NNPCL bẹ̀rẹ̀ gbígbé epo láti iléeṣẹ́ Dangote - Wo àǹfàní tó wà fọ́mọ Naijiria

Oríṣun àwòrán, @NNPCL/X
Àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ epo bẹntiróòlù ní Nàìjíríà ìyẹn Nigerian National Company Limited, NNPCL ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹsàn-án ni àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé epo láti ilé iṣẹ́ ìfọpo Dangote Petroleum Refinery.
Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ iléeṣẹ́ ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ títa epo rọ̀bì àti epo bẹntiróòlù, Zacch Adedeji ní ọjọ́ Kìíní, oṣù Kẹwàá ni àwọn yóò fún iléeṣẹ́ Dangote ní epo rọ̀bì mìíràn àti pé owó náírà ni àwọn yóò fi tà á fún-un.
Adedeji tó tún jẹ́ alága àjọ tó ń rí sí pípa owó wọlẹ́ lábẹ́nú ní Nàìjíríà, ìyẹn Federal Inland Revenue Service tún ṣàlàyé pé Dangote yóò máa ta epo bẹntiróòlù àti dísù padà fún ìjọba ní owó náírà bákan náà.
Ó ní inú òun dùn láti kéde pé àwọn ti parí gbogbo àdéhùn láti àjọsọ àwọn iléeṣẹ́ méjéèjì àti pé gbígbé epo bẹntiróòlù yóò bẹ̀ẹ̀ lọ́jọ́ Àìkú.
Àwọn nǹkan míì tí wọ́n tún fẹnukò lé lórí ni pé àwọn ilé epo tó bá fẹ́ máa rà dísù lọ́wọ́ Dangote yóò máa fi owó náírà rà á.
Bákan náà ni wọ́n ní NNPCL nìkan ni yóò máa ra epo bẹntiróòlù lọ́wọ́ Dangote.
Nínú àtẹ̀jáde tí iléeṣẹ́ NNPCL fi sórí ayélujára X lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ní àwọn ọkọ̀ agbépo àwọn tó lé ní ọgọ́rùn-ún ló ti wà ní ilé ìfọpo Dangote, táwọn mìíràn sì tún wà lọ́nà láti lọ gbé epo bẹntiróòlù.
Láti ìgbà tí ilé iṣẹ́ Dangote ti ń fọ epo ni àwọn èèyàn Nàìjíríà ti ń bèèrè pé àǹfàní wo ni èyí yóò jẹ́ fún àwọn?
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ṣé èyí yóò mú àdínkù bá owó epo àbí epo kàn máa wà lásán?
Onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé kan, tó tún jẹ́ èèkàn lórí ọ̀rọ̀ ohun àmúṣagbára, Dókítà Okey Okere sọ fún BBC News Pidgin pé nǹkan tó jẹ́ ìpèníjà ní pé ilé iṣẹ́ NNPCL nìkan ló ní àǹfàní láti ra epo lọ́wọ́ Dangote, tí yóò máa wá tà á fún àwọn ilé epo tó kù.
Okere ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní NNPCL kìí ṣe iléeṣẹ́ ìjọba mọ́, ó wòye pé ọwọ́ ìjọba kò tán lára rẹ̀ àti pé wọn kò ní ṣiṣẹ́ wọn dójú àmì bó ṣe yẹ .
Ó ní àǹfàní tó wà nínú bí Dangote ṣe ń fọ epo ní Nàìjíríà báyìí kò ní ju pé epo máa wà lọ́pọ̀ yanturu, kò ní máa sí ọ̀dá epo bíi ti ìgbà kan àmọ́ ó ṣeéṣe kí owó rẹ̀ má walẹ̀ jú báyìí lọ.
Ó fi kun pé ọ̀nà Nàìjiríà tí kò dára náà jẹ́ ohun kan tí yóò jẹ́ ìpèníjà nítorí àwọn ilé epo yóò nílò láti dé ìpínlẹ̀ Eko kí wọ́n tó le gbé epo lọ sí àwọn ìpínlẹ̀ tó kù.
