Àwọn wo tún ni ọlọ́pàá ‘Supernumerary Police’ àti pé kí ni iṣẹ́ wọn láwùjọ?

POlice

Oríṣun àwòrán, Muyiwa Adejobi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹnu ọjọ mẹta yii awuyewuye bẹrẹ lẹyin ti ọlọpaa to n pese abo kan sọrọ lori eto idibo gomina ti yoo waye nipinlẹ Edo.

Ọlọpaa naa ti wọn ko fi orukọ rẹ lede sọ pe ole ni ọkan lara awọn oludije sipo gomina ipinlẹ Edo, ti ko si yẹ ki awọn eeyan fi ibo wọn gbe wọle.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti sọ pe ‘Supernumerary Police Officer’ ni ọkunrin naa, ati pe ko gbẹnusọ fun oun.

Koda, awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ti ni ki wọn fi ṣikun ofin mu afurasi naa latari pe ko ko ara rẹ ni ijanu.

Latari iṣẹlẹ ọhun, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejobi ti kede pe iyatọ wa laarin ọlọpaa to n pese abo ‘Supernumerary Police Officer’ ti wọn tun mọ si ‘ Spy police’ atawọn ọlọpaa to n ṣewadii iwa ọdaranlaarin ilu.

Lasiko to n fi iyatọ naa lede loju opo X rẹ, Adejobi fi aṣọ awọn ‘ Spy police naa lede.

Awọn wo ni ''Supernumerary Police?''

Aworan aṣọ ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Muyiwa Adejobi/X

Adejobi ni ọlọpaa aladani ni awọn Supernumerary Police amọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria naa lo ṣe idanilẹkọọ fun wọn.

O ṣalaye pe awọn aladani ni wọn n ṣiṣẹ fun lati maa pese eto abo.

O ni “kii ṣe ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria lo n sa owo oṣu fun, nitori naa wọn ko bura fun Naijiria gẹgẹ bii awọn ọlọpaa to ku.

“Fun idi eyi, wọn lẹtọọ lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu to ba wu wọn bẹẹ ni wọn si le sọrọ nipa ohunkohun to ba wu wọn.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọlọpaa ko lẹtọ lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu tabi ṣe ifẹhonuhan ni Naijiria, bẹẹ ni kii ṣe gbogbo ọrọ ni wọn le da ni gbangba.

Bawo ni aṣọ Supernumerary Police Officer ṣe ri?

Aṣọ ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Muyiwa Adejobi/X

Iyato diẹ lo wa ninu aṣọ awọn Spy Police atawọn atawọn ọlọpaa.

Ileeṣẹ kan naa lo n pese aṣọ awọn mejeji.

Awọn naa n wọ kaki, aṣọ wọn ni okun lapa, wọn n wọ bata bii ti ologun, koda wọn n gbe ibọn.

Wọn kọ Supernumerary Police si ara aṣọ wọn gadagba-gadagba dipo Nigeria Police ti wọn kọ si ara aṣọ ọlọpaa ilu.

Ofin wo lo gbe Supernumerary Police Officer kalẹ?

Ofin Police Act ti ọdun 2020 to sọrọ nipa ojuṣe awọn ọlọpaa lo sọrọ nipa ojuṣe awọn ọlọpaa yii kan naa.

Gẹgẹ bi amofin Okorafor Chidiebere John ṣe sọ, ẹnikẹni tabi ileeṣẹ to ba nilo awọn ‘spy police’ gbọdọ kọwe ẹbẹ si ọọfisi ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa, IGP, pe oun nilo wọn fun abo.

Ẹnikẹni tabi ileeṣẹ bẹẹ gbọdọ ṣalaye ni kikun eredi ti oun fi nilo awọn ọlọpaa ọhun ati iṣẹ ti wọn yoo maa ṣe fun.

Lẹyin iwadii ni kikun ni ileeṣẹ ọlọpaa, pẹlu ifọwọsowọpọ ajọ Police Service Commision, PSC, yoo fun irufẹ ẹni bẹẹ ni ‘Spy Police.’

Wayi o, ẹni to bẹbẹ fun Spy Police ni yoo maa san owo oṣu rẹ, kii ṣe ileeṣẹ ọlọpaa, bẹẹ ni Spy Police ọhun ko ni awọn anfani kan bii owo ifẹyinti lọdọ ileeṣẹ ọlọpaa Najiria.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post