Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Omi o lapa omi o lẹsẹ, omi n wọ yanrin kẹrẹrẹ
Bẹẹ ni bomi ṣe wulo to naa lo ṣe lewu to
Iiroyin to n tẹ wa lọwọ lo sọ pe ni ṣe lawọn oṣiṣẹ adoola ẹmi n ṣa oku eeyan to lefoo lori omi niluu Maiduguri
Latari iṣẹlẹ omiyale to ṣọṣẹ nipinlẹ Bornu
Aṣoju akọroyin BBC to wa niluu Maiduguri ni eto idoola ẹmi si n lọ lọwọ nibẹ
ẹwẹ, Gomina Babagana Zulum ipinlẹ Borno ti ṣalaye pe ko din ni miliọnu meji eeyan ti omiyale ọhun ti ṣakoba fun
Gomina sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC wi pe o digba tomi naa ba lọọlẹ tan
Ki ijọba to le sọ pato iye eeyan to ba iṣẹlẹ naa lọ ati iye dukia to bajẹ
K’Eledua ma fomi bawa ja
Yoruba bọ wọn ni ti ọmọ ẹni ba dara ẹ jẹ ka wi tori a o ni fi ṣaya
Bẹẹ ni o Ajanaku Cristiano Ronldo kọja mo ri nnkan firi
Gbajugbaja ẹlẹsẹ ayo Ronaldo lo ti kede pe awọn olololufẹ oun lori itakun ayelujara ti di biliọnu kan bayii.
Haha iyẹn tun gbénutan o
Bẹẹni, kan si oju opo BBC.COM/Yoruba fun ẹkunrẹrẹ iroyin
Duro naa akinlabi, eyaan meloo lo n tẹle ọ lori itakun ayelujara na?
Iwọ ṣa maa wo n