“Mi ò mọ bí owọ epo ṣe fẹ́ wálẹ̀ nígbà tí àwọn ọkọ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ nílò láti dé Eko láti Kano, Kaura Namoda àti láti gbogbo ìpínlẹ̀ ní Nàìjíríà kí wọ́n tó ra epo lọ́wọ́ Dangote pẹ̀lú gbogbo ọ̀nà tí kò dára báyìí.”
Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ pé yóò mú ìdúró ire bá owó náírà nítorí àwọn tó ń gbé epo kò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wá dọ́là kiri láti fi ra epo wọlé mọ́.
Ó ṣàlàyé pé òun kò mọ̀ bóyá ó máa ní ipa lórí ọ̀wọ́n gógó ní kíákíá.
“Ọ̀wọ́n gógó ṣì máa wà fún ìgbà kan ná nítorí mi ò ní ìgboyà pé NNPCL yóò ṣe àmójútó pínpín epo bẹntiróòlù bó ṣe yẹ tó fi máa mú àdínkù bá iye tí bẹntiróòlù jẹ́ báyìí.
A fẹ́ máa ra epo láti ọ̀dọ̀ Dangote fúnra wa
Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ àwọn alágbàtà epo bẹntiro ní Nàìjíríà ní àwọn fẹ́ máa ra epo lọ́wọ́ Dangote fúnra àwọn ni dípò kí àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ máa rà á láti ọwọ́ NNPCL.
Alukoro IPMAN, Chinedu Ukadike nínú ìròyìn iléeṣẹ́ The PUNCH kan sọ pé ó yẹ kí ìjọba àti NNPCL fi ààyè gba alágbàtà tó bá fẹ́ ra epo lọ́wọ́ Dangote ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú àlàkalẹ̀ wọn tẹ́lẹ̀.
Ó ní èyí yóò fún àwọn alágbàtà epo ní àǹfàní láti sọ pé iye kan ni àwọn fẹ́ máa ta epo àwọn nígbà tí àwọn bá ti ṣí owó ọkọ̀ tí àwọn fi gbé epo papọ̀.
Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ náà, ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn tó ní ilé epo ní Nàìjíríà, Billy Gillis-Harry sọ pé kò yẹ kí àwọn máa dúró de NNPCL nígbà tí àwọn lọ ń ra epo nílẹ̀ òkèrè kí àwọn tún máa dúró dè wọ́n ní orílẹ̀ èdè àwọn bákan náà.
Ó ní títí di ọjọ́ Àbámẹ́ta, àwọn kò mọ iye tí Dangote fẹ́ máa ta epo fún NNPCL débi tí àwọn máa mọ iye tí àwọn máa tà á.
Ó ní inú àwọn máa dùn tó bá jẹ́ pé iye tí Dangote fẹ́ ta epo dínwo sí iye tí àwọn ń rà á tẹ́lẹ̀ àmọ́ àwọn kò ì tíì gbọ́ nǹkankan nípa iye owó náà.
Ó fi kun pé gbogbo ìgbìyànjú ni àwọn ti ṣe láti bá iléeṣẹ́ Dangote sọ̀rọ̀ àmọ́ Dangote kò ṣetán láti dúnàádúrà pẹ̀lú àwọn.

Oríṣun àwòrán, NNPCL/X
Àwọn nǹkan tó yẹ kó o mọ̀ nípa ilé eṣẹ́ ìfọpo Dangote
Ní agbègbè Ibeju-Lekki ní ìpínlẹ̀ Eko ni ilé iṣẹ́ náà wà tó sì gbà tó sarè ilẹ̀ 2,635.
Gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ Dangote Group ṣe sọ, iléeṣẹ́ náà èyí tó lè fọ àgbá epo bẹntiro 650,000 lójúmọ́.
Tí ó bá ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, ó lè pesè epo bẹntiro tí Nàìjíríà nílò, tí yóò sì tún ṣẹ́kù tí wan lọ gbé lọ sílẹ̀ òkèrè fún títà.
Ó ní táǹkì 177 tó sì lè gba epo lítà bílíọ̀nù 4.742.
Iléeṣẹ́ náà ná wọn tó mílíọ̀nù ọ̀ọ́dúnrún yúrò gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde Dangote kan ṣe sọ.















