WHO buwọ́lu abẹ́rẹ́ àjẹsára Monkeypox fún lílò àgbáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ eleto ilera agbaye WHO tí buwọlu abẹrẹ ajẹsara MVA-BN, eyi to jẹ abẹrẹ ajẹsara akọkọ fun idena itankalẹ aarun Monkeypox.
Igbesẹ yii waye lati jẹ kí abẹrẹ naa tete de sibi ti wọn ti nilo rẹ lati gbe ogun ti itankalẹ aarun Mpox.
Bavarian Nordic A/S lo pelo abẹrẹ naa, ti ajọ Europe Medicine Agency si se ayẹwo rẹ.
Tẹlẹ, ko si abẹrẹ ajẹsara fun aarun Mpox, eyi to fa ti wọn n fi lo abẹrẹ ajẹsara small pox lati koju rẹ nitori aarun mejeeji jọ ara wọn.
Ọga agba fun WHO, Dokita Tedros Adhanom Ghebreyesus gba niyanju pe ki wọn yara lati gbe abẹrẹ ajẹsara naa lọ ilẹ Afrika ati awọn agbegbe mii ti aarun naa ti n ja.
"Bibuwọlu abẹrẹ ajẹsara yii lo jẹ igbesẹ to ṣe koko lati koju aarun yii lọwọ yii ati lọjọ iwaju."
Bawo ni wọn ṣe maa gba abẹrẹ yìí?
Abẹrẹ ajẹsara MVA-BN ni wọn yoo ma gba ni ẹẹmeji laarin ọsẹ mẹrin.
Dokita Yukiko Nakatani salaye pe bibuwọlu abẹrẹ ajẹsara yii yoo ran ijọba ati awọn ajọ bi Gavi ati Unicef lọwọ lati gba abẹrẹ naa, ti wọn yoo si pese rẹ fun awọn to nilo rẹ.
Abẹrẹ naa ko wa fun awọn ọmọde tí wọn ko ti pe ọdun mejidinlogun.
WHO gba lamọran pe ki awọn eeyan gba abẹrẹ kan, eyi ti o ṣíṣẹ ni ida 76%, ti abẹrẹ ajẹsara meji sì n sisẹ ni ida 82%.
Itankalẹ aarun yii lo bẹrẹ ni orilẹede Democratic Republic of Congo ati awọn agbegbe to yi ka, ti WHO si kede ilu o fararọ lori aarun naa ni oṣu to kọja.
Lati ọdun 2022, o le ni eeyan 103,000 to ti lugbadi aarun naa ni orilẹede 120.
O le eeyan 700 to ti padanu ẹmi wọn ni ilẹ Afrika.














