Ajínigbé jí akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣẹ̀gùn 13 gbé, bèrè ₦50m owó ìtúsílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Adejobi Olumuyiwa
Ọga agba ileeṣe ọlọpaa Naijiria ti paṣẹ ki awọn oṣiṣẹ rẹ doola awọn akẹkọọ imọ iṣẹgun ti wọn ji gbe niluu Otukpo, nipinlẹ Benue.
Awọn akẹkọọ naa, ti wọn jẹ akẹkọọ imọ iṣegun fasiti ilu Jos ni wọn ko sọwọ ajinigbe loju ọna marose Otukpo si Enugu lasiko ti wọn n lọ si idanilẹkọọ kan.
Agbẹnusọ ileeeṣẹ ọlọpaa Naijiria, ACP Olumiyiwa Adejobi, lo fi ọro naa lede ninu atẹjade kan lọjọ Abamẹta.
Asiko ti awọn akẹkọọ naa n lọ sibi idanilẹkọọ awọn akẹgbẹ wọ niluu Enugu ni iṣẹlẹ naa waye.
Egbetokun juwe ijinigbe awọn akẹkọọ imọ iṣẹgun ọhun gẹgẹ bii eyii to buru jai.
O ni “ọga agba ọlọpaa ti fi awọn ọlọpaa ati irinṣẹ ṣọwọ sileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Benue lọna ati le tete doola awọn akẹkọọ naa.
“Lara igbesẹ yii ni kiko awọn oṣiṣe lati ẹka FID-STS ati FID-IRT, ọkọ ofurufu ẹlikọpita atawọn ọkọ ti a o lo lati ṣawari wọn ki a si da wọn pada sile.
“Ọkan wa wa pẹlu awọn akẹkọọ naa atawọn mọlẹbi wọn lasiko yii, afojusun wa si ni lati da wọn pada sile.”
Awọn ajinigbe bere aadọta miliọnu naira owo itusilẹ
Wayi o, awọn to ji awọn akẹkọọ naa gbe ti n bere owo ti iye rẹ jẹ aadọta miliọnu naira gẹgẹ bii owo itusilẹ wọn.
Eyii lo waye lẹyin ti awọn ajinigbe ọhun kan si awọn mọlẹbi awọ akẹkọọ naa.
Ẹgbẹ awọn akẹkọọ ọhun, SUG, lo fi ọrọ naa lede.
Agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Adeniran Adebanjo sọ ninu atẹjade kan pe awọn ajinigbe naa ti kan si awọn mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe, awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa atawọn mii ti ọrọ ọhun kan.
Atẹjade naa ni “A mo pe iroyin yii yoo ba ọpọ lọkan jẹ, ṣugbọn a rọ gbogbo akẹkọọ ki wọn fi ọkan wọn balẹ, awọn agbofinro ti bẹrẹ iṣẹ lori ọrọ naa a si gbagbọ pe wọn yoo yanju rẹ laipẹ.”















