Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Owa Obokun Ilẹ Ijesha tó wàjà

Oríṣun àwòrán, Facebook/Omo owa obokun Ijesaland
Ti a ba n sọrọ nipa Ọba alade ni ile kaarọ ojiire, ọkan gboogi ni Ọwa Oboku ti ilu Ijẹsa.
Ọdun mejilologogi ni Oba Gabriel Adekunle Aromolaran II lo lori apere ki ọlọjọ to de.
Ọba Aromolaran, jẹ abikẹyin iya rẹ, ti wọn si bi ni ọjọ kẹtala, ọsu kẹwaa ọdun 1937, si ile oye Ọba Alayeluwa Iluyomade Aromolaran I, Ọwa Obokun ati olori fun gbogbo ilu ijẹsa(1930-1942).
Ọdun 1982 ni wọn yan an gẹgẹ Owa Obokun ni ile loko ati lẹyin odi lẹyin ipapoda Ọba Peter Adeniran Olatunji Agunlejika II
O bẹrẹ ile ẹkọ rẹ ni ile ẹkọ Otapete Methodist, to si paari ile ẹkọ alakọbẹrẹ rẹ ni ile ẹkọ Methodist ni Agbeni loke Ado niluu Ibadan.
Bakan lo lọ ile ẹkọ girama ti ilu Ilesa lati ọdun 1970 si ọdun 1974. O sisẹ olukọni ko to morile Wesley College, Elekuro niluu Ibadan.
Ọba Aromolaran lọ si fasiti ilu Ibadan nibi to kawe gbo ninu iṣiro ni ọdun 1965.
Gẹgẹ bii olukọ, Ọba Aromolaran tẹsiwaju ninu iwe klka, to si tun lọ ilu Amẹrika lati kawegba oye Masters.
O pada wa si orilẹede Naijiria lati gba oye PhD ni fasiti Ibadan.
Ọba Aromolaran ni Ọba akọkọ ninu itan orilẹede Naijiria ni kẹkọ gbogbe PhD, to si kọ iwe akọkọ rẹr jade ni ọdun 1966.
Akikanju Ọba ni Ọba Aromolaran – Gomina Ademola Adeleke
Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti ransẹ ibanikẹdun si mọlẹbi Owa Obokun ati gbogbo ọmọ ilu Ijẹsa lori ipapoda Oba Oba Gabriel Adekunle Aromolaran II.
Ninu atẹjade ti Gomina fi sọwọ si awọn mọlẹbi, o ṣapejuwe Oba Alade naa gẹgẹ igi lẹyin ọgba, ẹni to oun ri gẹgẹ bi baba, to n tọ oun sọna lori ilọsiwaju ilu Ijẹsa ati ipinlẹ Osun lapapọ.
O kan sanra si iwa akikanju Oba Aromolaran, eyi to ni awọn eeyan jọla pupọ lasiko to wa lori itẹ.
“Baba daada ni Kabiyesi, ti ko ki n sẹ ọrọ ku lori idagbasoke ati igbayegbadun awọn eeyan. Ọrẹ ijọba ni Kabiyesi.
“Mo wa pẹlu Kabiyesi lasiko ti a ṣe ifilọlẹ oju ọna Brewery si aafin. Inu mi dun pe eyi waye loju aye Kabiyesi.”
Owa Obokun Ilẹ Ijesha jáde láyé lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínláàdọ̀rún

Oríṣun àwòrán, Daily Gist
Erin wo, ajanaku sun bi oke, Owa Obokun ti Ile Ijesha, Ọba Gabriel Adekunle Aromolaran ti waja lẹni ọdun mẹrindinlaadọrun un.
Asiwaju gbogbo ọmọ bibi ijesa lapapọ Oloye Olayinka Fasuyi lo kede pe alẹ Ọjọru ọjọ Kọkànlá osu Kẹ̀sán yii ni kabiyesi naa darapọ mawọn baba nla wọn.
Ki Oloye Fasuyi to kede iku kabiyesi naa lawọn eeyan ti n gbọ finrin finrin pe o ṣee ṣe ki ori ade naa ti papoda.















