Ọmọṣẹ́ olùdásílẹ̀ Gokada tó pa ọ̀gá rẹ̀ rí ẹ̀wọ̀n ogójì ọdún he

Aworan Fahim Saleh

Oríṣun àwòrán, Instagram/@gokadang

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ile ẹjọ ni Manhattan tí ran oludamọran tẹlẹ fun Fahim Saleh si ẹwọn ogoji ọdun fun bi o ṣe ṣekupa Ọga rẹ, ẹni to ni ileeṣẹ Gokada.

Ọkunrin naa, ẹni ọdun mẹẹdọgbọn. Tyrese Haspil ni ile ẹjọ rí pe o jẹbi awọn ẹsun ti wọn ka sí lẹsẹ nípa isekupani.

Haspil yoo jẹ ẹni ọdun mokanlelọgọta nigba ti yoo kuro ni ọgba ẹwọn.

Ile ẹjọ ran lọ sí ẹwọn ọdun mẹẹdọgbọn fun iṣekupani ati ẹwọn ọdun mẹẹdogun fun kiko owo oloogbe, jíjà wọ ile rẹ ati bi o ṣe ṣe oku oloogbe.

Gẹgẹ bii atẹjade to jade ṣe salaye, Haspil gbiyanju lati bo asiri rẹ.

Agbẹjọro awọn mọlẹbi ni ẹjọ yìí yoo fi awọn mọlẹbi lọkan balẹ bo ti lẹ jẹ pe ko le da ọmọ wọn padà.

"Lonii, Tyrese Haspil foju ba ile ẹjọ fun ẹsun ipaniyan Fahim Saleh, ọdọmọkunrin to n ṣe rere. Leyin ti Haspil ba jale, Saleh yoo tun da aṣọ asiri bo," Agbẹjọro Bragg sọ fun ile ẹjọ.

"Igbẹjọ oni ko le da Saleh pada. Mo lero pe yoo fi awọn mọlẹbi lọkan balẹ."

Aworan Fahim Saleh

Oríṣun àwòrán, Getty Images/@fahims/Instagram

Ki lọ sẹlẹ ṣaaju?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọwọ ọlọpaa tẹ oluranlọwọ pataki oludasilẹ ileeṣẹ ọlọkada to n jẹ Gokada eyi ti wọn ba oku ara rẹ nilẹ inu ile nla kan ni agbegbe Manhattan Lower East lọsan gangan ọjọ Iṣẹgun.

Gẹgẹ bi iwadii ṣe fidsi rẹ mulẹ, ni ọjọ Kẹtala oṣu Keje ọdun 2020 ni Haspil lọ si iyẹwu Salah pẹlu ọbẹ ati taser lọwọ to si wọ aṣọ iboju ki Saleh fi ma da mọ.

O tẹle Saleh wọ inu ẹrọ to maa n gbe eeyan gun oke to si gun ni ọrun titit ti ẹmi fi bọ lara rẹ.

Haspil lọ sile ọga rẹ ni ọjọ keji lati lọ sọ awọn nnkan to le jẹ ẹri fun awọn ọlọpaa nu to si ge awọn ẹya ara oloogbe naa kan danu.

Aburo Oloogbe Saleh lo ri ara ẹgbọn rẹ nigba ti o lọ bẹẹ wo tori pe ko gburoo rẹ fun ọjọ kan, awọn ọlọpaa ni nigba to ri oku rẹ nilẹ lo kan si awọn.

Nigba ti awọn agbofinro bẹrẹ iwadii, wọn ba ara Saleh lai si ọwọ ati ẹsẹ rẹ mọ ti wọn si ri abẹ oni ina kan ti wọn fi maa n gegi lẹgbẹ rẹ.

Awọn ọlọpaa meji kan lo jabọ ohun toju wọn ri pe wọn pada ba ori ati ara rẹ nikan ninu ile naa.

Wọn ko tete da a mọ pe oun ni ṣugbọn ọpọlọpọ awọn ọrẹ rẹ to sọrọ lori iṣẹlẹ yii sọ pe awọn ko fẹ darukọ ara awọn pe Fahim Saleh gangan ni oku ẹni ti wọn ri to jẹ oniṣowo imọ ẹrọ igbalode to si jẹ oun lo ni ile ti wọn ti ba oku rẹ nilẹ.

Taa ni Fahim Saleh?

Wọn bi ẹni ọdun mẹtalelọgbọn yii si ilu Saudi Arabia, ti awọn obi rẹ si jẹ ọmọ orilẹ ede Bangladesh.

Nigba to ya ni gbogbo wọn kuro ni Saudi Arabia lọ si New York, Amẹrika lati lọ gbe.

Fahim Saleh bẹrẹ ileeṣẹ ọkada, Gokada lorilẹede Naijiria ni ọdun 2018.

Ileeṣẹ yii niluu Eko kọ ni ileeṣẹ rẹ akọkọ, o sẹda irufẹ rẹ Pathao, si ilu Bangladesh ni ọdun 2015.