Iṣẹ́ wo ni 'Ice cream' ń ṣe fún ọpọlọ, àti pé ta ló kọ́kọ́ ṣe é jáde lágbàáyé? Àlàyé rèé

Aworan Tapiwa Guzha to mu kọpu ice cream da ni

Oríṣun àwòrán, YouTube @tapiwaguzhamade

Àkọlé àwòrán, Aworan Tapiwa Guzha to mu kọpu ice cream da ni
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ẹ jẹ ka bẹrẹ pẹlu ibeere pe ki lode ti a fẹran ohun amu inu tutu, ti a n pe ni koronu, eyi ti oloyinbo n pe ni ‘Ice Cream’?

Idi ti ọpọ eeyan fi fẹran ohun amu inu tutu yii lo ni atilẹyin imọ sayẹnsi.

Awọn onimọ ti ṣe ayẹwọ lori ohun amu inu tutu yii, awọn eroja aṣaralore rẹ ati awọn ipenija to mu ba ilera ara.

Bakan naa ni iwadii wa lori bi ohun amu inu tutu se le mu ayipada ba ero wa.

Institute of Psychiatry ni Ilu London ti wọn da silẹ lọdun 2021 se iwadi pe ọpọlọ awọn eeyan ma n gbe igbesẹ lẹyin ti a ba tọ ohun amu inu tutu wo.

Awọn iwadii miiran ṣe afihan pe awọn eroja bi Protein ati fat wa ni ọpọ ninu amu inu tutu Ice cream ti wọn ba se daada, ti si ma mu ara awọn eeyan ji pepe.

Eyi lo ṣalaye idi ti awọn eeyan fi fẹran lati ma je ohun to ba dun lorekore.

Amu inu tutu yii lo kun ọpọ suga, ọra, nnkan tutu, eyi ti ọpọ eeyan fẹran lati ma rọ mi si ikun.

Orisun amu inu tutu Ice Cream yii lo fa ọpọ ariyanjiyan fun ọpọ awọn onitan.

Ọpọ awọn ẹya ni Ọlọrun fun ni iyin, ti wọn si sẹda ọpọ ati ohun mimu pẹlu rẹ.

Awọn ara Rome maa n lọ ko iyin lati ori apata nigba kan lati fi se ohun eso mimu.

Ninu iwe rẹ, Laura B Weiss kọ nipa bi wọn se n po miliki maalu, ọgbukọ ati ẹfọn papọ, eyi ti wọn yoo gbe lena pẹlu ọpọ eroja mii.

Aworan kọpu amu inu tutu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ice cream, gelato tabi sorbet?

Robin Weir, ẹni to kọwe nipa amu inu tutu Ice Cream, ti o pe orukọ rẹ ni, Ice Cream, Sorbets ati Gelati gba ni imọran pe ki a wo ọna meji to se iranlọwọ lati mọ awọn to sẹda amu inu tutu naa.

Lakọkọ, a ni lati ṣalaye ohun ti amu inu tutu.

“Lati le ye ọpọ, amu inu tutu jẹ ni iwe ti a kọ nnkan si ninu sugbọn sorbet ko ni,” o sọ fun BBC lọdun 2022.

“Gelato, eyi to wa lati Italy, ko ni iyin ninu rẹ.

“Amu inu tutu jẹ ohun iyalẹnu fun mi nitori eroja kekere lo wa ninu rẹ, bi suga, omi, boya, miliki, iyin ati awọn ohun aladun- o da lori bi o ba se le po wọn papọ.

Ọna keji lati wa orisun Ice cream ti Weir alaye ni lati se iwadii lori nigba ti awọn ṣawari ohun ti oloyinbo n pe ni enthothermic effect- ilana to ni ki eeyan ma po iyọ mọ iyin lati pẹtu si nnkan to gbọna.

Laura B Weiss ṣalaye pe awọn Chinese, Arab ati India ti wọn farahan ninu itan lori oye wọn nipa endothermic effect to ṣalaye nipa pipo nnkan pọ.

Aworan ''ice cream'' to dabi ile atijọ lorilẹede Persia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan ''ice cream'' to dabi ile atijọ lorilẹede Persia
Aworan Kitty Travers lati ilu London

Sise orisiris aladun ni ilana ibilẹ

Awọn ọmọde n mu amu inu tutu Ice Cream

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Loni, amu inu tutu ice cream jẹ ile-iṣẹ agbaye ti n pawo toto $ 103.4bn ni ọdun 2024, gẹgẹ bii iwadii se ṣalaye.

Ni ifiwera, awọn owo ti n wọle fun ohun mimu chocolate ati kọfi jẹ $ 133.6bn ati $ 93.46bn.

Awọn adun to n pese lọwọ yii ni wọn ti n se ni ilana ti ibilẹ, to si n pe adun nnkan ibilẹ

Tapiwa Guzha, ti o ni ile iṣẹ idana kan ni South Africa niluu Cape Town, ni wọn n sọrọ rẹ lori ayelujara ni ọdun 2022 pẹlu bi o se fi ẹja gbigbẹ se amu inu tutu ice cream.

Onimọ ijinlẹ nipa ẹya ara lati orilẹede Zimbabwe ṣe apejuwe ara rẹ gẹgẹ bi onimọ ounjẹ pẹlu ero sayẹnsi.

O sọ fun BBC pe: “Emi ko pinnu lati ṣe awọn adun ajeji tabi oriṣiriṣi, Mo kan n ṣe awọn adun ti o ni ṣe pẹlu afihan eto ounjẹ agbegbe ni [Afirika].

"Ounjẹ mi ni lati ṣe afihan awọn ounjẹ lati ẹya oriṣiriṣi ni Afrika."

Amu inu tutu miliki Mare

Àkọlé fídíò, N jẹ wa le mu ohun amu inu tutu yii

Ohun amu inu tutu tuntun bayii wa lati Poland.

Awọn oniwadi lati Ile-ẹkọ Imọ-ẹrọ ti Oorun Pomeranian ni Szczecin gbinyanju lati se ohun amu inu tutu mare, eyi ti fara pẹ lilo miliki maalu.

Iwadi ti wọn gbejade ni Oṣu Kẹjọ tun daba pe wara mare le ṣe iranlọwọ lati mu ilọsiwaju ilera inu eeyan dara, ṣugbọn a si nilo ọpọ iwadii.

Wara ẹhin ni wọn n lo ni aringbungbun Asia fun igba pipẹ, ṣugbọn ṣiṣe amu inu tutu lati ara rẹ lo jẹ tuntun.

Kitty Travers ti ṣe ayẹwo wọn elo yii

Nigbati BBC ṣabẹwo si i ni ipari Oṣu Kẹjọ, o ti ṣe ipele miiran nipa lilo awọ eso pia, eruku adodo fennel ati awọn irugbin lati ṣe amu inu tutu Mare.

Lẹyin ọsẹ, o ṣe adun tuntun ni ibi ayẹyẹ kan, ti awọn ọrẹ si i ki kaare