
Oríṣun àwòrán, @officialbisolabadmus/Instagram
Ní ọjọ́ méjì sẹ́yìn ni fídíò kan nípa òṣèrébìnrin, Bisola Badmus gba orí ayélujára.
Nínú fídíò náà ni òṣèrébìnrin náà ti sọ pé ara òun kò yá láti bíi ọdún méjì sẹ́yìn, tí nǹkan kò sì lọ dédé fún òun mọ́.
Fídíò náà ni Bisola gbé sórí ìkànnì ayélujára Instagram rẹ̀ lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí.
Nínú fídíò náà ni òṣèrékùnrin, Oriyomi Olaniyi, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ọmọga ti ń tọrọ owó lọ́wọ́ Bisola Badmus pé òun fẹ́ ya fíìmù kan àmọ́ òun ṣì nílò owó tó tó mílíọ̀nù méje náírà láti ya fíìmù náà.
Ó ní nǹkan tó gbé òun dé ọ̀dọ̀ Bisola ni pé òun fẹ́ kí ó ran òun lọ́wọ́ láti fún òun nínú owó náà kí òun ba à lè ri fíìmù náà yà.
Àmọ́ nígbà tí Bisola máa fun lésì, ó ní ó ti lé ní ọdún méjì sẹ́yìn tí òun ti ń bá àìsàn kan fínra, tí òun kò s ríbi ṣe iṣẹ́ kankan láti ìgbà náà.
Ó ní òun kò ní ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún náírà láti fi ran Oriyomi lọ́wọ́ àmọ́ tí òun bá tún rí si nígbà tó bá ti ń bá fíìmù náà lọ òun tún máa ṣe ìrànlọ́wa fún-un.
Ó sọ pé láti bíi ọdún méjì sẹ́yìn ni ara òun kò ti yá gidi ṣùgbọ́n òun dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé ẹ̀mí òun ṣì wà.
Ó sọ nínú fídíò náà pé àìsàn tó ń ṣe òun kò jẹ́ kí òun dá èèyàn mọ̀ kódà tó fi dé orí ọmọ òun.
Ní ọjọ́ ìbí rẹ̀ lọ́dún 2023 ni Bisola Badmus, nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí ayélujára Instagram rẹ̀ ló ti kọ́kọ́ kéde pé òun ní àìsàn kan tó ń jẹ́ Encephalopathy.
Ó ní àìsàn náà lágbára débi pé òun kò lè gbèrò rẹ̀ fún ọ̀tá òun níbi tó lágbára dé.
Ó sọ pé nítorí náà ni òun ṣe kúrò lórí ayélujára fún ìgbà kan ná láti lè mójútó ara òun.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Pẹ̀lú omije lójú ni Oriyomi, Bisola Badmus àti òṣèré mìíràn, Olamilekan Ayinla tí òun náà wà nínú fídíò náà fi ń sọ̀rọ̀ lórí àárẹ̀ náà.
Oriyomi ní ó ya òun lẹ́nu pé nígbà tí òun dé ìta ilé Bisola tí òun kò bá ọkọ̀ rẹ̀ níbẹ̀ tí òun sì rò pé bóyá ó ti jáde ni.
Bisola ní ọkọ̀ méjì ni òun ní kí àárẹ̀ tó ṣe tó bẹ̀rẹ̀ àmọ́ òun ti tà wọ́n láti fi tọ́jú ara òun.
“Mọ́tò méjì ni mo ní, mọ́tò méjì ni mò ń lò, mo ti tà á, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, a ṣá ń dúpẹ́ ẹ̀mí.”
Nínú rẹ̀ ọ̀rọ̀, Olamilekan Ayinla ní kìí ṣe pé Oriyomi fẹ́ bèèrè owó lọ́wọ́ Bisola Badmus tẹ́lẹ̀ bíkòṣe láti ṣe àwọn ẹ̀tàn tí wọ́n máa ń ṣe fáwọn èèyàn lórí ayélujára àmọ́ òun ni òun sọ fún pé ara rẹ̀ kò yá.
Ó ní òun mọ̀ pé èèyàn tó máa ń tiraka láti ṣe fún àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ni Bisola ni òun fi sọ fún pé kó nìṣó, pé òun mọ̀ pé gbogbo nǹkan tó bá wà lọ́wọ́ rẹ̀ ni yóò gbìyànjú láti fi ràn-án lọ́wọ́.
Ayinla ní pẹ̀lú bí Bisola ṣe ní ìpèníjà pẹ̀lú ìlera rẹ̀ lásìkò tí òun ní ìjàmbá ọkọ̀, ó ní Bisola tún fi owó ránṣẹ́ sí òun láì wò wí pé òun náà ní tí tòun lára.
Ó ní láti inú oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2021 ni Bisola ti ń ṣe àìsàn, tí àwọn sì ti ń da ọwọ́ bò ó nítorí àwọn kò fẹ́ pariwo rẹ̀ fún aráyé.
Ó ṣàlàyé pé ìdí nìyẹn tí àwọn kò fi gbé sórí ayélujára nípa nǹkan tó ń ṣe Bisola.
Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn òṣèré tíátà bíi Madam Saje, Biola Adebayo, Sotayo àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni wan ti ṣe ìrànwọ́ gẹ́gẹ́ bí agbára wọn ṣe mọ́ láti ìgbà tí ara rẹ̀ kò ti yá.
Ó fi kun pé òun ní ìgbàgbọ́ pé ọlọ́run yóò jofgún àláfíà tó pé fún-un láìpẹ́ ọjọ́ àti pé yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe iṣẹ́ padà láti lè máa rí ọwọ́ mú sẹ́nu.
Ta ni Bisola Badmus?

Oríṣun àwòrán, @officialbisolabadmus/Instagram
Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà ni Bisola Badmus jẹ́.
Ní ọjọ́ kẹrin, oṣù Kejìlá, ọdún1983 ni wọ́n bí, tó sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ijebu-Ode ní ìpínlẹ̀ Ogun.
Ijebu-Ode ló ti kẹ́kọ̀ọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama kó tó tẹ̀síwájú ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìlú Ibadan níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ eré orí ìtàgé, “Theatre Arts”.
Lẹ́yìn náà ló tún kẹ́kọ̀ọ́ gboyè onípò kejì ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Lagos State University nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ètò ọrọ̀ ajé, “Economics”.
Ní ọdún 2000 ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àmọ́ ọdún 2008 ló di ìlú mọ̀ọ́ká pẹ̀lú ipa tó kó nínú eré Jenifa àti Omo Ghetto.
Lára àwọn fíìmù tó tún ti kópa ni The Figurine, I am Bisola, Tears of the sun, The Ghost and the tout àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.















