'Ẹ̀ẹ̀mejì ni wọ́n jí mi gbé fi ṣe iṣẹ́ àṣẹ́wó, ọkùnrin mẹ́wàá ló sì ń bá mi sùn ní alẹ́ sí òwúrọ̀'

Aworan ọmọbinrin naa, Isata
Àkọlé àwòrán, Isata
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Ọdọmọbinrin to ṣẹṣẹ le diẹ logun ọdun ni Isata, o ti bimọ obinrin kan ati ọkunrin kan.

Igbesi aye Isata ṣafihan ijiya nla to koju rẹ pẹlu ọpọlọpọ obinrin nipasẹ iṣẹ aṣẹwo ti wọn sẹ lorilẹde Sierra Leone.

Wọn ji Isata gbe lọ si Gambia, Senegal ati Mali lati lọọ ṣe iṣẹ aṣẹwo.

Wọn fi lilu ṣe tiẹ, wọn ja a lole, ko too pada ri itusilẹ gba lati ṣalaye ohun toju rẹ ri.

Ohun to mu ọrọ Isata buru ju ni ti oogun oloro kan ti wọn n pe ni ‘Kush’, eyi ti ko le ma mu.

Kush yii la gbọ pe o n ba aye awọn eeyan to n mu un jẹ ni apa Iwọ Oorun Afrika.

Ọdun mẹrin gbako ni ẹka iroyin BBC Africa Eye lo lati ṣe iwadii awọn ikọ aṣẹwo kan to wa ni Makeni, eyi ti ko ju kilomita igba lọ si olu ilu Sieraa Leone, Freetown.

Okuta olowo iyebiye, Diamond lo pọ ni Makeni yii, ṣugbọn awọn oninabi ibẹ, eyi ti Isata jẹ ọkan lara wọn, ko fi ti nnkan alumọọni naa ṣe.

Isata, gẹgẹ bi awọn oninabi yooku ti BBC ba sọrọ, ko sọ orukọ baba wọn, orukọ abisọ ara wọn nikan ni wọn da fun awọn akọroyin wa.

Isata sọ pe gbogbo iya ti oun n jẹ yii, nitori ọmọ oun ni.

'Mo ti jẹ iya to pọ lori irin, nigboro.

'Mo pade ọkunrin kan ni ile ijo, o fa aṣọ mi ya, mo gbiyanju lati gba ara mi silẹ lọwọ rẹ, o fi idi ibọn to mu dani gba mi lori, o fẹẹ pa mi patapata ni.

'Igbesi aye to buru la n gbe, awọn mii wa ninu awọn obinrin yii ti wọn ti ko arun Ko-gboogun (HIV).

Wọn ti pa awọn miran, ṣugbọn ọpọ lo gba pe ko sohun tawọn le ṣe si i.'

Bayii ni Isata wi.

Ìbálòpọ̀ kan, Dọ́là kan

Nibi kan to ṣokunkun birimu, ti wọn tẹ awọn apo si, ni awọn ọmọbinrin aṣẹwo meji naka si fun ikọ iroyin BBC Africa Eye, wọn ni ni ibi ti awọn ti n ṣiṣẹ awọn niyẹn.

Ọkan ninu awọn oloṣo naa torukọ rẹ n jẹ Mabinty, sọ pe awọn n ba ọkunrin mẹwaa lo pọ lori apo naa laṣalẹ kan ṣoṣo, o kere tan.

Dọla kan lo ni wọn maa n san fawọn fun ibalopọ kan.

Mabinty n gbiyanju lati kowo jọ fun awọn ọmọ rẹ gẹgẹ bo ṣe ṣalaye. Ọmọ mẹfa lo ni oun bi, ṣugbọn mẹta ti ku ninu wọn, awọn mẹta yooku wa nile ẹkọ.

'Ọmọ mi kan ṣẹṣẹ pari idanwo rẹ ni, mi o lowo to maa fi lọ sileewe si i, afi ti mo ba ṣiṣẹ aṣẹwo. Awọn nnkan to n fiya jẹ mi ree.'

