Ìjọba, ẹ tètè wá nǹkan ṣe sí ìwà ìpànìyàn fún ògùn owó tó wọ́pọ̀ láàrin àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà - Oluwo

Aworan Oluwo

Oríṣun àwòrán, Oluwo ilẹ Iwo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oluwo ti ilẹ Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi ti kepe ijọba apapọ ati tàwọn ipinlẹ wi pe ki wọn tete wa nkan ṣe si iwa ipaniyan ṣe oogun owo eyi to wọpọ bayii laarin awọn ọdọ ni Naijiria.

Oluwo koro oju si awọn ọna t'awọn eeyan fi n wa owo bayii eyi to mu ẹmi ọpọ eeyan ti ko mọwọ mẹsẹ ku iku aitọjọ.

Ọba Akanbi tun kepe awọn ori ade bi tirẹ naa ti fẹnu si ọrọ ọhun.

Oluwo ni fifi eeyan ṣe ogun owo ni ṣe pẹlu bi ilu ṣe le koko lasiko yii.

Ọba Akanbi ti wa rọ ijọba lati gbe idajọ iku kalẹ fun ẹnikẹni ti wọn ba ka ara eeyan mọ lọwọ.

Bakan naa ni Oluwo rọ ijọba lati ṣe idasilẹ ajọ kan ti yoo maa gbogun ti awọn to n fi eeyan ṣe ogun owo.

"Ijọba ṣe idasilẹ ajọ EFCC ati ICPC lati gbogun ti iwa ibajẹ lawujọ.

Bakan naa lo ṣe yẹ ki ijọba da ajọ kan silẹ eyi ti yoo maa gbogun ti awọn to n fi eeyan ṣe ogun owo at'awọn ẹlẹgbẹ okunkun.

Iṣẹlẹ ipaniyan fun ogun owo nilo ki ijọba tete wa nkan ṣe lori rẹ.

Lojoojumọ ni mo maa ka nipa rẹ ninu iwe iroyin, awọn eleyii to si han sita nìyẹn.

''Ni ṣe lo yẹ ki wọn maa pa ẹnikẹni ti wọn ba ka ẹya ara eeyan mọ lọwọ''

Oluwo sọ pe o yẹ ki wọn maa pa ẹnikẹni ti wọn ba ka ẹya ara eeyan mọ lọwọ.

Eyi naa jẹ arikọgbọn fawọn eeyan mii to ba fẹ hu iru iwa bẹẹ," Oluwo lo sọ bẹẹ.

Oluwo ni awọn ọdọ ẹlẹgbẹ okunkun t'awọn ọba kan n ṣatilẹyin fun lo n saba fi eeyan ṣogun owo.

Ori ade ilu Iwo wa rọ ijọba wa lati gbogun ti ẹgbẹ okunkun eyi to n ṣokunfa ipaniyan fun ogun owo.

Oluwo ni oun gẹgẹ bi ori ade gbogun ti iwa ipaniyan fun ogun owo tori oun fẹ fopin si gbogbo iwa palapala nilẹ Yoruba.

O ni idi gan an niyi ti oun fi kọ lati darapọ mọ ẹgbẹ okunkun bo tilẹ jẹ pe ọpọ lo ti n rọ oun lati ṣe bẹẹ.