Ọkùnrin tó gún ààrẹ Comoros lọ́bẹ jáde láyé

Ààrẹ Comoros, Azali Assoumani

Oríṣun àwòrán, AFP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Àwọn aláṣẹ orílẹ̀ èdè Comoros ní ọkùnrin tó ṣe ìkọlù sí ààrẹ pẹ̀lú ọ̀bẹ lọ́jọ́ Ẹtì ni wọ́n bá òkú rẹ̀ ní àhámọ́ ọlọ́pàá tó wà.

Níbi ètò ayẹyẹ ìsìnkú kan ni ọkùnrin náà ti ṣe ìkọlù sí ààrẹ Azali Assoumani ní apá, tó sì farapa.

Olùpẹjọ́ fún ìjọba, Ali Mohamed Djounaid sọ pé lẹ́yìn tí ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin ọ̀húnni wan fi sí àháma kan lọ́tọ̀ kí ara rẹ̀ fi balẹ̀.

Wọ́n ní òkú ọmọkùnrin náà ni àwọn bá nínú yàrá tó wà ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta.

Djounaid sọ fún àwọn akọ̀ròyìn ní ìlú Moroni pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti fìdí ikú rẹ̀ múlẹ̀.

Mínísítà fọ̀rọ̀ ohun àmúṣagbára, Aboubacar Saïd Anli gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ìròyìn AFP News ṣe sọ, ní ààrẹ Assoumani wà ní àláfíà, pé kò ní ìpèníjà ìlera kankan.

Anli ní wọ́n kàn rán apá náà ni.

Wọ́n ní ọmọ ogun orílẹ̀ èdè náà ni Ahmed Abdou, ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún tó ṣe ìkọlù náà.

Ààrẹ Comoros farapa lẹ́yìn tí wọ́n gun l’ọ̀bẹ níbi ètò ìsìnkú

Azali Assouman

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ orilẹede Comoros, Azali Assoumani, ti farapa lẹyin ti ẹnikan dede gun lọbẹ nibi ode kan.

Ọkan lara awọ agbẹnusọ ijọba ilẹ naa sọ pe inu awọn dun pe o mọribọ ninu ikọlu ọhun.

Agbẹnusọ Aarẹ, Fatima Ahamada sọ fun ileeṣe iroyin Reuters pe ṣe ni wọn gun lọbẹ laskiko to yọju sibi eto isinku aṣaaju ẹsin kan lẹba ilu Moroni to jẹ olu ilu orilẹede naa.

O fi kun pe ọwọ ijọba ti tẹ ẹni to gun lọbẹ ọhun.

Ko si ẹni to tii le sọ eredi ikọlu naa titi di igba ti n ko iroyin yii jọ.

Bo tilẹ jẹ pe wọn tii kede orukọ ọkunrin to ṣakọlu naa, iroyin ni ọkan lara awọn ọmọ ogun orilẹede ọhun ni.

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ pe awọn ri afurasi naa to wọ aṣọ to gun ninu iyara ti wọn ti n kẹdun oloogbe ti wọn lọ ṣe oku rẹ.

Wọn ni o fi ọbẹ gun ọwọ Aarẹ naa ki ọkan lara awọn to n kẹdun oloogbe to da duro.

Ọdun 1999 ni Aarẹ Azali kọkọ gori alefa pẹlu iditẹgbajọba.

Lẹyin ọdun mẹwaa si asiko naa ni o jawe olubori ninu eto idibo ti inu ọpọ araalu ko yọ si lọdun 2016, ki wọn to tun fi ibo gbe wọle ninu oṣu Kinni, ọdun 2023.

Wayi, ọpọ araalu ni Comoros lo ti fẹsun kan Aarẹ ọhun pe o n ṣejọba bo ṣe wu ti ẹnikẹni ko si le gbena woju rẹ.