Àlàyé ohun tó fa wàhálà ní ilé ìjọsìn l'Abuja, tí ọlọ́pàá fi fi tajútajú 'tear gas' tú ìsìn ká

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ohun ti awọn agba n sọ ni pe, ko si ija ni ṣọọṣi ju ki n ṣadura n ṣamin lọ.
Amọṣa ọrọ to waye ni ile ijọsin kan ni ilu Abuja tii ṣe olu ilu Naijiria lọjọ Aiku kọja adura ati amin o nigba ti wahala bẹ silẹ lasiko ijọsin.
Wahala naa le tobẹ gẹ to jẹ wi pe ẹni n ṣe adura gan ko le ṣadura mọ, bẹẹni ẹni n ṣe amin gan ko roju raye amin mọ nigba ti awọn olujọsin gbe pẹrẹgi kana ni ile Ijọsin United Methodist Church nibẹ.
Ọpọlọpọ wakati ni ija naa fi waye, oniruuru dukia ni wọn si bajẹ, ki awọn ọlọpaa lẹkun olu ilu Naijira to wa yanju rẹ pẹlu afẹfẹ tear gas tajutaju ni ile ijọsin kan eleyi to mu ki iṣẹ isin wa si idaduro lairotẹlẹ.
Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, awọn ọlọpaa ni lati ti ile ijọsin naa pa ni ti wọn si le awọn olujọsin kuro nibẹ sita ki wọn to gbe awọn alagba ijọ naa lọ si agọ ọlọpaa.
Ki lo fa ija naa
Ohun ti awọn kan n sọ ni pe ariyanjiyan lori boya ki wọn yapa kuro labẹ olu ilu ijọ wọn to wa ni Amẹrika tabi ki wọn ṣi duro sibẹ lo fa wahala naa.
Iroyin abẹle sọ pe olu ẹka ijọ naa paṣẹ awọn igbesẹ tuntun kan ni ile ijọsin naa eleyi ti awọn ọmọ ijọ naa wo gẹgẹ bi eyi ti ko ṣee ṣe.
Wọn ni awọn igbesẹ naa jẹ eyi to ṣe ajeji si aṣa agbegbe yii eleyi to mu ki awọn agbaagba ijọ naa kan fariga ti wọn si bẹrẹ si nii pe fun iyapa kuro labẹ olu ijọ naa, ki wọn si bẹrẹ si nii jẹ orukọ miran.
Bi awọn agbagb kan tun ṣe tako igbesẹ ti awọn agbagba yii n beere fun yii lo fa wahala naa to fi di gbodonroṣọ.














