Kí ló dé táwọn ọmọbinrin Japan ṣe ń gùn lọ́rùn?

Aworan Sarah Mizugochi

Oríṣun àwòrán, Sarah Mizugochi

    • Author, Issariya Praithongyaem
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Nigba ti o wa ni ọmọde, Sarah Mizugochi ti o ga ni iwọn ẹsẹ bata marun un, ni ko saara, to si gun lọrun pupọ.

“Mo maa n ronu nipa ounjẹ ni gbogbo igba ti ebi si n pa mi nigba gbogbo. Igba kan ṣoṣo ti mo maa n jẹ akara oyinbo ni ọjọ ibi mi ati pe iyẹn ti wa fun ọdun mẹta si mẹrin. Inu mi ko dun rara.”

Awọn iṣẹlẹ bii ti Sarah's, ẹni to jẹ ogun ọdun bayii, jẹ eyi ti o wọpọ ni Ilu Japan, ti aisanra awọn ọdọmọbinrin si ti di iṣoro ilera to lagbara.

Iwadii kan ti ẹka ilera ti Ilu Japan ṣe ni ọdun 2019 rii pe ida 20.7% tabi ọkan ninu obinrin marun un ti o wa ni ọjọ-ori ogun si mọkandinlọgbọn ni wọn ko sanra, eyi ti o jẹ asọye BMI (Atọka Mass Ara) ti o kere ju ida18.5. BMI ti Sarah kere ju ohun ara sisan to ni ilera to peye yẹ ko wa

Ajọ to n ri si ilera ni agbaye (WHO) ni awọn eeyan to n ṣe ifọkansi fun BMI wọn wa laaarin ọdun 18.5 si 25.

Japan nikan ni orilẹ-ede ti o n gba owo nla wọle ni agbaye pẹlu iru itankalẹ aisanra laarin awọn obinrin wọn.

Irufẹ nnkan bayii naa wa ni awọn orilẹede bii Timor-Leste, Burundi, Eritrea ati Niger, gẹgẹ bii iwadii 2024 kan lori awọn aṣa agbaye nipa aisanra ati sisanra ju ti wọn gbe jade ninu iwe akọọlẹ iṣoogun Lancet medical Jorunal.

Ni ọdun 1990, awọn obinrin Japanese kere ju bi wọn se wa lonii.

Ọpọ imọ ati awọn iwadii orilẹ-ede ti ṣafihan iṣẹlẹ gẹgẹ bii aṣa laarin awọn ọdọbinrin.

Ni ọdun diẹ sẹyin, ọrọ yii "iwọn Cinderella" wọpọ laaarin awọn ọdọbirin ni Japan. Ọrọ naa tọka si BMI to kere ju bi o ṣe yẹ ko wa lọ, eyi ti ko ni ilera lori iwọn BMI, ṣugbọn ọpọlọpọ awọn obinrin nifẹẹ lati ṣaṣeyọri yii.

Ọpọ eeyan lo kọyin si ero yii nitori ko ni alaafia ninu rara.

Asa

Aworan awọn ọdọ ọmọbinrin Japanese ninu aṣọ kimono

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Tomohiro Yasuda, ọjọgbọn ni Ile Ẹkọ Nọọsi ni fasiti Seirei Christopher ni ilu Hamamatsu, agbegbe Shizuoka, ní Japan, kẹkọọ nipa awọn ọdọmọbìnrin ará Japan tí wọn ko sanra.

Iwadi rẹ fihan pe bi o tilẹ jẹ pe awọn obinrin gba pe wọn nilo lati sanra, oye nipa iye ara sisan ti wọn nilo lo kere gan.

Awọn obinrin ti ko sanra yii to kopa ninu iwadii yii nilo lati sanra ni iwọn 10.3kg lati de biti BMI só pe ki obinrin sanra de eyi to ni ilera pupọ ṣugbọn nigba ti wọn beere lọwọ, ọpọ wọn sọ pe wọn fẹ sanra ni iwọn apapọ 0.4kg.

