Bàbá ọlọ́pàá tó pa ọmọ mi ti wá bẹ̀ mí, àmọ́ ìdájọ́ òdodo ni mò ń fẹ́ - bàbá akẹ́kọ̀ọ́ Kwara Poly tó d'olóògbé

Àkọlé fídíò, Àwọn òbí akẹ́kọ̀ọ́ Kwara Poly táwọn afurasí ọlọ́pàá 'yìnbon pa' ń bèèrè ìdájọ́ òdodo
Bàbá ọlọ́pàá tó pa ọmọ mi ti wá bẹ̀ mí, àmọ́ ìdájọ́ òdodo ni mò ń fẹ́ - bàbá akẹ́kọ̀ọ́ Kwara Poly tó d'olóògbé

Ogbeni Abdulyekeen Muslim Ayinla ati iyawo rẹ Ramat Abdulyekeen ti wọn jẹ obi Abdulqoyum Bamidele Ishola, akẹkọọ ile ẹkọ gbogbonise Kwara Poly niluu Ilorin, ipinlẹ Kwara ti wọn ni afurasi ọlọpaa yinbon pa si duro lori idajọ ododo lori iku ọmọ wọn.

Baba oloogbe naa ni oun ko le pari ile ti toun n gbe nitori awọn ọmọ oun, ki wọn ba le ni ẹkọ to ye kooro.

‘’Buọda mi lo ṣadeedee pe mi lọjọ naa wi pe ọmọ mi ni ijamba ọkọ wi pe ki n maa bọ.

Ipo to wa nigba ti mo ri i nile iwosan fihan pe wọn ti da ẹmi rẹ legbodo, eyi lo jẹ ki omi bọ loju mi,'' Ogbeni Abdulyekeen lo sọ bẹẹ.

''Ọmọ mi kii ṣe onijọgbọn''

Ogbeni Abdulyekeen ni ''ọmọ mi kii ṣe onijọgbọn, to ba wa ninu ile gan an, eeyan o le mọ pe o wa ninu ile.

Wọn o gbe iwa ọdaran wa ba mi nile nipa ọmọ mi ri lati ọjọ ti mo to bi i.

Awọn eeyan to wa lagbegbe iṣẹlẹ ọhun ti waye sọ fun mi pe lootọ lawọn gbọ iro ibọn.''

Baba oloogbe naa ni baba ati ẹbi ọlọpaa to pa ọmọ oun ti wa bẹ oun wi pe koun ṣe aforijin fawọn tori aṣiṣe ni.

Amọ, o ni oun jẹ ko ye wọn pe ọrọ naa kii se bi ko ṣe ti jọba nitori o kọja agbara oun.

Ogbeni Abdulyekeen ni oun mọ pe wọn ti da oun loro, amọ, o ni oun n wa idajọ ododo ki iru iṣẹlẹ yii ma ba le maa ṣẹlẹ mọ.

‘’Awọn ọlọpaa yii naa ti figba kan ri mu ọmọ mi mọlẹ nigba to n lọ sile ẹkọ rẹ, wọn si gba foonu lọwọ rẹ.

Wọn o ri nkan kan ninu foonu rẹ nigba ti wọn wo o, lẹyin naa ni wọn ni ki n lọ mu N500,000 wa lati beeli rẹ.

Mo ni lati san N50,000 fun wọn ki ọmọ mi ma ba sun agọ ọlọpaa lọjọ naa.

Mo mọ pe awọn ọlọpaa ti da ẹmi ọmọ mi legbodo, amọ, mo fẹ idajọ ododo lori iku rẹ.

''Idajọ ita gbangba ni mo fẹ lori iku ọmọ mi''

Ninu ọrọ tirẹ, mama oloogbe naa, Ramat Abdulyekeen sọ pe idajọ ita gbangba ni oun fẹ latọdọ ijọba ki wọn si ma ṣe ọrọ naa ni bonkẹlẹ.

"Mi o fẹ ki iya yii jẹ mi gbe. Ṣowo ile ẹkọ ni ka sọ ni, ọmọ ti mo n wo ti wọn si fi lami loju, idajọ ododo ni mo fẹ o,'' Ramat lo sọ bẹẹ.

Kinni ọlọpaa sọ lori iṣẹlẹ naa?

Ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria, IGP Kayode Adeolu Egbetokun, ti paṣẹ pe ki iwadii kikun waye lori ohun to ṣokunfa iku Qoyum Ishola Abdulyekeen.

Ọga ọlọpaa sọrọ yii ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejobi fi sita lana ọjọ Aje.

Ni bayii, awọn ọlọpaa tọrọ naa kan, Insipẹkitọ Abiodun Kayode, Insipẹkitọ James Emmanuel, and Sajẹnti Oni Philip, ti wa ni ahamọ ọlọpaa nigba ti iwadii n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ ọhun.

Ọga ọlọpaa Egbetokun kẹdun pẹlu ẹbi, ọrẹ atawọn akẹgbẹ rẹ nile ẹkọ giga Kwara Poly lori iku Ishola.

O fi dawọn loju wi pe idajọ ododo yoo waye lori iṣẹlẹ naa.

Ṣaaju ni agbenusọ ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara, DSP Ejire Adeyemi Adetoun, naa ti sọ pe iwadii to peye si n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.

DSP Adeyemi ni lotitọ gẹgẹ bi awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa ti wi, ọwọ ọlọpaa wa ninu ọrọ naa nitori awọn lo da wọn duro, sugbọn ohun to sẹlẹ lẹhin ti wọn dawọn duro ni awọn ko tii le sọ.

O salaye pe "awọn o so ju mi koro lo sọ ọ pe oloopa lo da wọn duro, kii se pe awọn ọlọpaa naa jẹwọ pe awọn ṣe bẹẹ gẹgẹ.

"Sugbọn ju gbogbo rẹ lọ, a ti mu awọn ọlọpaa naa, wọn si ti wa latimọle nigbati iwadi n lọ lọwọ," DSP Adeyemi ṣalaye.