sisan, irufẹ ofin yii si ni ofin FIRA ati PITA ti ọdun 2011 to jẹ ti ijọba apapọ ti atunṣe si tun ti ba at'awọn ofin mii tawọn ipinlẹ naa ṣe.

Ijiya to wa fawọn ti ko ba sanwo ori

Nigba to n sọrọ nipa awọn ijiya to wa fawọn to ba kọ lati sanwo ori, alaga igbimọ to n pawo wọle fun ijoba nipinlẹ Oyo sọ pe iwa ọdaran lẹni ti ko san owo ori n hu labẹ ofin.

O ni ẹnikẹni to ba jẹbi ẹsun aisan owo ori le dero ẹwọn tabi ko san faini, o si le ṣe mejeeji naa.

Ọgbẹni Awakan ni ẹka ijọba to n ri si ọrọ owo ori lo le sọ bo ya araalu tabi olokowo kan n jẹ ijọba ni owo ori.

Bakan naa ni Ọgbẹni Awakan sọ pe ijọba le gbẹsẹ le dukia tabi apo ikowosi banki ẹni ti ko ba sanwo ori.

O fikun ọrọ rẹ pe olokowo ti o ba kọ lati sanwo ori rẹ yoo ni inira lati ṣe isọdọtun iwe okowo rẹ.

Ọgbẹni Awakan ni ijọba le gbe ẹnikẹni to ba kọ lati sanwo ori rẹ lọ ile ẹjọ.