Ẹgbẹ̀rún obìnrin ni àkọsílẹ̀ wà pé wọ́n ti di aṣẹ́wó báyìí káàkiri Sierra Leone

Isata pẹlu ọmọ rẹ obinrin
Àkọlé àwòrán, Isata pẹlu ọmọ rẹ obinrin
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Pupọ ninu awọn obinrin to di aṣẹwo yii lo ṣi kere lọjọ ori, ogun to ja orilẹede naa lo sọ wọn di alailobi mọ.

Eyi lo fa a ti ọpọlọpọ wọn fi di alai-ni-olubawi kankan ati oninabi.

O le ni aadọta ẹgbẹrun eeyan to ba ogun naa lọ pẹlu, awọn eeyan ti ko nile lori mọ si fẹrẹ to idaji orilẹede naa nigba ti ogun yii yoo fi dopin ni 2022.

Awọn ajọ alaanu fidi ẹ mulẹ, pe awọn ọdọbinrin to n ṣiṣẹ aṣẹwo ni Sierra Leone tun ti pọ si i, bi ilu naa ṣe n ba oṣi to n ta wọn latari Ebola ati Korona to ja nibẹ wọya ija.

Gẹgẹ bo ṣe maa n ri bi iru nnkan bayii ba ṣẹlẹ, awọn obinrin orilẹede naa lo faragba ikọlu yii ju.

Ohun kan ni pe ofin orilẹede Sierra Leone fi aaye gba iṣẹ aṣẹwo ṣiṣẹ, ki i ṣe iwa ọdaran lati jẹ oloṣo.

Ṣugbọn oju abuku ni wọn maa n fi wo obinrin to ba n ṣe e, wọn ko si ki n ri iranlọwọ gidi gba lọdọ ijọba ati awọn araalu.

Ko pẹ pupọ ti a ba Isata sọrọ ni 2020 ni ikọ ọdaran kan ji i gbe, wọn fi agidi gbe e lọ si Gambia, nibi ti wọn ti n fi i ṣe iṣẹ aṣẹwo.

Lẹyin Gambia ni wọn gbe e lọ si Sengal, orilẹede Mali lo si pada balẹ si, nibi to ti ri anfaani lati ri ẹrọ ibaraẹnisọrọ kan, to si ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun BBC lẹẹkan si i.

“ Ṣe ẹ ri ọna ti wọn gba mu wa, afi bii pe wọn fẹẹ pa wa ni ti a ba fi le kọ lati tẹle wọn.Iya n jẹ mi pupọ.”

Ọrọ Isata yii ni BBC Africa Eye fi wa a de ọdọ ajọ International Organisation for Migration (IOM), awọn ni wọn ran an lọwọ to fi pada si Sierra Leone.

Ọmọ elépo tún ìgò rẹ̀ fọ̀, Isata padà sí iṣẹ́ olóṣó

Loootọ ni Isata fi iṣẹ oloṣo silẹ nigba yẹn, o si lọọ n ba wọn ṣe ọmọ ọdọ ọlọka nile ounjẹ kan lati tọju ọmọ rẹ.

Ṣugbọn nigba ti a tun maa gbọ nipa rẹ ni 2023, Isata ti pada sidi iṣẹ nabi rẹ, lẹyin ti ohun oloro ti wọn n pe ni Kush ti di ko ṣee ma mu fun un.

Ohun mimu amara-gba-yagiyagi ni Kush, egungun eeyan wa ninu ohun ti a gbọ pe wọn fi n ṣe e, owo rẹ si gba ọpọ pupọ, ko wọn lati ra fun awọn to n mu un.

Iṣoro nla ni Kush yii ti da fun wọn ni Sierra Leone, to bẹẹ ti aarẹ orilẹede naa ti kede ẹ bii nnkan aburu to gba abojuto ni pajawiri (National Emergency).

Nibi ti Kush ti di baraku fun Isata de, o fi ọmọ rẹ ọkunrin to ṣẹṣẹ bi silẹ, ọmọ oṣu mẹrin, o si n ba aye rẹ lọ lẹka oloṣo ṣiṣe.

Iya Isata, Poseh, lo n tọju ọmọdekurin naa.