"Ni ilu Japan, itankalẹ wa ninu awọn ọdọbirin ti wọn ko sanra, eyi to lewu fun airiọmọbi, ai ri ara gbe oyun le sokunfa ọpọ ijamba, o sọ fun BBC.

Aìjẹunkanu le yọri si ipadanui egungun, ẹjẹ, ati airi nnkan oṣu, nigba ti ko ba si eroja protein eyi to maa n yọri si idaamu iṣan ara.

Diẹ ninu awọn ọmọ akẹkọọ ni kilasi Ọjọgbọn Yasuda lori sisanraju ati aisanra sọ fun u pe wọn fẹ lati padanu ọra ara nitori awọn ilumọka wọn jẹ eeyan ti ko sanra.

"O ni nnkan se pẹlu ohun ti wọn n wo lori ayelujara Japan ati ifẹ wọn si aṣa orilẹede Amẹrika ati Europe, eyiti o ti n ṣe asiwaju aṣa ati awọn ẹya miiran nipa aṣa Japanese fun igba diẹ," o sọ.

Ọjọgbọn Yasuda ṣalaye pe, ni oritakun ayelujara Japan, awọn ọkunrin han bi eniyan ti awọn ọjọ-ori dagba ati pe irisi wọn fihan, sugbọn obinrin ni wọn da bi ọmọde.

“Ati nItorI bi ọpọ ọdọbìnrin se ri ti wọn ko sanra yii, mo ro pe o ni nnkan se pẹlu ọrọ ti ni awọn obinrin lẹpa lo dara.

Ti awọn nnkan to wa ninu iroyin ba ṣe akoba fun ẹ, ri daju lati kan si awọn onimọ ilera fun imọran to tọ.

Irinajo Sarah's lati di onimọ nipa ounjẹ lori ayelujara

Aworan Sarah Mizugochi

Oríṣun àwòrán, Sarah Mizugochi

Sarah Mizugochi, ẹni to ti di ọnimọ nipa ounjẹ , to n gbe niluu olu ilu Japan, Tokyo, sọ pe awọn obi rẹ gba ni iyanju pe ko ma sanra nigba to wa ni ọmọde.

“Mama mi ko fẹ ki n sanra,” o sọ fun BBC.

Ni akoko ounjẹ, wọn maa n sọ fun un pe ko jẹ ẹran ati ewebẹ dipo irẹsi, eyi to ni ọpọ eroja carbohydrates, ti ko fi bẹẹ wulo.

Iwa yii wa pẹlu rẹ fun ọpọlọpọ ọdun.

Apoti bento kekere ti o maa n gbe lọ si ile ẹkọ fun ounjẹ ọsan jẹ ewebẹ ati ẹran: “N ko fẹ jẹ ìrẹsì rara.”

Laarin ọjọ ori ti 12 si 15, nitori Sarah fe di ojuloge. O ni aniyan nipa awọn nnkan to n jẹ sikun bi kaori.

“Ni ile ẹkọ, mo ba ọmọbìnrin miiran dije. Ni ọjọ kan, o jẹ saladi, edamame, ati ẹran ẹlẹdẹ diẹ fun ounjẹ ọsan. Mo ranti pe mo sọ fun un pe ounjẹ rẹ kun fun awọn kalori!”

Aworan Sarah Mizugochi pẹlu ounjẹ

Oríṣun àwòrán, Sarah Mizugochi

Sarah bẹrẹ si i ri idi to fi ni lati jẹ ounjẹ pupọ si i nigba to ka iwe nipa Biology ni ile ẹkọ girama.

“Mo kọ ẹkọ nipa ẹya ara eeyan ati pe iyẹn jẹ akoko gilobu ina. Ah! Gbogbo wa nilo ounjẹ. ”

Lẹyin ija nla to waye ni Japan, o lọ si UK o si ṣe awari pe eniyan ko bikita pupọ nipa jijẹ kalori. O jẹ kilo mẹta sii ara rẹ.

