N1,300, N690! Èló gan-an ni Dangote ta lítà epo bẹtirò fún NNPCL?

Aworan awon oko to n gbe epo

Oríṣun àwòrán, NNPCL/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọjọ Aiku, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹsan-an, ni ajọ NNPCL bẹrẹ si ni gbe epo bẹtiro nileeṣẹ Dangote.

Ninu ọrọ kan to sọ, agbẹnusọ NNPCL, Ọgbẹni Olufemi Soneye, sọ pe 16.8m lita bẹtiro ni awọn ọkọ epo àjọ naa gbe.

O fi kun ọrọ rẹ pe nigba ti yoo fi di aago mẹrin irọlẹ ọjọ Aiku, aadọrin ọkọ lo ti gbe epo bẹtiro jade.

Ibeere to wa lẹ́nu ọpọ ọmọ Naijiria ni pe, elo gan-an ni Dangote ta epo bẹtiro fun NNPCL.

Eyi ko ṣẹyin bo ṣe jẹ pe iye ti NNPCL ra epo lọwọ rẹ ni yoo ṣe atọna iye ti araalu yoo tun maa ra lita epo kan.

Ṣaaju ni iroyin kan jade ni irọlẹ ọjọ Aiku pe, Naira mejidinlẹẹdẹgbẹrun, N898, ni ileeṣẹ Dangote ta lita bẹtiro kan fun NNPCL.

Agbẹnusọ fún NNPCL, Olufemi Soneye sọ pe irọ patapata ni pe N1,300 tabi N760 ni awọn ra lita kan.

'Mo le fidirẹ mulẹ fun yin pe, N898 la ra epo lonii.'

Ṣugbọn nigba ti yoo fi di alẹ ọjọ Aiku bakan naa, agbẹnusọ ileeṣẹ Dangote sọ pe irọ ni iroyin naa.

'Ọrọ to le ṣi eeyan lọna ni NNPCL sọ'

Ninu atẹjade to fi sita, agbẹnusọ fun ileeṣẹ naa, Anthony Chiejina, sọ pe ọrọ ti NNPCL sọ, jẹ eyi to le ṣini lọna, to si tun jẹ erongba lati yẹpẹrẹ aṣeyọri nla to waye lọjọ Aiku.

"Ọrọ naa jẹ erongba lati yẹpẹrẹ aṣeyọri ti a ṣe akọsilẹ rẹ lonii, eyi to jẹ ojutuu si iṣoro aito epo to ti n ba ọrọ aje finra fun bi aadọta ọdun.

Chiejina ni awọn rọ awọn ọmọ Naijiria lati duro de ìkéde iye ti awọn n ta epo, ti yoo waye lati ọdọ àjọ ti Aarẹ Tinubu yan lori tita eporọbi fun awọn ileeṣẹ ifọpo abẹle ni Naira dipo Dollar.

Bakan naa lo tun ṣalaye pe Dollar ni NNPCL fira epo bẹtiro naa, nitori pe Dollar ni awọn naa ra epo ti awọn n ta lọwọlọwọ.

Owo pupọ si ni NNPCL ri fi pamọ, eyi to ju iye ti wọn n ri tẹlẹ lọ, nitori igbesẹ yii.

'Pẹlu igbesẹ wa, gbogbo ijọba ibilẹ to wa ni Naijiria, ni epo bẹtiro yoo wa fun tita.'

Lọwọlọwọ, niṣe ni awọn ọkọ n to rẹpẹtẹ si awọn ile-epo.

Eyi ko ṣẹyin ọwọn gogo, ti ọpọ wọn si n ta lita kan ni bi ẹgbẹrun kan Naira.