‘Mo fẹ́ kí àwọn ọmọ mi ṣe oríire láyé ni mo ṣe ń ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó’

Nata lo n kun oju rẹ yii, o n mura ibi iṣẹ oloṣo
Àkọlé àwòrán, Nata lo n kun oju rẹ yii, o n mura ibi iṣẹ oloṣo

Ọmọbinrin mii ti BBC Africa Eye tun ba sọrọ ni Nata, oun naa le logun ọdun, o si ti bimọ obinrin mẹta.

Nile rẹ ti BBC ti ba a, o n kun oju rẹ lọwọ ni, o si n mura lati lọọ ṣiṣẹ aṣẹwo rẹ.

Nata sọ pe, oun fẹ ki awọn ọmọ oun ṣe oriire laye ni oun ṣe n ṣiṣẹ aṣewo.

'Mo si lero pe Oluwa yoo gbọ adura mi.'

Ọkan ninu awọn ọmọ rẹ n wo o bo ṣe n kun oju lati lọọ ṣiṣẹ nabi, ọmọ naa sọ fun BBC pe oun ko fẹẹ ṣe oloṣo ni t'oun.

O ni iṣẹ agbẹjọro lo wu oun lati ṣe ti oun ba dagba, ki oun le maa ran iya oun lọwọ.

Lẹyin eyi ti BBC tun ri Nata, wọn ko da a mọ mọ.

Ohun mimu Kush ti ba aye tiẹ naa jẹ, awọn ọmọ rẹ si ti lọọ n gbe lọdọ awọn ẹbi kiri.

‘Ibi iṣẹ́ aṣéwó ni wọ́n pa ìyá mi sí, kò ju ẹni ọdún mọ́kàndínlógún lọ’

Rugiatu, ọmọ ti wọn pa iya rẹ nibi iṣẹ oloṣo
Àkọlé àwòrán, Rugiatu, ọmọ ti wọn pa iya rẹ nibi iṣẹ oloṣo

Ninu irinkerindo BBC Africa Eye ni wọn ti ba ọmọ ọdun mẹwaa kan pade, obinrin ni, Rugiatu lorukọ rẹ.

Gina ni orukọ Iya Rugiatu, iṣẹ aṣẹwo l'oun naa n ṣe nigba to wa laye gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Nibi iṣẹ aṣẹwo naa ni wọn pa a si lọdun 2020, nigba ti ko ju ẹni ọdun mọkandinlogun (19) lọ.

Baba to bi Rugiatu fun naa ti ku, ọmọdebinrin naa si ti di ọmọ orukan.

'Iya ati baba mi ti ku bayii, ọdọ iya mi agba ni mo n gbe.

Bi iya agba naa ba fi le ku bayii, ko sohun ti mo le maa ṣe ju ki n maa tọrọ owo lojuu popo lọ.

Emi o fẹ ki wọn pa mi si titi bi wọn ṣe pa iya mi.'

Bẹẹ ni ọmọkekere to n jẹ Rugiatu naa ṣalaye.

Ìgbẹ̀yìn Isata

Ni ti Isata, bo tilẹ jẹ pe o ti pada sile bayii, wọn ti kọkọ ji i gbe ni ibẹrẹ ọdun 2024 yii.

Ọkunrin kan lo ni ko waa lọọ ṣiṣẹ ọmọ ọdọ ni Ghana, ṣugbọn obinrin Naijiria kan to n jẹ Joy lo pada fa Isata le lọwọ.

Iyẹn gbe e lọ si Mali, nibi to ti bẹrẹ nabi pada lagbegbe kan ti wọn ti n wakusa.

Bi yoo ba fi iṣẹ naa silẹ, wọn ni ko lọọ mu $1,700 (£1,300).

Bi Isata yoo ba ri iru owo bẹẹ, ibalopọ ọgọrun-un kan ko ka a.

Ṣugbọn pẹlu iranlọwọ ajọ IOM, to n ri si bi wọn ṣe n da awọn ọmọ Sierra Leone to n ṣe aṣẹwo pada siluu wọn, Isata naa ti pada si Makeni bayii, o si ti n gbe pẹlu iya ati awọn ọmọ rẹ meji.