“Mo ni ayọ ni ile-ẹkọ giga titi emi o fi pada si Japan fun isinmi. Awọn eniyan ti o wa ni ayika mi, pẹlu iya mi, sọ pe mo ti sanra. Nitori naa mo ni lati padanu awọn kilo diẹ, ṣugbọn iyẹn ko pẹ.”

Sarah bẹrẹ lati jẹ iresi lẹẹkan si nigba ti o pe ọdun 25, ọdun mẹrin sẹyin.

“Inu mi dun pupọ ati ilera mi si dara; Mo jere 7kg. Mo ni awọn iṣan.”

Titako awọn nnkan ẹwa ni Japan

Aworan Dulmi Obata

Oríṣun àwòrán, Asako Nakamura

Awọn eniyan miiran ni Ilu Japan n bẹrẹ lati koju aṣa ara sisan ati awọn iṣedede ẹwa.

Dulmi Obata, 25, jẹ idaji Japanese, idaji Sri Lanka, o si n gbe ni Kanakawa, agbegbe eti okun ni guusu ti Tokyo.

Awọ dudu ara rẹ, sisanra ati irun rẹ to yatọ lo fa ti ọpọ fi n bu ni ile ẹkọ.

Ni ile-iwe alakọbẹrẹ, awọn ọmọkunrin kan n pe ni ọmọbinrin dudu. Awọn ọmọde kekere ko fẹ gba nnkan lọwọ rẹ.

“Wọn ro pe ọwọ mi dọti. O dun mi,” Dulmi ṣalaye.

Aworan Dulmi Obata

Oríṣun àwòrán, Asako Nakamura

O bẹrẹ si i ma ri pe o da yatọ, to si ni iṣan lara, nigba to di ọlọmọge ni bi ọmọ ọdun mẹtala sugbọn eyi ko ba lẹru rara.

Ni ọdun 2021, lẹyin ṣiṣe iwadii lori ojuloge to sanra , Dulmi wọ inu idije Miss Universe Japan, ni mimọ pe awọn obinrin miiran yoo gun lọrun.

“N ko fẹ padanu ara sisan mi lakoko idije naa. Mo fẹ gbe sita pe ara sisan kii ṣe nnkan buburu. Mo fẹ ayipada ni Japan.”

Dulmi pegede de aṣekagba idije naa. O gbagbo pe oun nikan ni obinrin to sanra to de ipele naa.

“Dajudaju, Mo kan sara si ara mi. Awọn iriri mi nigba ti mo wa ni ọmọde jẹ ki n padanu igbagbọ ninu ara mi. Mo mọ pe mo le ma ni igbẹkẹle 100% [bayii], ṣugbọn iyẹn dara,” o sọ.

Ki ni ijọba n ṣe lori aṣa aifẹ sanra ni Japan?

Awọn ijọba orilẹ ede Japan ti n gbiyanju lati koju iṣoro awọn obinrin ti ko fẹ sanra pẹlu pipese itọsọna ounjẹ aṣara loore fun awọn ọmọ ile ẹkọ.

Ni Oṣu Kẹta ọdun 2000, ijọba ṣe idasilẹ awọn itọsọna ounjẹ fun Japanese. Ọkan ninu awọn itọnisọna ni imọran pe awọn olugbe le mojuto ara wọn pẹlu ere idaraya, jijẹ ounjẹ aṣara loore, ki wọn si dẹkun fifi ebi pa ara wọn lati ma le sanra.

Ni ọdun 2022, ijọba ṣe ifilọlẹ ipilẹṣẹ kan ti o pe ọpọlọpọ awọn ẹya awujọ lati kopa. Ipilẹṣẹ yii jẹwọ pe awọn iṣoro ai fẹ sanra wọpọ laarin awọn ọdọmọbinrin ni awujọ.

Awọn alaṣẹ agbegbe, pẹlu eyi to wa ni Ilu Yamato, agbegbe Kanagawa, ni ita Tokyo, gbiyanju lati ṣe idanilẹkọ lori idi to yẹ ki awọn ọdọmọbinrin fi ma jẹ ounjẹ to n ṣe ara wọn loore.