Ohun tí a mọ̀ nípa bí Isaac Ajiboye Omodewu, alága APC ní ìpínlẹ̀ Oyo ṣe kú sí orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà

Oríṣun àwòrán, others
Alukoro ẹgbẹ oṣele APC n'ipinlẹ Ọyọ, Olawale Sadare to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba ṣe alaye wi pe itọju ni Omodewu wa lọ si ilu Amẹrika ni ibi ti ọlọjọ ti de.
Alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Ajiboye Omodewu jade laye lọjọ Aiku lorilẹede Amẹrika.
Lati bii oṣu diẹ sẹyin ni Omodewu ti n tọju aisan ti ko han si awọn ara ita ko to di pe o jade laye ni ẹni ọdun mọkanlelọgọta.
Alukoro ẹgbẹ oṣelu APC n'ipinlẹ Ọyọ, Olawale Sadare to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba ṣe alaye wi pe itọju ni Omodewu wa lọ si ilu Amẹrika ni ibi ti ọlọjọ to de.
Yatọ si ipo ti Omodewu di mu gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ oṣelu APC nigba aye rẹ, o ti ṣe Kọmisana ri ni ọkanojọkan ẹka ileeṣẹ ijọba ninu iṣakoso Gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ọyọ, Abiọla Ajmọbi.
Ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ọyọ fi ọrọ lede lori ipapoda alaga wọn

Oríṣun àwòrán, others
Ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ọyọ ti ṣe akawe ipapoda alaga wọn, Amofin Isaac Ajiboye Omodewu gẹgẹ bii adaanu nla fun ẹgbẹ naa ati orilẹede Naijiria ni apapọ.
Ninu atejade ti wọn fi ṣọwọ si awọn oniroyin lati ọwọ alukoro ẹgbẹ, Olawale Sadare niluu Ibadan lowurọ oni, ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ọyọ ṣe afihan ijaya ati Kayeefi ti ipapoda Omodewu mu ba ẹgbẹ naa lojiji.
Ẹgbẹ oṣelu naa ni, "Iroko nla ti ṣubu, bẹẹ si ni aye nla ti ṣofo ninu ẹgbẹ oṣelu wa.
Alaga wa to di oloogbe jẹ ẹni to kun fun iwa irẹlẹ, ikaanu, o si jẹ ẹni ti ko mọ ti ara rẹ nikan.
O di alaga ẹgbẹ ninu ọpọlọpọ rogbodiyan, ṣugbọn o sa ipa rẹ lati mu ki ẹgbẹ duro ire. Nnkan ibanujẹ gbaa ni bi o ṣe jade laye lasiko ti gbogbo igbiyanju rẹ ti n so eso rere".
Ẹgbẹ naa kẹdun pẹlu Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, Alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu APC ni Naijiria ati gbogbo ọmọ ẹgbẹ naa jakejado, gẹgẹ bi wọn ṣe n gbadura pe ki Ọlọrun tẹ Oloogbe naa si afẹfẹ rere.
Ohun ti a mọ nipa igbeaye Oloogbe naa
Wọn bi Isaac Ajiboye Omodewu ninu oṣu kẹrin ọdun 1963 ni Otu, ijọba Itẹsiwaju ipinlẹ Ọyọ.
O bẹrẹ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni Otu, ki o to tẹsiwaju lọ si ile ẹkọ 'Baptist Modern School', Otu, 'Community Grammar School', Otu, ati ile ẹkọ girama 'Ansar-U-deen High School, Saki, n'ipinlẹ Ọyọ.
O kẹkọọ boye giga akọkọ ninu imọ iṣiro nile ẹkọ giga 'Yaba College of Technology', n'ipinlẹ Eko.
Lẹyin eleyii ni o tẹsiwaju lọ si orilẹede Amẹrika lati kẹkọọ gba oye mii nipa imọ iṣiro owo, ni fasiti 'New York, New York City'.
Bakan naa ni o tun kẹkọọ gboye mii ni fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ, Ile-Ifẹ.

Ajiboye Omodewu ṣiṣẹ ni oriṣiriṣi ileeṣẹ lorilẹede Amẹrika ki o to wọ inu oṣelu. Ni ọdun 1979, ọdọmọde Ajiboye Omodewu bẹrẹ sini foju si eto oṣelu nigba ti o bẹrẹ sini kopa kopa ninu ipade oṣelu pẹlu baba rẹ, Oloogbe, Alagba Omodewu.
Iṣẹ rẹ gẹgẹ bi oloṣelu bẹrẹ ni pẹrẹu ni ọdun akọkọ ti Gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹri, Oloogbe Abiọla Ajimọbi gun ori apere ijọba l’ọdun 2011.
Ajimọbi yan Omodewu gẹgẹ bii Kọmisana fun Ileigbe ati Ato Ilu. O lo ọdun meji ni ẹka ileeṣẹ ijọba naa ki o to di pe wọn gbee lọ si ẹka Ijọba Ibile ati Ọrọ Oye jijẹ gẹgẹ bii Kọmisana nigba ti Ajimọbi ṣe atunto awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ.
O ṣiṣẹ fun ọdun kan ni ẹka yii ki o tun to pada si ẹka Ileigbe ati Ato Ilu ti o wa tẹlẹri.
Ọpọlọpọ iriri ti o ti ni ninu ato ilu ati eto oṣelu lo mu ki o du ipo alaga ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ọyọ ti o si wọle ni ọdun 2021.
Ipo yii ni Omodewu wa titi ti ọlọjọ fi de.
Oloogbe naa fẹ aya o si bi ọmọ mẹta(obinrin meji ati ọmọkunrin kan).














