Ẹ̀yẹ ìkẹyìn bẹ̀rẹ̀ fún alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC l'Oyo, Isaac Omodewu tó di olóògbé

Aworan Isaac Omodewu to di oloogbe
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹgbẹ oṣelu 'All Progressives Congress (APC)' ipinlẹ Ọyọ ti kede alakalẹ eto lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun alaga ẹgbẹ oṣelu naa, Amofin Isaac Ajiboye Omodewu to jade laye.

Ninu atẹjade ti wọn fi ṣọwọ si awọn oniroyin l'Ọjọru, ni igbimọ ipolongo fun ẹgbẹ oṣelu naa ti ṣe atupalẹ bi eto isinku naa yoo ṣe lọ.

Alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC naa jade laye lorilẹede Amẹrika

Awọn alakalẹ eto isinku Isaac Ajiboye Omodewu

Afihan Ara Oloogbe:

L'Ọjọbọ ọjọ kejila oṣu kẹsan an ọdun yii ni ara oloogb yoo de si Naijiria lati orilẹede Amẹrika ni nnkan bii aago mẹwaa owurọ.

Lẹyin eyii ni ọkọ to gbe ara Oloogbe naa yoo morile ilu Ibadan ni olu ile ẹgbẹ oṣelu APC to n bẹ ni agbegbe Oke-Ado, ni ibi ti wọn o ti ṣe afihan ara Oloogbe.

Aisun Onigbagbọ at Aṣalẹ Idaro:

L'Ọjọbọ ọjọ kejila oṣu kẹsan an bakan naa ni aisun onigbagbọ ati aṣalẹ idaro yoo waye ni gbọngan ayẹyẹ 'Victoria Garden Event Centre' to n bẹ ni adojukọ ile ẹkọ giga gbogboniṣe, Poly Ibadan, bẹrẹ lati aago mẹta ọsan.

Eto Isinku:

Eto isinku yoo waye lọjọ Ẹti, ọjọ kẹtala, oṣu kẹsan an ọdun yii, ni ile ijọsin 'First Baptist Church' to n bẹ ni ilu Otu ni ijọba ibilẹ Itesiwaju, bẹrẹ lati aago mẹwa owurọ.

Alaga ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ọyọ, Isaac Ajiboye Omodewu jade laye l'ẹni ọdun mọkanlelọgọta lọjọ kọkandinlogun oṣu kẹjọ ọdun yii, ni ibi ti o ti lọ gba itọju lorilẹede Amẹrika.

Ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ọyọ ṣe apejuwe Oloogbe naa gẹgẹ bii adari to da yatọ, to si n ṣe ojuṣe rẹ pẹlu irẹlẹ.

L'asiko rẹ gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ọyọ, ẹgbẹ naa ni Omodewu rii daju wi pe gbogbo aawọ lo yanju fun ifidimulẹ ati alaafia ẹgbẹ naa. "Labẹ bẹẹ lo si fi yẹ fun ẹyẹ ikẹyin to muna doko".

Taa ni Isaac Omodewu?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Isaac Omodewu bẹrẹ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni Otu, ki o to tẹsiwaju lọ si ile ẹkọ 'Baptist Modern School', Otu, 'Community Grammar School', Otu, ati ile ẹkọ girama 'Ansar-U-deen High School, Saki, n'ipinlẹ Ọyọ.

O kẹkọọ boye giga akọkọ ninu imọ iṣiro nile ẹkọ giga 'Yaba College of Technology', n'ipinlẹ Eko.

Lẹyin eleyii ni o tẹsiwaju lọ si orilẹede Amẹrika lati kẹkọọ gba oye mii nipa imọ iṣiro owo, ni fasiti 'New York, New York City'.

Bakan naa ni o tun kẹkọọ gboye mii ni fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ, Ile-Ifẹ.

Ajiboye Omodewu ṣiṣẹ ni oriṣiriṣi ileeṣẹ lorilẹede Amẹrika ki o to wọ inu oṣelu. Ni ọdun 1979, ọdọmọde Ajiboye Omodewu bẹrẹ sini foju si eto oṣelu nigba ti o bẹrẹ sini kopa kopa ninu ipade oṣelu pẹlu baba rẹ, Oloogbe, Alagba Omodewu.

Iṣẹ rẹ gẹgẹ bi oloṣelu bẹrẹ ni pẹrẹu ni ọdun akọkọ ti Gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹri, Oloogbe Abiọla Ajimọbi gun ori apere ijọba l’ọdun 2011.

Ajimọbi yan Omodewu gẹgẹ bii Kọmisana fun Ileigbe ati Ato Ilu. O lo ọdun meji ni ẹka ileeṣẹ ijọba naa ki o to di pe wọn gbee lọ si ẹka Ijọba Ibile ati Ọrọ Oye jijẹ gẹgẹ bii Kọmisana nigba ti Ajimọbi ṣe atunto awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ.

O ṣiṣẹ fun ọdun kan ni ẹka yii ki o tun to pada si ẹka Ileigbe ati Ato Ilu ti o wa tẹlẹri.

Ọpọlọpọ iriri ti o ti ni ninu ato ilu ati eto oṣelu lo mu ki o du ipo alaga ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ọyọ ti o si wọle ni ọdun 2021.

Ipo yii ni Omodewu wa titi ti ọlọjọ fi de.

Oloogbe naa fẹ aya o si bi ọmọ mẹta(obinrin meji ati ọmọkunrin kan)